Wọ́n ti sin òkú èèyàn 86, 43 míràn di àwátì lẹ́yìn ìbúgbàmù táńkà epo ní Niger

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Eeyan mẹrindinlaadọrun un ti wọn padanu ẹmi wọn nibi ibugbamu tanka epo bẹntiro ni ijọba ibilẹ Gurara, nipinlẹ Niger ti wọ kaa ilẹ sun.

Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ naa sọ pe ọjọ Aiku ni wọn sin oku awọn eeyan naa.

Adari ajọ ọhun, Abdullahi Baba-Arah, sọ pe eto isinku ọlọgọrọ ero naa ni wọn ṣe fun wọn pẹlu ifọwọsowọpọ ijọba ibilẹ naa atawọn eeyan kan ti wọn fi ara jin fun eto isinku ọhun.

Aago marun un irọlẹ ati aago mejila oru ni eto isinkun naa waye nile iwosan Dikko Primary Healthcare Centre.

O fikun pe bo tilẹ jẹ pe ọpọ ninu awọn oku naa ni wọn sin sinu iboji kan ṣoṣo, marun un ninu wọn ni wọn fi ṣọwọ si awọn mọlẹbi wọn lati sin.

Ibugbamu to mu ẹmi awọn eeyan naa lọ waye ni orita Dikko, to wa laarin ipinlẹ Niger ati Kaduna.

Ṣaaju ni ọkọ nla kan to gbe epo bẹntiro ti kọkọ danu ni orita ọhun, ti awọn eeyan agbegbe naa si bẹrẹ si n gbọn epo naa.

Bi awọn eeyan naa ṣe n gbọn lọwọ ni ina ṣẹyọ, to si jo wọn, to fi mọ awọn to n gbiyanu lati doola awọn to n gbọn epo ọhun.

Awọn arinrinajo loju ọnanaa, to fi mọ awọn ti ileeṣẹ wọn wa layika lo fara gba ninu rẹ.

Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ, Yerima sọ fun awọn akọroyin pe awọn agbofinro gbiyanju lati dẹkun awọn eeyan ki wọn ma baa gbọn epo naa amọ wọn fi aake kọri.

Yerima ni ọkan ninu awọn ọdọ to n gbọn epo ọhun tilẹ fa ọbẹ yọ, to si ni oun yoo gun ọlọpaa to ni ki oun ma gbọna naa pa.

Wayi o, ọpọ eeyan lo ti ba awọn eeyan naa kẹdun, ti awọn mii si bu ẹnu atẹ lu bi awọn eeyan naa ṣe gbọn epo nibẹ nitori gbogbo igba ti awọn eeyan ba n gbọn ọkọ to ba danu ni irufẹ iṣẹlẹ yii maa n waye.

Èèyàn tó jóná níbi táńkà tó ṣubú táwọn èèyàn ti ń gbọ́n epo ti di 86 báyìí

Awọn eeyan to jona raurau nibi iiamba ọkọ tanka to gbina lọjọ Abanmẹta nipinlẹ Niger ti di mẹrinlelọgọrin bayii.

Awọn ipinlẹ Niger to fidi ọrọ yii mulẹ ṣalaye pe eeyan mẹẹdọgbọn to farapa nibi iṣẹlẹ naa n gba itọju lọwọ nile iwosan.

Tanka agbepo ọhun ni a gbọ pe o ṣubu niluu Suleja ti awọn eeyan agbegbe to ti ṣubu si bẹrẹ si ni gbọn epo to n danu lati inu rẹ.

Gẹgẹ bi ophun ti a gbọ lati ipinlẹ Niger, ko pẹ tawọn eeyan bẹrẹ sii gbọn epo ni tanka naa bu gbamu ti ọpọ eeyan si jona rau rau ti awọn mii si farapa yanayana.

Ijamba ọkọ agbepo tanka wọpọ ni Naijiria tori awọn tirela yii lo maa n gbe epo lọ kaakiri orilẹede Naijiria.

Ni nnkan bi ọsẹ meji sẹyin, tanka agbepo mii ṣubu nipinlẹ Delta nibi ti eeyan marun ti padanu ẹmi wọn.

Ọ̀pọ̀ èèyàn pàdánù ẹ̀mí wọn bí táńkà epo ṣe gbiná ni ìpínlẹ̀ Niger

Ọpọ awọn eeyan lo ti padanu ẹmi wọn nipinlẹ Niger lasiko ti wọn n gbọn epo lati inu tanka epo to danu soju ọna.

Bakan naa ni ọpọ eeyan wa ni ile iwosan bayii lẹyin ti wọn farapa yanayana.

Iṣẹlẹ yii lo waye ni owurọ Ọjọ Satide ni agbegbe Dikko lọna marose Niger si Kaduna.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni bi tanka naa se wo lulẹ ni ọpọ eeyan bẹrẹ si ni yọ ike, ti wọn si n gbọn epo.

Asiko ti wọn gbọn epo yii ni ina sọ, to si jo ọpọ eeyan to n gbọn epo lọwọ lasiko naa, ti awọn to si jina si tanka epo naa farapa yanayana.

Bologi Ibrahim, agbẹnusọ fun Gomina ipinlẹ Niger, Mohammed Bago, to kọwọ rin pẹlu Gomina lọ si ijọba ibilẹ Suleja ati Tafa lati lọ se abẹwo si awọn akanse Gomina lo fi di iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin ileeṣẹ iroyin abẹle.

O ni iṣẹlẹ naa lo jẹ ohun to ba Gomina Bago lọkan jẹ pupọ, to si kesi awọn ẹsọ alabo lati pese aabo ni agbegbe naa ni kiakia.

"Gomina ipinlẹ Niger, Mohammed Umaru Bago ṣapejuwe iṣẹlẹ yii gẹgẹ bii eyi to bani inu jẹ, to si gba ẹmi ọpọ eeyan, ti dukia si tun ṣofo.

"Gomina wa ransẹ ibanikẹdun si awọn mọlẹbi awọn eeyan to padanu ẹmi wọn, oe ki Ọlọrun Allah duro ti wọn lasiko yii.

"Gomina tun wa palasẹ fun awọn ẹka ijọba lati se ohunkohun lati ri pe alaafia jọba ni agbegbe naa."