Wo iye owó tí o nílò láti lọ Hajj lọ́dún 2025 yìí

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ NAHCON to n ri si ọrọ irinajo Hajj si ilẹ mimọ niluu Mecca lorilẹede Mecca ti kede iye tawọn eeyan to ba fẹ lọ si Saudi Arabia lọdun yii yoo san.

Ninu ifọrọwerọ ti o ṣe pẹlu BBC, alaga ajọ NAHCON, ọJỌGBỌN Abdullahi Saleh Usman Pakistan, ṣalaye pe irin-ajo Hajj ti ọdun 2025 yii pin si ọna mẹta.

Ọjọgbọn Abdullahi ṣalaye pe owo tawọn ẹlẹsin musulumi to ba fẹ lọ Mecca lati apa guusu orilẹede Naijiria yoo pọ ju tawọn eeyan to ba fẹ lọ lati ẹkun ila-oorun ariwa ati iwọ -oorun ariwa lọ.

Alaga NAHCON ni awọn to ba fẹ lọ si Mecca lati awọn ipinlẹ to wa ni apa iwọ oorun ariwa Naijiria bii Kano, Kaduna, Jigawa, Katsina, Zamfara, Sokoto ati Kebbi yoo san N8,457,685.59.

Bakan naa ni o sọ pe awọn musulumi to ba fẹ lọ Mecca lati awọn ipinlẹ to wa ni apa ila oorun ariwa Naijiria bii Adamawa, Yobe, Borno, Gombe, Bauchi ati Taraba yoo san N8,327,127.59 fun irin-ajo Hajj.

Alaga ajọ NAHCON ni awọn musulumi to ba fẹ lọ Hajj lati awọn ipinlẹ to wa lapa guusu Naijiria yoo san N8,784,85.59 fun owo Hajj wọn.

Ọjọgbọn Abdullahi ni owo Hajji ọdun 2025 yii fi diẹ ju ti ọdun 2024 lọ.

''Ẹru tiẹ kọkọ ba wa tori a ti ro pe owo Hajj ọdun yii maa ti muliọnu mẹwaa naira ni tabi ko ju bẹẹ lọ.

Amọ, pẹlu iranlọwọ Ọlọrun atawọn igbesẹ kan ti a gbe, o pada jẹ irọrun fun wa.

A tun ti ṣeto fun adinku inawo awọn alalhaji ti yoo wa ni Mina ki o le rọrun fun wọn,'' Ọjọgbọn Abdullahi lo sọ bẹẹ.

Alaga NAHCON ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe ko si iranwọ owo lati ọdọ ijọba lori owo Hajj yii.

O fikun ọrọ rẹ ẹẹdẹgbẹta owo dọla ni awọn alalhaji yoo gba lọdun yii lati fi ra nnkan ti wọn ba nilo nibi iṣẹ Hajj.

Ọjọgbọn Abdullahi ni ajọ NAHCON ti ṣeto gidi ki iru nnkan to ṣẹlẹ lọdun to lọ ni Mina ma ba le ṣẹlẹ lọdun yii.

O tun sọ pe ọjọ karun un oṣu Keji ọdun yii ni gbedeke fun sisan owo Hajj ọdun yii, bi bẹẹ kọọ, ẹnikẹni ti ko ba sanwo tiẹ titi ọjọ yii ko ni lanfaani lati lọ Hajj lọdun yii.