You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo bí ìgbẹ́jọ́ akọrin ẹ̀mí Timileyin Ajayi afurasí tó pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ Salome tó si gé e wẹ́lẹwẹ̀lẹ ṣe lọ
Ile ẹjọ giga niluu Lafia nipinlẹ Nasarawa ti paṣẹ wi pe ki wọn ju akorin ẹmi Timileyin Ajayi, afurasi to pa ọrẹbinrin rẹ, Salome Adaidu si ọgba ẹwọn.
Adajọ Simon Aboki lo pàṣẹ yii nibi igbẹjọ Timileyin ẹni ti wọn fẹsun kan wi pe o ge ẹya ara Salome si ọna aadọta lẹyin to pa a tan.
Ọwọ ọlọpaa tẹ Timileyin nigba to n gbe ori Salome lọ si Uke nipinle Nasarawa.
Lẹyin naa ni ileeṣẹ ọlọpaa gbe Timileyin lọ ileẹjọ lori ẹsun ipaniyan.
Adajọ Aboki paṣẹ pe ki wọn ju Timileyin si ọgba ẹwọn to wa ni ilu Lafia tori agbẹjọro rẹ to le bẹbẹ fun un ko yọju sile ẹjọ.
Ni nnkan bi ọsẹ kan seyin ni orukọ Timileyin lu ori ayelujara pa lẹyin tawọn ọlọpaa ṣafihan rẹ gẹgẹ bi afurasi to pa Salome agunbanirọ to n ṣe iruulu niluu Abuja.
Awọn ileeṣẹ iroyin ni Nasarawa fidi rẹ múlẹ pe Timileyin ti foju ba ile ẹjọ, ati pe adajọ Simon Aboki lo wa lori ẹjọ naa.
Timileyin ti n ka boro boro fawọn ọlọpaa, amọ, ọpọ eeyan lo n sọ lori itakun ayelujara pe o n dibọn ni.
Ẹbi Salome si wa ninu ibanujẹ di akoko yii, wọn si n pe fun idajọ ododo.
Oloogbe Salome Eleojo Adaidu to jẹ agunbanirọ lo n ṣe iruulu nile iṣẹ adojutofo NICON niluu Abuja.
SP Rahman Nansel to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Nasarawa fidi rẹ múlẹ pe awọn ri ẹya ara Salome ti Timileyin ti ge wẹlẹwẹlẹ gba lọwọ rẹ nigba tawọn eeyan n lu u lalubami.
Ileẹjọ ti sún igbẹjọ sọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kinni ọdun yii.
Ṣùgbọ́n ta gan-an ni Timilẹyin Ajayi?
Akọrin ẹmi ni Timilẹyin Ajayi, ẹni ọgbọn ọdun ni.
Ipinlẹ Kogi ni wọn ti bi i, ni Aarin-gbungbun Ariwa orilẹede Naijiria.
Timileyin ṣalaye pe aṣoju awọn to n fi owo ilẹ okeere da okoowo lori ayelujara (cryptocurrency agent), loun.
Bo tilẹ jẹ pe ko sọ igba to ti n ṣe òwò ọhun bọ.
O ni o ti fẹrẹ to ọdun kan ti oun ati Oloogbe Salome Adaidu ti n fẹ ara wọn bọ.
O ni ṣugbọn ajọṣepọ naa ko ja geere, nitori awọn ki i rira deede.
Ṣugbọn awọn ẹbi Adaidu tako eyi, wọn ni ọmọ awọn ki i ṣe ololufẹ afurasi yii rara.
Loju opo TikTok rẹ, Timileyin kọ ọ sibẹ pe ayaworan sinima loun.
O tun ni oun maa n ṣe awọn eto lori ayelujura, oludari ẹka iroyin ayelujara lo tun pe ara ẹ, bẹẹ lo ni oun n ya aworan fidio, oun si tun maa n ṣe akọsilẹ orin.
Mo pa ọ̀rẹ́bìnrin mi torí ó ń fẹ́ ẹlòmíràn pẹ̀lú mi, n kò kábàmọ́ọ̀ ikú rẹ̀ – Akọrin ẹ̀mí Timileyin Ajayi
Timileyin Ajayi, ọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn ti wọn fẹsun kan pe o ṣekupa ọrẹbinrin rẹ ti ṣalaye eredi to fi wu iwa laabi naa.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin ni ẹka CID to wa ni ọọfisi ọlọpaa ipinlẹ Nasarawa ni afurasi naa jẹwọ bẹẹ.
Timileyin sọ pe oun pa ọdọbinrin ọhun latari pe o n fẹ ọkunrin mii pẹlu oun, ati pe oun ko kabamọ iku rẹ.
Nigba ti awọn akọroyin beere lọwọ rẹ pe ṣe lootọ lo pa obinrin naa, o ni ootọ ni.
Timileyin sọ pe "Mo ṣekupa a nitori awa mejeji ko ri aye fun ara wa, kii ṣe ohun ti mo gba lero tẹlẹ amọ o ti ṣẹlẹ naa niyẹn.
"Kii ṣe pe mo ni lọkan tẹlẹ lati pa amọ o n fẹ ẹlomiran pẹlu mi.
"Ọpọ nnkan nipa rẹ lo maa n fi pamọ fun mi; ori ẹrọ ilewọ rẹ ni mo ti ri pe o maa n ba awọn ọkunrin mii sọrọ, eredi ree ti mo fi gbe igbesẹ naa."
Afurasi ọhun sọ siwaju si pe oun ko kabamọ pe oun ṣe sekupa oloogbe naa.
Ẹwẹ, ẹgbọn oloogbe, Esther Adaidu ti sọ pe awọn mọlẹbi wọn ko mọ pe aburo oun n ṣere ifẹ pẹlu afurasi naa.
Esther sọ pe "Awa ko mọ ọgbẹni Timileyin yii rara, a ko tii foju ganni rẹ ri titi di igba ti wọn pe wa o ṣekupa aburo wa, to si ge ẹya ara rẹ.
"Awa gẹgẹ bii mọlẹbi n beere idajọ ododo lori ọrọ yii nitori oun lo pa aburo mi, o si ti jẹwọ fun."
Ọjọ Aiku, ọjọ kejila, oṣu Kini, ọdun 2025 yii ni ọwọ tẹ Timileyin pẹlu ori ọrẹbinrin rẹ ọhun, Salome Eleojo Adaidu.
Ẹni ọdun mẹrinlelogun ni Salome, agunbanirọ lo si n ṣe niluu Abuja ṣaaju iku rẹ.
Salome pade iku ojiji lasiko to lọ ṣabẹwo sile afurasi to wa lagbegbe Papalana, ni New Karshi to wa ni ijọba ibilẹ Karu nipinlẹ Nasarawa