Ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí ìyàwó ọ̀gá ọlọ́pàá tẹ́lẹ̀ rí AIG Hakeem Odumosu táwọn ajínigbé jí gbé ní Ogun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ogun ti kéde pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti ṣàwárí ìyàwó ọ̀gá ọlọ́pàá tẹ́lẹ̀ rí, Hakeem Odumosu.

Agbenusọ ọlọ́pàá Ogun, Omolola Odutola ló ṣíṣọ lójú ọ̀rọ̀ náà nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ní Abeokuta, olú ìlú ìpínlẹ̀ náà.

Odutola ṣàlàyé lálẹ́ Ọjọ́bọ̀ làwọn ajínigbé kan jí ìyàwó ọ̀gá ọlọ́pàá náà gbé nígbà tó ń wọ ilé rẹ̀ tó wà ní òpópónà Aminu Street, Orange Estate, Arepo ní ìjọba ìbílẹ̀ Obafemi Owode.

Ó ní àwọn ajínigbé mẹ́rin tí wọ́n da àwọ̀n bojú wọ́ obìnrin náà bọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀ Lexus Sports Utility rẹ̀, tí wọ́n sì gbé e lọ.

Ó fi kun pé DPO àgọ́ ọlọ́pàá Warewa ló ṣáájú àwọn ọlọ́pàá lọ sí ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, tí wọ́n sì ń wá inú igbó táwọn ajínigbé náà gbà lọ.

Odutola ní DPO náà tún ti kan sáwọn fijilanté Warewa àti Maaba láti ṣe ìrànwọ́ nípa ṣíṣe àwárí obìnrin náà.

Ó sọ pé bí nǹkan bá ṣe ń lọ sí ni àwọn yóò máa fi tó aráàlú létí.

Bákan náà ló ní àwọn ti fi ọ̀rọ̀ náà tó kọmíṣánnà ọlọ́pàá Ogun, Lanre Ogunlowo létí táwọn yóò sì ṣàmúlò gbogbo nǹkan tó yẹ láti gba ìtúsílẹ̀ obìnrin ọ̀hún.