K1 De Ultimate pàdánù ìyá rẹ̀ lẹ́ni ọdún 105

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde Marshal, ẹni ti ọpọ mọ si K1 De Ultimate ti padanu iya rẹ, Alhaja Halima Anifowoshe.

K1 kede iku iya rẹ loju opo ayelujare rẹ ni owurọ Ọjọ Satide, ọjọ kejidinlogun oṣu kinni ọdun 2025.

Fọnran iya to di oloogbe naa pẹlu K1 ni wọn fi kede iku iya.

"Pẹlu ẹdun ọkan ni a fi kede ipapoda iku iya King Wasiu Ayinde. Ki Ọlọrun ba wa tẹ si afẹfẹ rere. Alhaja Shadiya Omoakeredolu Aya Anifowoshe. Sun re oo."

Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti ba K1 De Ultimate kedun lori iku iya rẹ.

Ninu fọnran kan ti K1 gbe sita ṣafihan bi o se n ba aarẹ sọrọ lori ipapoda iya naa ninu ile rẹ

Iroyin to tẹ wa lọwọ bayii ni pe wọn yoo sin iya naa lonii ni ilana ẹsin musulumi ni ile rẹ to wa niluu Ijebu Ode nipinlẹ Ogun.

Saaju ni Wasiu Ayinde ni gbogbo ẹbun orin ti oun ni lo jẹ pe ọwọ ara iya rẹ lo ti gba.

O ṣapejuwe ajọsepọ to wa laarin oun pẹlu iya rẹ gẹgẹ bii eyi ti o danmọran pẹlu ọpọ ifẹ otitọ.

"Iya mi ni ẹbun orin. Wọn bi mi sinu orin . Olorin ni iya mi ko to di pe o ṣe igbeyawo. O ni ẹbun orin kikọ , to si tun jẹ ọmọ ọba.

"Wọn ko gba laaye lati kọrin nitori o jẹ ọmọọba, ti awọn obi rẹ si lero pe orin kikọ yoo se idaduro igbeyawo rẹ."

Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti ba K1 De Ultimate kedun lori iku rẹ.

Ninu fọnran kan ti K1 gbe sita ṣafihan bi o se n b a aarẹ sọrọ lori ipapoda iya rẹ.