You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ògiri ilé ìtura dà wó pa ọmọdé méjì ní Ikorodu,wo ìgbésẹ tí ìjọba Eko tí gbé
Iṣẹlẹ ile wiwo kan to waye ni ọjọ Abamẹta ti mu ẹmi ọmọde meji lọ ni ipinlẹ Eko.
Agbegbe Ikorodu ni iṣẹlẹ yi ti waye nigba ti ogiri alapa ile itura ile onipẹtẹsi alaja kan wo lu ile oniyara mẹta kan to wa lẹyin rẹ.
Ọmọde meji, Gbolahan Atolagbe ọmọ ọdun meje ati Yinka Atolagbe ọmọ ọdun mẹsan la gbọ pe wọn ba iṣẹlẹ naa lọ.
Olufẹmi Osanyintolu to jẹ ọga ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko lo fi ọrọ yi lede ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sawọn akọroyin.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ
Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ṣalaye fawọn akọroyin pe ṣadede ni ogiri ile itura yi wo lu yara tawọn ọmọde yi wa lasiko ti ojo n rọ lọjọ Abamẹta.
Lowurọ ọjọ Abamẹta ni iṣẹlẹ yi waye.
Ileeṣẹ iroyin Sahara Reporters jabọ wi pe nkan bi ago mọkanla aabọ ni ogiri naa wo lu ile tawọn ọmọ naa wa ninu rẹ ni ojule Karundinlọgbọn, adugbo Ajao CWC lẹgbẹ Olainukan Bus stop, Ishawo, Ikorodu.
A gbọ pe wọn ko tete ribi kesi awọn oṣiṣẹ pajawiri lati le ribi doola awọn ọmọ wọnyi to jẹ ọmọ baba kanna.
Nigba ti wọn yoo fiu ri wọn yọ kuro labẹ ile naa, awọn mejeji ti padanu ẹmi wọn.
Wn ti sin awọn ọmọde wọnyi nilana musulumi.
Ẹwẹ ajọ to n risi ọrọ pajawiri ni ipinlẹ Eko sọ pe awọn ti ra ọgba yika agbegbe ibi ti iṣẹlẹ yi ti waye.
Wọn ko sọ idi ti ogiri ile naa ṣe wo pa ọmọde wọnyii tabi boya wọn ti fi panpẹ ofin mu ẹnikẹni lori iṣẹlẹ yi