'Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló máa ń gbéṣẹ́ fún mi nítorí mo jẹ́ obìnrin'

Àkọlé fídíò, Opeyemi ṣàlàyé ìrìnàjò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí obìnrin tó ń ṣe ilé àti gbọ̀ngàn ayẹyẹ lọ́ṣọ̀ọ́
'Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló máa ń gbéṣẹ́ fún mi nítorí mo jẹ́ obìnrin'

Lóde òní wọ́n ní kò sí ohun tí ọkùnrin ń ṣe tí obìnrin náà kò lè ṣe kòdá ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin a máa fakọyọ ní ìpò tí wọ́n bá wà.

Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀rọ̀ fún arábìnrin yìí, Kareem Suliyat Opeyemi tó jẹ́ ẹni tó máa ń fi òdòdó ṣe ọ̀ṣọ́ sí ara ilé títì, òpópónà, inú gbọ̀ngàn ayẹyẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Opeyemi Kareem tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gboyè lẹ́ka ìmọ̀ okoòwò ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ní títa òdòdó ni òun fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà kí òun tó tẹ̀síwájú láti fi ṣíṣe àwọn ọ̀ṣọ́ kún-un.

Ó ní àwọn tí àwọn dìjọ ń ṣiṣẹ́ ló fún òun ní ìwúrí láti máa gun òkè ńlá láti fi ṣe ar ilé lọ́ṣọ̀ọ́.

Ó nígbà táwọn ènìyàn ti àwọn ń ta òdòdó fún bẹ̀rẹ̀ sí ní bèrè pé ṣé òun kò lè ṣe ilé lọ́ṣọ̀ọ́ ní òun rò ó wí pé òun le fi ìyẹn náà kún okoòwò òun.

“Nígbà tí máa fi bẹ̀rẹ̀, ẹ̀rù láti gun òkè máa ń bàmí àmọ́ ní báyìí, ẹ̀rù òkè kankan kì í bàmí mọ́, kò sí òkè tí mi ò le gùn láti fi ṣe ilé lọ́ṣọ̀ọ́.”

Opeyemi Kareem tún sọ pé láti ìgbà tí òun ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí òun yàn láàyò, inú àwọn ènìyàn máa ń dùn láti gbé iṣẹ́ fún òun nítorí tí òun jẹ́ obìnrin tí òun ń ṣe iṣẹ́ náà.

Ó ní ọ̀pọ̀ tilẹ̀ máa ń torí obìnrin tí òun jẹ́ gbé iṣẹ́ fún òun.

Bákan náà lo ní nígbà mìíràn àwọn mìíràn máa ń rò wí pé òun kò le ṣe àwọn iṣẹ́ kan nítorí pé òun jẹ́ obìnrin ṣùgbọ́n máa ń sọ fún wọn kí wọn fi iṣẹ́ dán òun wò, tí òun kì í sì jáwọn kulẹ̀.

Ó ní ìpèníjà tí àwọn máa ń kojú lẹ́nu iṣẹ́ kò ju àṣìṣe tí àwọn máa ń ṣe nígbà tí àwọn bá ń ṣe iṣẹ́ lọ́wọ́ tó sì jẹ́ wí pé àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ máa tún bẹ̀rẹ̀ ni tí oníbàárà bá dá irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ padà.