You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Akẹ́kọ̀ọ́ fásitì UNILAG ṣubúlulẹ̀ níbi tó ti ń gbá bọ́ọ̀lù, ó gba ibẹ̀ kú
Akẹkọọ onipele kini lẹka eto ìmọ nipa ato ilu ni fasiti Eko, Simon Adokwu ti jade laye lasiko to n gba bọọlu pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ logba ile ẹkọ fasiti naa to wa niAkoka niluu Eko
Iroyin kaakiri awọn ileeṣẹ iroyin abẹlẹ ni Naijiria sọ pe akẹkọọ naa ṣẹṣẹ ti ile ijọsin de loun ati awọn akẹgbẹ rẹ ba gbe bọọlu sita lati fi ṣe ere ni papa isere to wa nitosi ibudo idagbasoke oṣiṣẹ Human Resource Development Center nile ẹkọ naa ko to di pe omodekunrin naa ṣa dede ṣubululẹ to si ku.
Nigba ti awọn akẹgbẹ rẹ yoo fi gbe e de ileewosan to wa nile ẹkọ giga fasiti naa, dokita fìdí rẹ mulẹ pe o ti jade laye.
Alukoro ile ẹkọ fasiti naa, Alagba Ibraheem sọ pe ẹni ọdun mejilelogun ni akẹkọọ naa ko ro dagbere fun aye.
O ni o ṣalaye fun awọn akẹgbẹ rẹ ṣaaju pe ara oun ko ya ko to lọ si papa lọ gba bọọlu.
Arabinrin Ibraheem ni sibẹ o sọ fun wọn pe oun ṣi fẹ lati gba bọọlu pẹlu wọn.
“Ibi ti wọn ti n ba ere bọọlu lọ lọwọ ni wọn ti wo ẹyìn wo ti wọn ri pe oti ṣubu lulẹ.
“Awon akẹgbẹ rẹ gbe e lọ si ileewosan, wọn si gbiyanju lati raa pada nibẹ ṣugbọn epa ko boro mọ, ọmọ naa ti ku.”
Alukoro UNILAG ni awọn alaṣẹ ile ẹkọ fasiti naa ti kan sí awọn obi akẹkọọ naa, wọn si ti ni awọn yoo wa gbe oku rẹ.
Amọṣa o ni ile ẹkọ naa ṣi kọkọ fẹ ṣe ayẹwo oku rẹ lati mọ bi ọrọ iku rẹ ṣe jẹ.