Lagos Flood: Omíyalé gbẹ́mìí ọmọ ìyá mẹ́ta àti àgbálàgbá mẹ́rin - NEMA

Ajọ to ri si iṣẹlẹ pajawiri lorilẹde Naijiria (NEMA) ti kede pe iṣẹlẹ omiyale to ṣelẹ ni ipinlẹ Eko lọse to kọja gbẹmi eeyan meje.

Alamojuto ajọ ni apa guusu iwọ-oorun orilẹ ede yii, Arakunrin Ibrahim Farinloye sọrọ ninu atesita kan to fi sita fun awọn akoroyin ni ipinlẹ Eko lọjọru ọse yii.

O ni;

“Iwadi wa lori ojo arọrọ da ti o bẹrẹ lati ọjọ kẹjọ si ọjọ kẹsan oṣu keje ni ipinlẹ Eko fihan pe eeyan meje lo ba iṣẹlẹ naa lọ- awọn ọmọ iya mẹta ati agbalagba mẹrin.”

“O to eeyan mẹjọ ti ajọ na igbinyanju lati dola ẹmi lẹyin iṣẹlẹ omoiyale naa,“ o tẹsiwaju.

Farinloye ni awọn ọmọ iya mẹta ti wọn ba iṣẹlẹ naa lọ ni wọn gbe ni ile gbe kan ti wọn ti kọ tan ti o jẹ ti ile jọsin Mercy of Christ Apostolic Church.

O ni, Michael, 18; Elizabeth, 17; ati Timi, 14, ni sagbako iku nigba ti wọn igbinyanju lati kuro ninu ile wọn lọ si ninu ile jọsin.

Farinloye ni, Timi, ọmọ to kere ninu awọn iya meta naa fẹ gun igi bo si ninu ile jọsin, ni ẹsẹ rẹ yẹ ti o si bọ si ninu agbara omi naa.

Awọn ọmọ iya meji yoku ninu igbinyanju wọn lati dola ẹmi aburo wọn naa bo si ninu agbara omiyale, ti awọn mẹtẹta si ba omi lọ.

Farinloye ni ajó NEMA ti sabẹwo si agbegbe naa lati ba awọn aṣoju adugbo naa sọrọ lori awọn ipenija ti wọn koju ati lati ṣe ikini si ọdọ awọn molẹbi awọn ọmọ iya mẹta.

“A ya si ọdọ awọn molẹbi awọn ọmọ naa ni ile wọn sugbọn wọn ko si nile , lẹyin naa la ṣe abẹwo si awọn ariki agbegbe naa.”

“A rọ awọn olugbe agbegbe naa pe ti ọdun yii a fi pari, wọn ṣe oju ni alakan fi n sọri lati dẹkun iṣẹlẹ omoiyale naa.”

Awọn aṣoju agbegbe sọ fun ajọ NEMA pe lẹyin ti awón iya mẹta naa ba iṣẹlẹ omiyale naa, awọn ọmọ iya mẹrin miran ni omiyale tun fẹ gbe lọ sugbọn wọn sare lati dola awọn ọmọ naa.”

Farinloye wa darukọ awọn agbegbe ti wọn ti ri ikọlu: Oke Isagun, Agbado Oke, Oko LCDA, ti gbogbo wọn wa ni ijọba Alimosho.