Ìdí tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC fi fagilé ìwọde tí wọ́n fẹ́ bẹ̀rẹ̀ lónìí lórí àfikún tàríìfù orí ìpè àti dátà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ti fagile iwọde tawọn oṣiṣẹ fẹ ṣe lonii ọjọ kẹrin oṣu Keji tako afikun ida 50% owo tariiifu ori ipe ati data ori foonu ti ajọ NCC to n ri si eto ibaraẹnisọrọ buwọlu laipẹ yii.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ yi ipinnu rẹ lori ifẹhonuhan to fẹẹ ṣe pada lẹyin ipade ti wọn ṣe pẹlu ijọba apapọ eyi ti akọwe ijọba, George Akume, dari.

Gẹgẹ bi atẹjade ti adari ẹka eto iroyin ati ilukoro ni ọọfisi akọwe ijọba apapọ, Segun Imohiosen, fi sita ṣe sọ, ipade naa da lori ọna ati daabo ọmọ Naijiria ati fun iṣọkan laarin awọn oṣiṣẹ ati ijọba.

Ọgbẹni Imohiosen ni minisita eto iroyin, Mohammed Idris, to sọrọ lorukọ ijọba apapọ nibi ipade naa sọ pe ijiroro waye nibẹ lori iwadii ti ajọ NCC ṣe eyi to mu wọn gba fawọn ileeṣẹ ibanisọrọ lati ṣe afikun tariifu ori ipe ati data pẹlu ida aadọta.

Lẹyin ijiroro to waye ni igun mejeeji ṣe agbekalẹ igbimọ ẹlẹni mẹwaa kan ti yoo ṣiṣẹ lori iwadii ajọ NCC lori ọrọ tariifu.

Igbimọ yii ti eeyan marun un ninu wọn ọmọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC nigba ti marun un yooku jẹ aṣoju ijọba apapọ ni wọn ti fun ni ọsẹ meji lati jabọ fun ijọba ati ẹgbẹ oṣiṣẹ.

Lẹyin ti igbimọ yii ba ṣiṣẹ wọn tan lati ọsẹ meji ni wọn yoo da aba fun ijọba ati ẹgbẹ oṣiṣẹ lori igbesẹ ti wọn ro pe ijọba le gbe lori ọrọ afikun owo tariifu ori ipe ati data.

Ẹwẹ, aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC, Joe Ajaero, ti sọ pe ẹgbẹ oṣiṣẹ yoo duro titi ti igbimọ ẹlẹni mẹwaa naa yoo fi pari iṣẹ wọn lati mọ igbesẹ to ba kan ti NLC yoo gbe.

Lara awọn to wa nibi ipade naa ni minisita ileeṣẹ ijọba to n ri si ẹki ibanisọrọ, Bosun Tijani, Minisita eto inawo, Wale Edun, Ọga agba ajọ NCC, Ọmọwe Aminu Maida, Minisita fọrọ awọn oṣiṣẹ, Alhaji Mohammed Dingyadi ati oludamọran aarẹ lori eto abo, Nuhu Ribadu.

Kí ni ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC fẹ́ ṣe ìwọ́de lé lórí káàkiri Nàìjíríà ọjọ́ Ìṣẹ́gun tẹ́lẹ̀?

Lonii ọjọ kẹrin oṣu Keji ọdun yii ni ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC kede pe awọn oṣiṣẹ yoo bẹrẹ ifẹhonuhan tẹlẹ, lori afikun ida 50% owo tariiifu ori ipe ati data ori foonu ti ajọ NCC to n ri si eto ibaraẹnisọrọ buwọlu laipẹ yii.

Ṣaaju ninu atẹjade kan ti aarẹ ẹgbẹ naa, Joe Ajaero, buwọlu ni NLC ti kede igbesẹ yii nibi ipade igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa to waye l'ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kinni yii niluu Abuja.

Igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ NLC tako afikun owo tariifu pẹlu ida 50% nibi ipade wọn, eyi ti wọn ṣapejuwe wi pe o ti pọju fun araalu.

Ajọ NLC tun bu ẹnu ẹtẹ igbesẹ ajọ NCC lori bi o ti buwọlu afikun owo tariifu lori ipe ati data.

Ṣaaju ni NLC paṣẹ ninu atẹjade naa wi pe ki gbogbo oṣiṣẹ dẹyẹ si lilo foonu tabi rira data lati ọjọ kẹrin oṣu Keji ti ijọba ba kọ lati ṣe idaduro afikun owo tariifu naa.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ni igbesẹ ajọ NCC yii buru jai, o si le ṣakoba fawọn oṣiṣẹ atawọn araalu lapapọ papaa julọ lasiko yii ti ọpọ ti ilu le koko latari awọn eto ti ijọba to wa lode n ṣe ti ko tii kẹsẹjari.

Ikilọ ni a fẹ fi iwọde yii ṣe fun ijọba - NLC

NLC ni awọn oṣiṣẹ yoo fẹhonu wọn han lori igbesẹ ajọ NCC yii nipa siṣe iwọde kaakiri orilẹede lọjọ kẹrin oṣu Keji.

Ajọ NLC sọ ninu atẹjade naa wi pe iwọde yii yoo jẹ ikilọ fun ijọba lati jẹ ki wọn mọ akoba ti afikun owo tariifu yii le ṣe fawọn oṣiṣẹ to n gba N70,000 gẹgẹ bii owo oṣu to kere julọ.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ tun fikun ọrọ rẹ pe kii ṣe lasiko ti ijọba gbe owo ina mọnamọna ati epo bẹntiroolu lọ soke ti ọwọngogo nnkan gbode yii lo tun yẹ ki afikun tun ba owo tariifu fun ipe ori foonu ati data.

Gbogbo ẹka awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ lawọn ipinlẹ kaakiri Naijiria atawọn ẹgbẹ mii ni ajọ NLC ti rọ bayii lati darapọ mọ iwọde ọhun ti yoo waye lọjọ kẹrin oṣu Keji.

NLC ko ṣai kepe ijọba apapọ, ajọ NCC ati ile aṣofin agba l'Abuja lati ṣepade pọ pẹlu awọn tọrọ kan lẹka eto ibanisọrọ, ki wọn da afikun owo tariifu naa duro.

Ajọ NLC ni ti ijọba ba kọ lati ṣe eleyii, ẹgbẹ oṣiṣẹ yoo tẹsiwaju pẹlu ifẹhonuhan to fẹ ṣe, ati pe awọn tun le dẹyẹ si ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ kaakiri orilẹede Naijiria.

Awọn onibaara pariwo lori afikun tariifu ori ipe ati data

Ẹwẹ, lati igba ti ajọ NCC ti kede afikun ida 50% owo tariifu ori ipe ati data lọpọ onibaara ti n fi aidunnu wọn han.

Funmi Adejumo to jẹ oniṣowo niluu Eko sọ pe ''gbogbo igba ni wọn maa n sọ fun wa pe Naijiria lawọn eeyan ti n sanwo to kere julọ lori ipe, atẹjiṣẹ ati data nilẹ Afirika.

Amọ, ki ni eyi tumọ si nigba tawọn eeyan ko ba lagbara ra data ọhun mọ?

Lai ṣe ani ani, afikun owo tariifu yii yoo mu aye le sii fun ọpọ ọmọ Naijiria.

Ṣugbọn oninmọ nipa ọrọ aje, Aliyu Ilias, sọ pe ko si bi awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ sẹ fẹ tẹsiwaju lati maa ṣiṣẹ ti wọn ko ba fowo kun owo tariifu ori ipe, atẹjiṣẹ ati data.

Akọsilẹ kan ti ajọ ITU to n ri si eto ibaraẹnisọrọ lagbaaye lọdun 2023 sọ pe $2.35 lawọn eeyan n ra data giigi meji (2GB) ni Naijiria, eyi ti wọn n ra n ni $2.66 lorilẹede Ghana, $2.92 ni Kenya, ati $7.98 lorilẹede South Africa.

''Ipe ori foonu tawọn eeyan n lo N11 fun tẹlẹ ti di N16.50''

Ipe ori foonu tawọn eeyan n lo N11 fun tẹlẹ ti di N16.50 pẹlu afikun owo tariifu ti ajọ NCC kede bayii.

Atẹjiṣẹ tawọn eeyan n lo N4 lati fi ranṣẹ lori foonu tẹlẹ ti di nnkan ti wọn n lo N6 lati fi ranṣẹ bayii.

Bakan naa, data giigi kan tawọn eeyan n fi N1000 ra tẹlẹ yoo di N1,500 bayii pẹlu afikun owo tariifu ti ajọ NCC kede.

Ohun tawọn akọṣẹmọṣẹ nipa eto ibaraẹnisọrọ ṣalaye ni pe alekun ko ba owo tariifu ni Naijiria fun bi ọdun mẹwaa bayii.

Bakan naa ni wọn sọ pe awọn nnkan tawọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ nilo lati ri awọn onibaara wọn n pe lori foonu gaara, fi atẹjiṣẹ ranṣẹ ati ṣe awọn nnkan mii ti gbowo lori.

Ọga agba ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ Airtel, Dinesh Balsingh, sọ pe afikun owo tariifu tawọn onibaara n san sẹ pataki ti wọn ba fẹ maa tẹsiwaju lati maa gbadun lilo foonu wọn fun ohun ti wọn ba fẹ.

Ọgbẹni Balsingh ṣalaye pe alekun ida 300% lo ba owo tawọn ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ fi n ṣiṣẹ laarin ọdun meji pere.

Bakan naa ni o tun sọ pe bi owo Naira ko ti ra nnkan kan mọ naa wa lara awọn nnkan to ṣakoba fun awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ.

Ọga ileeṣẹ Airtel fikun ọrọ rẹ pe owo lita kan epo disu tawọn n lo fun ẹrọ amunawa ti lọ soke lati N230 si N1,000.

Ti ẹ o ba gbagbe, ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ MTN ati Airtel kede pe awọn jẹ gbese nitori bi awọn nnkan ti wọn fi n ṣiṣẹ ṣe gbowo lori .

MTN kede pe awọn padanu owo ti ko din ni ₦514.9bn laarin oṣu mẹsan an akọkọ ninu ọdun 2024, nigba ti Airtel padanu $89m lọdun 2023.