Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ nílùú Esa Oke, ọlọ́pàá méje fara gba ọta ìbọn

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọlọpaa meje nipinlẹ Osun ni wọn fara kasa ọta ibọn lẹyin ti rogbodiyan kan bẹ silẹ niluu Esa Oke nijọba ibilẹ Obokun lori iyansipo Ọba tuntun.

Iroyin to tẹ Ileeṣẹ BBC News Yoruba lọwọ ni pe iṣẹlẹ yii waye lẹyin ti Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke yan Ọmọọba Timileyin Oluremi Ajayi, ọnimọẹrọ lati ilẹ Gẹẹsi gẹgẹ bii Olojudo ti ilu Ido Ayegunle.

Ohun ti a ri gbọ ni pe awọn eeyan ilu yii ti kesi ijọba pe ko gbe baale ilu sipo Oba gẹgẹ bii Olojudo ti ilu Ido Ayegunle, ko si ma yan olori tuntun fun wọn.

Bakan naa ni wọn bu atẹlu ijọba pe o yan eeyan lati ilu Ilesa lati wa jẹ ọba le wọn loeii.

Osolo ti ilu Esa Oke, Adegboyega Ajiboye ba ileeṣẹ iroyin abẹle Daily Trust sọrọ, to si jẹ ko di mimọ pe awọn eeyan kan ti wọn fi aṣọ boju lo ṣadede yawọ ilu naa, ti wọn si bẹrẹ si ni sina bolẹ.

"Wọn wa pẹlu ọkọ akero bọọsi, ti wọn si bẹrẹ sini sina bọlẹ fun awọn araalu ni Esa Oke, N ko le sọ iye eeyan to ti ba iṣẹlẹ yii lọ nitori mo jina si wọn bayii."

Agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun, Yemisi Opalola fidi iṣẹlẹ naa lasiko to n ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ.

Opelola ni kete ti ileeṣẹ ọlọpaa gbọ si iṣẹlẹ naa ni wọn gbera lọ si ilu naa ṣugbọn ohun ti wọn ba pada ni o fẹ kọja agbara wọn.

"Kete ti a gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni Esa Oke ni Kọmisana ileeṣẹ ọlọpaa paṣẹ fun awọn agbofinro pe ki wọn gbera lọ silẹ.

"Nigba ti wọn n sumọ ilu naa ni wọn ba ilu ti wọn gbe dina, to si n di wọn lọwọ lati kọja.

"Awọn ọlọpaa ka bọ silẹ lati gbe igi naa kuro loju ọna lati le jẹ ki wọn kọja ṣugbọn bi wọn se bọle ni wọn bẹrẹ si ni ma yin ibọn mọ wọn. Ọlọpaa meje ni ibọn ba."

Opelola ni ọwọ tẹ eeyan meji ninu awọn afurasi naa ti iṣẹ si n lọ lọwọ lati mu awọn yooku.