Àwọn aláìmọ̀kan ló ń tako ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ Sharia nílẹ̀ Yorùbá - Shittu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Mínísítà fétò ìbánisọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, Adebayo Shittu ti ní àìmọ̀kan ló ń mú àwọn tó ń tako ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ Sharia ní ẹkùn gúúsù ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà.

Shittu, nígbà tó ń kópa lórí ètò kan lórí amóhùnmáwòrán, ní ọ̀pọ̀ àwọn tó ń tako ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ náà ni kò ní ìmọ̀ kankan lórí ohun tí ìgbìmọ̀ náà jẹ́ àti bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́.

Ní nǹkan bíi ọ̀sẹ̀ mélòó kan sẹ́yìn ni ọ̀rọ̀ ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ Sharia ti ń fa awuyewuye káàkiri ilẹ̀ Yorùbá.

Ní ìpínlẹ̀ Ekiti, níbi tí ìjókòó ìgbìmọ̀ náà ti wáyé lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, ní Ewi ti Ado Ekiti, Oba Rufus Adeyemo Adejugbe ti ránṣẹ́ pé Imam àgbà ìlú Ado Ekiti, Sheikh Jamiu Kewulere, tó sì pàṣẹ pé kí wọ́n tú ìgbìmọ̀ náà ká.

Bákan náà ni àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Yorùbá mìíràn ti ń tako ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ náà ní agbègbè wọn.

Ohun tí wọ́n ń sọ ni pé ọ̀pọ̀ àwọn ìlú tí wọ́n ti ń lo òfin Sharia ni ìpànìyàn àti ìjínigbé pọ̀ níbẹ̀ jùlọ ní Nàìjíríà.

Àwọn olórí ẹ̀sìn Islam nílẹ̀ Yorùbá náà sọ pé ìgbìmọ̀ Sharia tí wọ́n fẹ́ dá sílẹ̀ náà yóò kan máa jẹ́ atọ́nà fún àwọn Mùsùlùmí lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó, ogún pínpín, títú ìgbéyàwó sílẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Shittu nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé láti bíi ọdún mẹ́wàá ni ìgbìmọ̀ yìí ti wà làwọn ìpínlẹ̀ Yoruba kan, tí wọ́n ti ń dá sí ọ̀rọ̀ láàárín àwọn Mùsùlùmí láìsí awuyewuye kankan.

Ó ní àìní ìmọ̀ kíkún nípa ìwé òfin Nàìjíríà ló ń mú kí àwọn gómìnà àti àwọn Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ṣe ń tako ìgbésẹ̀ náà.

"Ọ̀rọ̀ nípa ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ní ìlànà ẹ̀sìn Islam ni nǹkan tó ń jẹ́ Sharia. Ìwé òfin Nàìjíríà sì fàyè gba èèyàn láti ṣe ẹ̀sìn tó bá wù ú.

Ó wòye pé kìí ṣe ohun tó bójú mu fún àwọn tó ṣe ìgbéyàwó ní ìlànà Sharia láti máa lọ sí ilé ẹjọ́ tó jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn ló wà níbẹ̀ láti tú wọn ká nígbà tí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ bá fẹ́ tú ìgbéyàwó wọn ká.

Ó ní ìgbìmọ̀ Sharia yìí ti wà ní ìpínlẹ̀ Oyo àti Eko láti bíi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn tí wọ́n kò sì dí ẹnikẹ́ni lọ́wọ́.

"Ǹjẹ́ wọ́n ti wọ ẹni tí kìí ṣe Mùsùlùmí lọ síwájú ìgbìmọ̀ náà rí tàbí da ẹnikẹ́ni láàmú?

"Gbogbo èèyàn lábẹ́ òfin ló ní ẹ̀tọ́ láti yan ẹ̀sìn tó bá wù ú yálà ní ìlú Ekiti tàbí ibikíbi, èèyàn le mú òfin tó bá wù ú láti fi ṣètò ìgbésí ayé rẹ̀."

Shittu ní ó yẹ kí àwọn Mùsùlùmí làwọn ìpínlẹ̀ tí awuyewuye ti ń wáyé náà yóò gbé ìjọba tàbí ẹnikẹ́ni tó bá ń da àláfíà wọn láàmú lọ sílé ẹjọ́ ni.