You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn ọmọ Naijiria tí kò níwèé ìgbélùú l'America ń sá kiri- Ìwádìí
Awọn ọmọ Naijiria to wa ni orilẹede Amẹrika ti wọn ko ni iwe igbeluu ni wọn ko ni anfani lati rin bo ṣe wu wọn lati igba ti Aarẹ Trump ti kede pe oun yoo fi ọpọ awọn arin irinajo ti ko ni iwe igbeluu sọwọ pada si orilẹede wọn.
Ọpọ awọn eeyan yii lo ni erongba pe o ṣeeṣe ki wọn ma fi wọn sọwọ pada si orilẹede Naijiria titi wọ asiko ti Aarẹ Trump yoo fi yi ipinnu rẹ pada.
Iwadii ti ileeṣẹ iroyin abẹle Punch se fihan pe ọpọ awọn eeyan yii ni wọn ko le lọ si ibi iṣẹ ojọ wọn mọ, ile ijọsin tabi paapa ita gbangba lati naju lati igba ti wọn ti bura fun Aarẹ Donlad Trump gẹgẹ bii Aarẹ kẹtadinlaadọta fun orilẹede Amẹrika.
Ibẹru boju ni ọpọ fi n gbe aye lasiko yii, ti wọn ko si fẹ ko sọwọ awọn agbofinro.
Iwadii naa fihan pe o din ẹgbẹrun mẹrin (3690) ọmọ orilẹede Naijiria ti wọn koju didapada si orilẹede Naijiria lati orilẹede Amẹrika.
Orilẹede Mexico lo n lewaju pẹlu apapọ eeyan 252,044, ti orilẹede El Salvador si n tẹle pẹlu apapọ eeyan 203, 822.
Ẹka idajọ orilẹede Amẹrika ti jẹ ko di mimọ pe awọn setan lati gbe ẹnikẹni, ipinlẹ to igbinyanju lati gbegi dena de aṣẹ Aarẹ Trump lọ si ile ẹjọ.
O le ni eeyan mejidinlogojilelẹẹdẹgbẹta ti wọn gbe kuro orilẹede Amẹrika lọ orilẹede wọn bẹrẹ lati ọjọ kẹtalelogun oṣu kinni ọdun 2025
Lasiko ipolongo ibo ni Trump ti sẹleri lati gbe eto kan kalẹ eyi to yii ri si bi ijọba rẹ yoo ṣe le awọn to n gbe orilẹede Amẹrika lọna aitọ.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Fox News sẹ sọ, Trump yoo paṣẹ pe kawọn ọmogun lọ maa ṣọ ibode guusu orilẹede Amẹrika.
Bakan naa ni Trump tun kede oun yoo fopin si ofin to dena mawọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si wiwọle si Amẹrika lati fọwọ ofin mawọn eeyan nile ṣoọṣi ati lawọn ile ẹkọ.
Lara awọn ofin ti Trump yoo tun fopin si ni awọn to ba bimọ si Amẹrika ti iru awọn ọmọ naa maa di ọmọ ilu Amẹrika.