You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kàyèéfì! Obinrin kan tó ní ilé ọmọ méjì, bí ọmọ méjì láàrin ọjọ méjì
Arabinrin kan ni orilẹ-ede America, to ni ile ọmọ meji, ti bi ọmọ lẹẹmeji ọtọọtọ laarin ọjọ meji.
Kelsey Hatcher, ẹni ọdun mejilelọgbọn, bi ọmọ rẹ obinrin ni ọjọ Iṣẹgun, o si bi ọmọbinrin keji ni Ọjọru, ọjọ kọkandinlogun ati ogunjọ, oṣu Kejila, ọdun 2023, ni ileewosan Fasiti Alabama niluu Birmingham.
Nigba to kede ibi awọn “ọmọ iyanu” naa lori ayelujara, Hatcher gboriyin fun awọn nọọsi ati dokita to gbẹbi rẹ fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe.
Wọn ṣapejuwe awọn ọmọ tuntun naa gẹgẹ bi iru ibeji ti wọn n pe ni ‘fraternal twins’ – iyẹn tumọ si pe ibeji to waye nipasẹ ẹyin ọtọọtọ ati atọ ọtọọtọ.
Eyi jẹ nnkan ti ko fi bẹẹ wọpọ.
Ọkan lara awọn dokita onimọ nipa ilera awọn obinrin, to n ṣiṣẹ nileewosan naa fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni iya ati awọn ọmọ rẹ wa ni alaafia.
O sọ fun BBC pe iru iṣẹlẹ yii jẹ nnkan ti ọpọ dokita le ma ri iru rẹ titi yoo fi fẹhinti lẹnu iṣẹ.
Ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni Arabinrin Hatcher wa nigba ti wọn sọ fun pe ile ọmọ meji lo ni, eyi ti wọn n pe ni Uterus Didelphys.
Arabinrin Hatcher ti loyun pẹlu ile ọmọ kan ṣoṣo nigba mẹta ṣaaju asiko yii.
Nigba to loyun, igbagbọ rẹ ni pe ile ọmọ kan ni oyun naa yoo wa. Ṣugbọn si iyalẹnu rẹ, ayẹwo ultrasound fihan pe ọmọ miran wa ninu ile ọmọ keji.
O ni “niṣe ni mo fẹ daku, o ṣoro fun wa lati gbagbọ”.
Lati igba naa lo ti n kọ bi irinajo rẹ ṣe ri pẹlu aramanda oyun naa sori ayelujara Instagram rẹ.
Ọkan lara awọn dokita to gbẹbi rẹ, Ọjọgbọn Richard Davis, sọ pe ikọọkan awọn ọmọ naa raaye dagba daadaa ninu ile ọmọ ti wọn da wa, nitori pe wọn ko pin aaye kan ṣoṣo lo bo ṣe ma n ri fun awọn ibeji to ku.
Abẹrẹ ni wọn fun Arabinrin Hatcher nigba ti oyun naa pe ọsẹ mọkandinlogoji.
Dokita miran, Patel, sọ fun BBC pe ọgbọn ati imọ ti awọn fi n gbẹbi oyun to ri bo ṣe yẹ, ni awọn lo lati fi gbẹbi rẹ.
“Ilọpo meji oṣiṣẹ si lo gbẹbi fun un.”
Bakan naa lo ṣalaye pe ilana ọtọọtọ ni wọn fi gbẹbi awọn ọmọ naa nitori pe ipo ọtọọtọ ni wọn wa.
Eyi akọkọ, Roxi, gba oju ara iya wọn jade ni nnkan bi aago mẹjọ alẹ ku iṣẹju mẹẹdogun, lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila.
Iṣẹ abẹ ni wọn fi gbe ikeji, Rebel, jade lẹyin wakati mẹwaa.
Nnkan to yẹ ki o mọ nipa ki obinrin ni ile ọmọ meji (Uterine Didelphys)
Awọn onimọ nileewosan naa sọ pe ida 0.3% lo ma n ni iru ile ọmọ bẹẹ laarin gbogbo obinrin l’agbaye.
Bakan naa ni wọn sọ pe ko wọpọ lati fi ile ọmọ mejeeji gbe oyun - ẹyọkan ninu miliọnu obinrin ni iru rẹ ma n ṣẹlẹ si.
Ẹwẹ, iroyin sọ pe iru nnkan bayii ṣọwọn pupọ ni agbaye.
Lọdun 2019, dokita kan ni orilẹ-ede Bangladesh, sọ fun BBC pe obinrin kan bi ibeji lẹyin bii oṣu kan to bi ọmọ kan ti oṣu rẹ ko pe e lati inu ile ọmọ rẹ keji.
Akọsilẹ ti awọn onimọ ni Mayo Clinic kọ ni pe Uteus didelphys jẹ aleebu ti ko wọpọ.
Nigba ti ọmọbinrin ba wa ninu oyun iya rẹ - ile ọmọ yoo kọkọ ma a dagba bi ọpa kekere meji. Bi oyun naa ba ṣe n dagba, ni ọpa mejeeji yoo parapọ di ẹya ara kan ṣoṣo, ile ọmọ.
Amọ nigba miran, awọn ọpa mejeeji kii parapọ daadaa. Dipo bẹẹ, ikọọkan wọn yoo da duro gẹgẹ bi ẹya ara kọọkan.
O ṣeeṣe ki ile ọmọ mejeeji ni ẹnu ọna kan ṣoṣo (cervix) to jade si oju ara obinrin, tabi ki ẹnu ọna naa pin si ọna meji.
Lootọ ni awọn obirin to ba ni ile ọmọ meji ṣaba ma n ru oyun wọn là, amọ ipo agọara wọn ma n fi wọn si inu ewu bibi ọmọ laipe ọjọ.