Ìṣòro ló sún mi débi pé mo ń f'ẹ̀jẹ̀ wẹ̀ - Afurasí

weGaniyu Shina, ọkunrin ẹni ọdun mokandinlaadota ni o ti wa ni akata awọn ọlọọpa bayii, wọn mu u nigba ti o n fi ẹjẹ wẹ ni odo kan ni agbegbe Kotopo, Abeokuta, nijoba ibilẹ Odeda nipinlẹ Ogun.

eGẹgẹ bi atẹjade ti ile iṣe ọlọpa fi lede Arakunrin naa to n gb ni opopona kẹrin, Oguji Street, Obantoko ni ilu Abeokuta, ni wọn mu lẹyin ti awọn ara adugbo kan rii ni eti odo, ti wọn si fi to awọn ọlọpaa leti.

Wọn ni o gbe ọkọ ayọkẹlẹ rẹ Nissan silẹ ̀, ti wọn si ri akerengbe kan to kun fun ohun ti wọn pe ni ẹjẹ ati kainkain ibilẹ ti o si bẹrẹ si ni wẹ ni kete to de eti odo naa.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi ninu atẹjade to fi lede ṣalaye pe ọkunrin naa gbiyanju lati sa nigbati ti o rii wipe awọn eniyan n wo oun ki awọn ara adugbo naa to mu u ti wọn si fa a le ile-iṣẹ ọlọpaa lọwọ.

Nigbati wọn n fọrọ wa a lẹnu wo, afurasi naa sọ pe iṣoro lo sun oun de idi ki oun fi ẹjẹ wẹ, Ganiyu ni ẹjẹ maalu ni o wa lọwọ oun kii se ẹjẹ eniyan.

Komisana ọlọpaa ti ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole, ti paṣẹ pe ki wọn mu ẹjẹ to ku lo fun ayẹwo , lati mo boya ẹjẹ ẹniyan ni tabi ti ẹranko.

Bankole gboriyin fun awọn ara adugbo naa ti o si ṣeleri lati se iwadii afurasi naa doju ami.