Adari tí wọ́n yọ nípò ní Burkina Faso fi ẹsẹ̀ fẹ lọ Togo

Ijọba orilẹede Togo ti kede pe adari ti wọn yọ nipo ni orilẹede Burkina Faso ti wa ni ilẹ wọn.

Eyi ko ṣẹyin bi adari tuntun, Ọgagun Ibrahim Traore ṣe gbajọba lọwọ Ọgagun Paul Henri -Dabima to bọ si ipo ni Oṣu Kini, ọdun 2022.

Aarẹ orilẹede Togo, Akodah Ayewouaden ni awọn gba adari tẹlẹ naa ki alaafia le jọba ni ẹkun wọn.

Ninu fidio ti Damiba fi ranṣẹ si ile lori ẹrọ ayelujara, lo ti ni oun fẹ rere fun adari tuntun, ati pe igba rẹ tu awọn eniyan lara.

O ni oun gba lati fi ipo silẹ nitori adari tuntun naa gba awọn ilakalẹ ti oun fẹ, ki oun to fi ipo silẹ.

Ko si aridaju boya o danikan wa nigba to ṣe fidio naa.

Amọ adari tuntun naa ti kesi awọn minisita lati ṣiṣẹ ni pajawiri fun awọn ipenija to n koju orilẹede naa.

O ni asiko ti to fun ijọba lati mu iṣẹ ṣe ni okunkundun, ki wọn pa imẹlẹ ti.

Awọn onwoye ni adari tuntun naa wa ọna abayọ ni kiakia si awọn iṣoro to n koju ilẹ naa, paapaa ni ẹka ilera, aabo, igbayegbadun awọn eniyan ati awọn ohun ini ijọba.

Wọn o ṣeeṣe ki orilẹede Russia jẹ atilẹyin fun wọn yatọ si orilẹede Faranse to ko wọn lẹrun ni igba naa lọhun.

Ni ọpọ igba ni orilẹede Russia ati Faranse ti ma n fi ori gbari lori ẹni ti yoo ni ajoṣepọ to dan mọran pẹlu awọn orilẹede ni ilẹ Afrika to fi mọ awọn eleyii ti ilẹ Faranse ti jọba le lori lasiko ikọnilẹru.

Adarí ìjọba ológun ní Burkina Faso gbà láti fipò sílẹ̀

Adari ijọba ologun lorilẹede Burkina Faso, Ọgagun Paul-Henri Damiba ti gba lati fi ipo rẹ silẹ lẹyin iditẹgbajọba to mu sa asala fun ẹmi rẹ.

Awọn adari ẹsin ati ilu lo fi iroyin naa lede fun awọn araalu.

Wọn ni adari orilẹede tuntun, Ọgagun Ibrahim Traoré to ditẹ gba ijọba lọwọ Damiba ti gba ko fi ipo rẹ silẹ ati ọna ti yoo gba ṣe bẹ.

Eyi ko ṣẹyin ikọlu si awọn ohun ini orilẹede Faranse to wa ni Burkina Faso, lẹyin ti iroyin ni awọn ni wọn gba a si ọdọ lati doola ẹmi rẹ.

Igba keji rẹ ni ọdun 2022 ti iditẹ gbajọba yoo ma waye ni Burkina Faso.

Ohun ti wọn sọ pe iditẹ gbajọba naa fi n waye ni eto aabo orilẹede naa to dẹnukọlẹ, ti awọn agbesunmọmi si ti gbakoso ibẹ.

O kere tan ida ogoji ilẹ naa ni awọn agbesunmọmi naa ti gba,nigba ti Burkina Faso n sakoso ida ọgọta ilẹ wọn.

Ajọ Iṣọkan ilẹ Afrika ti bu ẹnu atẹ lu iditẹ gbajọba naa, nigba ti Ajọ Ecowas ni igbeṣẹ naa ko dara to nigba ti wọn n gbiyanju lati pada si ijọba tiwantiwa

Awọn alaṣẹ naa ni Damiba fun wọn ni adehun meje ti wọn gbọdọ muṣẹ,ki ohun le fi ipo silẹ.

Wọn ni Damiba gbe igbesẹ naa ki ikọlu le dawọ duro ni awọn ileeṣẹ ilẹ Faranse.

"Mo fẹ kẹ pese aabo to daju fun mi"

O ni wọn gbọdọ ri pe aabo to daju wa fun oun.

Igbesẹ gbọdọ tẹsiwaju lati mu ibaṣepọ to danmọran wa lorilẹede ọhun

Bakan naa ni wọn gbọdọ ri daju pe awọn gbe ijọba pada fun ijọba tiwantiwa laarin ọdun meji.

Adari ti wọn le lori oye naa le aarẹ Roch Kaboré kuro lori oye lori ẹsun pe ko kunjuwọn lati gbogun ti igbesunmọmi ni agbegbe ọhun.

Ọdun 2015 ni igbesunmọmi ti bẹrẹ nibẹ, ti eniyan ẹgbẹgbẹrun si ti ba a lọ, ti awọn eniyan to le ni miliọnu meji si ti di alairile gbe.

Igba kejo niyii ti ikọ ologun yoo gbajọba lorilẹede Burkina Faso lati ọdun 1960 ti wọn ti gba ominira.