You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Inú mi kò dùn bí aráàlú ṣe dáná sun darandaran méjì – El-Rufai
Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai, ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn araalu ṣe pa awọn darandaran meji ni ijọba ibilẹ Birnin-Gwari, ni ipinlẹ naa.
Kọmiṣọna to n ri si eto abo labẹle, Samuel Aruwan sọ fun awọn akọroyin pe ṣe ni awọn araalu naa fi agidi mu awọn darandaran naa.
O ni isẹlẹ yii lo waye lẹyin ti wọn fẹsun kan wọn pe wọn lọwọ ninu igbesumọmi, ti wọn si gba ẹmi wọn.
O ni “Wọn ṣekupa awọn darandaran naa, wọn si tun dana sun wọn, bo tilẹ jẹ pe ko si ẹri aridaju pe wọn lọwọ ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn ọhun.”
Agbofinro, ẹ bẹrẹ iwadii yin lori isẹlẹ yii - El-Rufai
Gomina El-Rufai ni inu oun bajẹ bi awọn araalu ṣe pa awọn darandaran naa.
El-Rufai wa parọwa si awọn mọlẹbi awọn oloogbe ọhun lati ni suuru, o si ke si awọn agbofinro lati bẹrẹ iwadii ni lori iṣẹlẹ naa ni kankan.
Kọmiṣọna naa sọ pe inu gomina El-Rufai ko dun rara si bi wọn ṣe pa awọn darandaran meji ọhun.
O ni “Gomina El-Rufai koro oju si iṣẹlẹ naa, o si parọwa pe ki araalu maṣe maa da ofin ṣe lọwọ ara wọn, ti wọn ba mu awọn afurasi.”
"Ijọba ipinlẹ Kaduna ko ni gba ki araalu maa dajọ iku fun afurasi"
“Gomina ti parọwa si awọn mọlẹbi awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ pe ki wọn ṣe suuru, o si ti ke si awọn agbofinro lati bẹrẹ iwadii.”
“Gomina tun ti paṣẹ fun ileeṣẹ to n ri si eto abo abẹle lati fọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ ọmọ ogun, to fi mọ awọn ọlọpaa ati DSS lati jiroro pẹlu awọn ẹbi awọn oloogbe lọna ati dena irufẹ ikọlu bẹẹ lọjọ iwaju.
O fi kun pe ijọba ti kilọ fun awọn araalu lati jawọ ninu irufẹ iwa bẹẹ.
Aruwan pari ọrọ rẹ pe ijọba ipinlẹ Kaduna ko ni gba ki awọn araalu maa dajọ iku fun awọn afurasi lai fa awọn afurasi bẹẹ le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ.