Àwọn oníṣòwò èròjà ìbóra ti rógo torí àrùn jẹjẹrẹ tó di méjì kọ́bọ̀ – NAFDAC

Ileesẹ to wa fun amojuto oogun, ounjẹ ati ohun mimu nilẹ wa, NAFDAC ti ke gbajare pe arun jẹjẹrẹ ti di tọrọ fọn kale lorilẹede yii.

Nafdac wa di ẹbi isẹlẹ naa ru awọn olookowo to n pese ipara to n bo ara fawọn aralu lọna to lodi sofin.

Ajọ naa ni ọpọ eroja majele fun agọ ara lawọn onisowo ibora naa n po papọ, eyi to le se ijamba fun awọ ara lode ati ninu.

Oludari agba fajọ Nafdac, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye lo ke gbajare bẹẹ lasiko ifikunlukun ọlọjọ meji to waye nilu Eko.

O ni asa ara bibo yii ti wa di gbajumọ laarin awọn ọkunrin ati obinrin ni Naijira, to si ti di tọrọ fọn kale.

"Awọn to n bo ara n gba abẹrẹ Vitamin C ati Glutathione"

Adeyeye, ẹni to gbarata lori bawọn asaloge se n lo majele oloro fawọn onibara wọn lati fi bora tun salaye pe, awọn eroja yii ni wọn n ta lori ayelujara lowo gege.

Bakan naa lo ni awọn onisowo to n polowo iku tantantan kiri ayelujara ọhun, tun maa n lẹdi apo pọ pẹlu awọn dokita onisegun oyinbo lati gun awọn to fẹ bora ni abẹrẹ.

Adeyeye ni lara irufẹ abẹrẹ bẹẹ́ ni wọn lo ni eroja Vitamin C ati Glutathione ninu, eyi tawọn alaimọkan onibara yoo gba lati fi bo ara.

Arun Jẹjẹrẹ, aisan Kidinrin ati ẹdọ fooro ni eroja ara bibo n bajẹ – NAFDAC

Ọga agba fun Nafdac wa sisọ loju rẹ pe ọpọ eroja to ni majele ninu, ti wọn fi n po ọsẹ ati ipara ibora naa papọ, ni wọn n ko wọle lati oke okun.

“Awọn eroja bii Kojic Acid ati Hydroquinone, ti odiwọn wọn kọja eyi to yẹ ko wọnu agọ ara, ni wọn ko fi orukọ wọn silẹ lọdọ ijọba, ti wọn si n ko wọle lati oke okun.

Idi ree ti arun jẹjẹrẹ se di tọrọ fọn kale ni Naijiria nitori awọn majele yii lo n se okunfa rẹ ninu ara, tijọba si ti fofin de eroja Mercury fun ilo awọn asaraloge

Bakan naa, ni awọn eroja ibora oni majele yii maa n se okunfa aisan Kidinrin ati ẹdọ fooro nitori pe o maa n gbogun ti wọn ninu agọ ara ni.’

O wa yan pe ara ti awọn eeyan ba bo loni lee se okunfa arun jẹjẹrẹ lọjọ ọla.

O wa fi ewe ọmọ mọ awọn onisowo iku yii leti pe ki wọn jawọ ninu owo ti ko ni laada ọhun nitori ẹni ti ọwọ Nafdac ba tẹ ninu wọn, yoo foju bale ẹjọ, ti yoo si fi ẹwọn jura.

“O nira fun Nafdac lati gba awọn olookowo ibora mu tori wọn kii patẹ rẹ”

O wa gbarata pe o nira fun ajọ Nafdac lati tete gba awọn apanimayọda onisowo eroja ibora naa mu nitori kiamọsa ni wọn maa n pese eroja naa, ti wọn yoo si ta fun onibara loju ẹsẹ.

O ni ọpọ wọn ni kii patẹ awọn eroja yii sori igba wọn, ki ọwọ awọn osisẹ Nafdac ma baa tẹ wọn.

Adeyeye ni se ni awọn eeyan to n ko awọn eroja ti wọn n po papọ lati fi bo ara yi wọle lati oke okun, maa n gbe pamọ labẹ ilana Global Lisitng, gbe kọja lara Nafdac.

Ọga agba fajọ Nafdac wa fi ọwọ gbaya pe ajọ naa ti n gbe igbesẹ lati fi awọn eeyan kan jofin lori iwa yii, ti ọwọ yoo si tẹ wọn laipẹ.