Wo àwọn orílẹ̀èdè 79 tí Malawi kéde pé wọ́n lè wọ̀ ilẹ̀ wọn láì lo 'visa'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orileede Malawi ti kede pe awọn ti yọ ilana gbigba iwe irina taa mọ si 'Visa' fun awọn arinrinajo lati orileede m ọkandinlọgọrin kan jakejado agbaye.
Igbesẹ yi ni orileede naa lawọn gbe lọna ti mu idagbasoke ba irinajo inaju ati karakata lorileede wọn.
Ikede yi waye ninu iwe aṣẹ ti Minisita fọrọ abẹle ati aabo ilẹ naa Ken Zikhale fi sita lỌjọru.
Ninu rẹ o ni awọn mu iyipada ba ofin to de awọn ọmọ orileede Ilẹ Gẹẹsi,China, Russia,Germany Australia,Canada, Belgium, Ghana, Gambia, Sierra Leone, France ati awọn mii.
O tun fikun pe awọn ọmọ orileede ọmọ ẹgbẹ ajọ idagbasoke orileede Guusu ilẹ Africa, Southern African Development Community (Sadc) ati awọn to wa lati orileede ọmọ ajọ Common Market for Eastern and Southern Africa (Comesa) naa ko ni nilo fisa lati fi wọ orileede wọn.
Wọn fi afikun pe eyi ko mọ awọn orileede to gbe ilana gbigba fisa wọ ilẹ wọn lori awọn ọmọ ilẹ Malawi toba fẹ wọn ilẹ wọn.
Orileede Naijiria ko si ninu awọn ajọ ti wọn darukọ ṣaaju yi.
A ko yi ti ri iwe aṣẹ ijọba naa lati mọ ẹkunrẹrẹ awọn orileede ti yoo jẹ anfaani yi.
Amọ ṣaaju asiko yi awọn ọmọ Naijiria a maa nilo fisa ki wọn to le wọ orileede Malawi.
Bẹẹ naa ni awọn ọmọ orileede Malawi a maa gba fisa ki wọn to wọ Naijiria.
Igba wo ni wọn le fi wa ni Malawi lori fisa yi
Iyipoada ti wọn muba ilana iwe irina yitun sọ pe awọn aṣoju ijọba orileede ati oṣiṣẹ ijọba kọọkan ati awọn orileede to ni adehun paṣiparọ eto iwọle fawọn ọmọ orileede wọn naa yoo jẹ anfaani yi.
Ni bayii ilana tuntun ti wọn gbe kalẹ ti wa sun iye igba ti eeyan le fi fisa wọle ni Malawi si oṣu mejila.
Minisita feto irinajo inaju Vera Kamtukule sọ fun awọn akọroyin pe ''Ipinnu manigbagbe yi kọja ọrọ fisa nikan. A ṣebẹ tori ki awọn eeyan le mọ nipa adun orileede wa ki awọn eeyan sile lanfaani lati wa jẹ igbadun yi fun ara wọn''
Bakan naa ni ileeṣẹ aṣoju orileede Gẹẹsi naa parọwa si awọn eeyan ilẹ wọn lati wa jẹ ninu anfaani idẹkun fisa ọfẹ yi lati le fi ṣabẹwo si awọn aaye inaju to wa lorileede ọhun.
Wn ko sọ boya awọn naa yoo dẹ ilana gbigba fisa fun awọn ọmọ orileede Malawi to ba fẹ wa ṣabẹwo si orileede wọn.
Awọn orileede Africa ti o dẹ ilana wiwọle lai gba fisa
Malawi naa ti wa darapọ mọ awọn orileede mii lorileede Africa to ṣi lẹkun wọn gbagada ki awọn eeyan ilẹ mi wle lai lo fisa.
Awọn orileede meji ni ila oorun Africa, Kenya ati Rwanda ti ṣaaju kede pe awọn fi anfaani silẹ fawọn eeyan Africa lati wa silẹ wọn lae lo fisa.
Bẹẹ naa ni orileede Benin, Seychelles ati Gambia.
Laarin ara wọn Ghana ati South Africa tọwọ bọ iwe adehun ki awọn ọmọ orilẹede wọn maa wọ ilẹ ara wọn lae lo fisa.
Ni iwọ oorun ilẹ Africa anfaani irinajo lae lo fisa wa fun awọn ọmọ ẹgbẹ Ecowas ṣugbọn kii ṣe fun gbogbo ọmọ ilẹ adulawọ.
Eredi igbesẹ yi lọpọ igba ni ki awọn eeyan lanfaani lati ṣe irinajo inaju ti yoo mu owo wọle fun orileede naa.












