Kí ló ń fa ìjà láàárín Donald Trump àti Elon Musk tí wọ́n fi ń tahùn síra wọn?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ki ni yoo ṣẹlẹ ti ija ba waye laarin ẹni to lowo julọ ati ẹni to lagbara julọ?

Eyii lo difa fun ija to n waye lọwọlọwọ laarin baba olowo Elon Musk ati ọrẹ rẹ to tun jẹ Aarẹ Amẹrika, Donald Trump.

Ija to n waye laarin awọn ọrẹ meji yii ti di ojukaye latari bi awọn mejeji ṣe n fi ohun ranṣẹ si ara wọn lori ayelujara ati niwaju awọn akọroyin.

Ija naa bẹrẹ lẹyin ti Trump sọ pe Musk ja oun kulẹ nipa awọn ọrọ kan to n sọ tako awọn igbesẹ oun lori abadofin ọrọ owo ori ati owo nina.

Nigba ti yoo fesi, Musk sọ pe alaimoore ni Trump nitori yoo lulẹ ninu eto idibo ilẹ Amẹrika lai si atilẹyin oun.

Amọ ṣa, lẹyin gbas-gbos aarin awọn mejeji, wọn ti n sọrọ bii pe wọn yoo ti ida wọn bọ akọ.

Eyii ko ṣẹyin bi Trump ṣe sọ fun ileeṣẹ iroyin rẹ, Politico, pe "Ko si wahala, ko si wahala, gbogbo nnkan n lọ bo ṣe yẹ."

Ni ti Musk, o sọ fun Bill Ackman to jẹ ọkan gboogi lara awọn alatilẹyin Trump nigba ti Ackman sọ fun pe ki wọn peri ija pe "Ootọ lo sọ, ko si irọ kankan nibẹ."

Asiko ti ariyanjiyan bẹrẹ ni igba ti Trump n duro ki ile aṣofin agba ilẹ naa buwọlu abadofin tuntun nipa ọrọ owo ori ati owo nina l'Amẹrika.

Lẹyin akoko diẹ ti Musk kuro nileeṣẹ to n bojuto bi ijọba ṣe n ṣe daadaa si, Department of Goment Efficiency (Doge) lo fi ẹnu tabuku abadofin naa.

Musk sọ loju opo X rẹ pe eewọ ni abadofin ọhun ati pe o yẹ ki oju ti gbogbo awọn to fọwọ si.

Ninu awijare Musk, abadofin naa tunbọ mu ki alekun ba iye gbese ti ijọba Amẹrika ti jẹ tẹlẹ ni.

Amọ ọrọ naa ko dun mọ Trump ninu.

Nibi ipade awọn akọroyin kan pẹlu olori ijọba France, Friedrich Merz, Trump sọ pe "Musk ti ja mi kulẹ nitori o mọ ohun gbogbo to yẹ nipa abadofin yii ju gbogbo awọn to joko sibi yii lọ, lojiji ni ko faramọ abadofin naa mọ."

Ibadọreẹ Trump ati Musk pọ si lẹyin ti ọkunrin kan gbiyanju lati gbẹmi Trump ninu oṣu Keje ọdun to kọja ni Pennsylvania.

Ọkunrin ọhun yinbọn si Trump lati orule ile kan amọ ni ṣe ni ọta ibọn naa fẹ eti Trump dipo ko gbẹmi rẹ bi afurasi naa ṣe lero.

Lẹyin naa ni Musk gbe $290m kalẹ fun ipolongo Trump pe dandan ni ko pada si White House to jẹ ile ijọba Amẹrika.