Mo fẹ́ kí wọ́n sìnkú mi láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́rin tí mo bá jáde láyé - Ayodele Fayose

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina nigba kan ri nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose ti jẹ ko di mimọ pe oun fẹ ki wọn sin oku oun laaarin ọsẹ mẹrin ti oun ba jade laye, o tun sọ bi o ṣe fẹ ki eto isinku rẹ waye.
Ninu fidio kan to lu sita lori ayelujara, loju opo City Edge TV, lọjọ Ṣatide, Fayose, ẹni to pe ẹni ọdun marundinlaadọrun lọjọ Ṣatide, Ọjọ kẹdogun, oṣu kọkanla, ọdun 2025, ni ijọba ipinlẹ Ekiti lo gbọdọ se amojuto eto isinku oun.
Fayose ni, "Ẹ ranti mi fun eyikeyi ti ẹ ba fẹ. Ati pe ti mo ba ku, ẹ jẹ ki n sọ eyi. Iku o ṣe yẹ, ijọba ipinlẹ Ekiti lo ni oku mi… mo n kọ lẹta si gomina.
"Fun awọn gomina to n bọ lọjọ iwaju, ijọba ipinlẹ Ekiti lo gbọdọ se akoso oku mi, ti wọn si gbọdọ sin mi laaarin ọsẹ mẹrin nitori ijọba le ma le gbaradi fun ọjọ meji si mẹta, ṣugbọn mo n fun wọn ni ọsẹ mẹrin.
Bakan naa ni Fayose tun fi ọrọ ransẹ si awọn ọmọ rẹ lori ohun ti wọn ni lati ṣe lasiko eto isinku ati ibi ti wọn yoo sin si i.
Fayose ṣalaye, " Si awọn ọmọ mi, wọn gbọdọ wọ aṣọ kana pẹlu awọn mọlẹbi, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati se ohun to yẹ.
"Mo kọ agbala kan si ile iya-iya mi, ibẹ ni mo fẹ ki wọn sin mi si lẹyin ti mo ba jade laye.
"Ẹnikẹni ko gbọdọ wa mi wa lẹyin ti mo ba ku,ti mo fẹ sin mi. Ti o ba ni nnkan ti o fẹ ṣe fun mi, asiko ree lati ṣe."
Ohun to ye ko mọ nipa Ayodele Fayose
Orukọ abisọ rẹ ni Peter Ayodele Fayose, ti wọn si bi ni ọjọ kẹdogun oṣu kọkanla ọdun 1960 niluu Ibadan to jẹ olu ilu ipinlẹ Oyo.
O jẹ ọmọ ipinlẹ Ekiti, lati ijọba ibilẹ Irepodun/Ifelodun.
Fayose jẹ oloṣelu, to fi jẹ gomina ipinlẹ Ekiti fun igba meji labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP
Yatọ si oloṣelu, Fayose jẹ onisowo.















