You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Seyi Makinde tí yí orúkọ fásitì Tech-U padà sí orúko Abiola Ajimobi
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti da gomina tẹlẹ to doloogbe lọla nipa yiyi orukọ fasiti pada si orukọ Abiola Ajimobi.
Fasiti imọ awọn oniṣẹ ọwọ ti wọn pe orukọ rẹ ni Tech-u ni wọn yipada si orukọ Abiola Ajimobi.
Makinde lo sọ eyi lasiko to n ba awọn akẹkọjade sọrọ ni ibi ayẹyẹ ikẹkọjade ti ẹlẹẹkeji ni fasiti naa.
Gomina ọhun ni gbogbo nkan ni asiko wa fun asiko lati lawari nkan, asiko lati wo ohun to padanu.
Bakan naa lo ṣalaye wi pe gbogbo ẹda lo n gbimọ lati mu imọ rere rẹ ṣẹ lagbaye.
O fikun un pe ẹẹmẹta ni oun dije dupo gẹgẹ bi gomina ti oun si fidi rẹmi, amọ ẹlẹkẹrin ni oun jawe olubori.
Gomina Makinde tun ṣalaye fun awọn olugbọ rẹ igbesẹ to gbe lati ri iṣẹ ni ileeṣẹ iwa epo Shell Oil company, lati bi oun ṣe lakaka lati di ipo gomina mu ni ipinlẹ Ọyọ
Gomina naa wa rọ awọn akẹkọọ lati foju si iwe wọn ki wọn si tun gbiyanju lati jẹ ẹni to n gbani si iṣẹ ki wọn ye wa iṣẹ kiri.
Alága Káńṣù àti Káńsélọ̀ tí Seyi Makinde yọ nípò pe ẹjọ míì, ilé ẹjọ́ gbẹ́sẹ̀ lé àpò owó báǹkì ìjọba Oyo mẹ́rin
Ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja ti pàṣẹ pé kí àwọn ilé ìfowópamọ́ mẹ́rin kan gbẹ́sẹ̀ lé akoto owó ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo.
Ohun tí àṣẹ yìí túmọ̀ sí ni pé ìjọba Oyo kò ní lè gba owó nínú akoto àwọn ilé ìfowópamọ́ yìí tí owó náà bá ti dín ní ₦3.4bn.
Àwọn ilé ìfowópama tí ọ̀rọ̀ náà kàn ni First Bank, United Bank for Africa (UBA), Wema Bank àti Zenith Bank.
Owó tí ilé ẹjọ́ gbẹ́sẹ̀ lé náà wà láti fi san gbèsè tí ìjọba jẹ àwọn alága tẹ́lẹ̀ náà - Agbẹjọ́rò
Adájọ́ A. O. Ebong gbé ìdájọ́ yìí kalẹ̀ lórí bí ìjọba Oyo lábẹ́ ìṣàkóso gómìnà Seyi Makinde, kò ṣe san owó àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ àtàwọn káńsélọ̀ tó fọwọ́ òsì júwe ilé fún lẹ́yìn tó gba ìjọba lọ́dún 2019.
Àwọn mẹ́ta nínú àwọn alága tẹ́lẹ̀ náà, Bashorun Majeed, Bosun Ajuwon àti Idris Okusesi ló ṣaájú pe ìjọba Oyo lẹ́jọ́ lórí bí ìjọba ṣe dá wọn dúró lọ́nà àìtọ́.
Gẹ́gẹ́ bí ìdájọ́ náà ṣe sọ, àwọn owó tí ilé ẹjọ́ gbẹ́sẹ̀ lé náà wà láti fi san gbogbo gbèsè tí ìjọba jẹ àwọn alága tẹ́lẹ̀ rí náà èyí tí Makinde dá dúró nígbà tí sáà wọn kò ì tíì pé.
Agbẹjẹ́rò àwọn alága àti káhúnsílọ̀ tẹ́lẹ̀ rí náà, Musibau Adetunji, SAN, ní àwọn pé ẹjọ́ láti dá ìjọba Oyo dúró láti máa rí owó gbà ní akoto wọn nítorí àti san owó tí ìjọba Oyo jẹ àwọn oníbàárà òun.
Ó ní ìgbésẹ̀ náà wáyé lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ti pàṣẹ fún ìjọba Oyo láti san gbogbo owó oṣù tó yẹ kí àwọn Alaga naa gbà ní ọ́fíìsì, padà fún wọn.
Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?
Ní ọjọ́ keje, oṣù karùn-ún ọdún 2021 ni ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Supreme Court dájọ́ pé kí ìjọba Oyo san owó oṣù tó yẹ fún àwọn alága tẹ́lẹ̀ rí náà nítorí ọ̀nà àìtọ́ ni ìjọba fi yọ wọ́n.
Ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹta ọdún 2018 ni wọ́n dìbò yan àwọn alága tẹ́lẹ̀ rí náà fún sáà ọlọ́dún mẹ́ta ṣùgbọ́n tí Seyi Makinde dáwọn dúró nígbà tó gba àkóso ìjọba Oyo lọ́dún 2019.
Lẹ́yìn náà ni àwọn alága náà gba ilé ẹjọ́ lọ láti lọ tako ìgbésẹ̀ gómìnà Seyi Makinde bí wọ́n ṣe ní ìgbésẹ̀ rẹ̀ kò bá òfin mu tí ilé ẹjọ́ sì ní Makinde jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án.
Ṣùgbọ́n síbẹ̀ Makinde ṣe ìdádúró àwọn alága àtàwọn káhúnsílọ̀ náà, tó sì gba ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lọ láti lọ tako ìdájọ́ ìdájọ́ ilé ẹja gíga Oyo.
₦4.2bn ni àpapọ̀ owó tí Makinde jẹ àwọn Alága àti Káńsélọ̀ tẹ́lẹ̀ naa, tó sì san ₦1.5bn
Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní ọjọ́ Kẹẹ̀dógún oṣù Keje ọdún 2020 dájọ́ tako àwọn alága ọ̀hún, tó sì ní ìjọba Oyo ṣe ohun tó tọ́.
Àwọn alága yìí náà tẹ̀síwájú láti lọ sí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ láti tako ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí adájọ́ Kudirat Kekere-Ekun sì dájọ́ pé ìgbésẹ̀ Makinde tako ìlànà ìjọba àwaarawa.
O ni Makinde sì gbọdọ̀ san gbogbo owó oṣù àti àjẹmọ́nú tó yẹ kí àwọn alága náà gbà fún gbogbo àsìkò tó yẹ kí wọ́n lo nípò fún wọn.
Àpapọ̀ gboogbo owó náà ló jẹ́ ₦4.2bn.
A ti ń san owó náà díẹ̀díẹ̀, ọ̀wọ́n gógó náírà ló dá wa lọ́wọ́ kọ́ lásìkò yìí – ìjọba Oyo
Wàyí ò, ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti fèsì sí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga Abuja tó fòfin de akoto owó àwọn nítorí gbèsè tí àwọn jẹ àwọn alága tẹ́lẹ̀ rí náà.
Kọmíṣọ́nà fétò ìdájọ́ ìpínlẹ̀ Oyo, Ọ̀jọ̀gbọ́n Oyelowo Oyewo ní kìí ṣe wí pé ìjọba kọtí ọ̀gbọ̀in sí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ nítorí àwọn ti ń san owó náà díẹ̀díẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Oyewo ní nínú ₦4.2bn, ìjọba Oyo ti san ₦1.5bn, tí àwọn sì ń ṣètò láti san ìyókù kí ọ̀wọ́n gógó náírà àti ètò ilé ìfowópamọ́ àgbà CBN, tó ṣe àkóbá fún àwọn.
Ó ní ìjọba ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tako ìdájọ́ náà nítorí ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja kò ní ẹ̀tọ́ láti gbọ́ ẹjọ́ náà.
Ó fi kun pé àwọn ti ní àjọsọ pẹ̀lú àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn láti máa san owó náà díẹ̀díẹ̀ èyí tí àwọn ti ń ṣe àti pé àwọn máa lọ gba àṣẹ ilé ẹjọ́ láti yí ìdájọ́ náà padà.