Wo àwọn gbankọgbì ìṣòro márùn ún tó ń dúró de Tinubu lórí àléfà

    • Author, Olumide Owaduge
    • Role, Broadcast Journalist

Ọpọ eeyan lo gbagbọ pe Naijiria lo n leke tente laarin awọn orilẹ-ede nilẹ adulawọ nitori bi iye eeyan rẹ ṣe pọ to, amọ ori nla kọ ni ọmọ fi n mọ iwe.

Bi Naijiria ṣe tobi to ti awọn eeyan inu rẹ si pọ to naa ni isọrọ rẹ pọ, lara awọn iṣoro naa ni yoo koju Aarẹ tuntun ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan, Bola Tinubu.

BBC ṣe akojọpọ awọn iṣoro marun un ti yoo koju iṣẹjọba Tinubu to ba gori alefa.

Fifopin si owo iranwọ epo bẹntiro

Bo tilẹ je Naijiria ni epo rọbi, orilẹ-ede mii lo ti n fọ epo ọhun, ọpọ owo gọbọi lo si fi n ko epo naa pada wọle.

Eredi ree ti ijọba fi n ṣe iranwọ lori epo naa, amọ akoba nla ni owo iranwọ ọhun n ṣe fun eto ọrọ aje ilu.

Lasiko ijọba Goodluck Jonathan lọdun 2012 to gbiyanju lati fopin si iranwọ owo epo naa, iwọde nla lo gba gbogbob awọn ilu nla kan ni Naijiria.

Wayi o, Tinubu ti sọ pe oun yoo fopin si owo iranwọ naa ti oun ba de ori alefa, ọpọ araalu lo ti n si woye ọgbọn ti yoo da si ati bi nnkan yoo ṣe to ba gbe igbesẹ naa tan.

Bi abala kan ninu awọn araalu ko ṣe fẹ Tinubu nipo

Yatọ si awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, awọn abala eeyan kan ti ko fẹ ri imi Tinubu laatan ni awọn “OBIdients” ti wọn jẹ alatilẹyin Peter Obi, to dije du ipo ninu ẹgbẹ oṣelu Labour.

Pupọ ninu awọn “OBIdients” naa ni wọn jẹ ọdọ, ti awọn mii ninu wọn si jẹ ẹya Igbo ni wọn gbagbọ pe INEC padi apo pọ pẹlu Tinubu lati ṣe makaruru ninu eto idibo to gbe wọle.

Tinubu yoo ni lati wa ọna fati a oju awọn eeyan naa mọra ki ọkan rẹ le balẹ lori oye.

Atunṣe eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ

Lootọ ni pe ẹkọ nipa eto iṣiro ni Tinubu kọ amọ nnkan ko tii buru bayii ri ninu itan Naijiria.

Ọkan lara awọn to sunmọ Tinubu, Seye Oyetade, sọ fun BBC pe iṣoro ti Naijiria n dojukọ kii ṣe nnkan ti Tinubu ko le yanju.

O ni iṣoro to wa ni Naijiri lonii farajọ irufẹ nnkan to ba nilẹ lasiko to di gomina ipinlẹ Eko lọdun 1999.

Ijinigbe ati eto abo to mẹhẹ

Lara awọn ọdaran ti Tinubu yoo ni lati ṣẹgun ni Boko Haram, agbebọn, atawọn ajinigbe ni iha Ariwa, to fi mọ awọn agbebọn ‘Unknown Gunmen’ ni Ila oorun atawọn afurasi Fulani darandaran.

Lasiko ipolongo ibo, igbakeji Aarẹ, Kashim Shetima sọ pe oun yoo lo iriri oun gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Borno nigba kan ri nibi ti Boko Haram gbilẹ si lati tan iṣoro eto aabo.

Amọ nnkan ti yipada ni ẹka eto abo Naijiria bayii yatọ si ti ọdun 2019 ti Shetima ti kuro lori oye gẹgẹ bii gomina Bornu.

Ilera Tinubu atawọn ọrọ mii to n jẹyọ

Lara awọn nnkan ti awọn ti ko fẹran Tinubu maa n sọ ni pe ko gbadun, bẹẹni okun rẹ ko to lati tukọ orilẹ-ede nla bii Naijiria.

Lẹyin eto idibo to kọja, Tinubu ti rinrinajo lọ soke okun nigba meji ọtọtọ, eyii ti ọpọ gbabọ pe o lọ fi gba itọju.

Amọ awọn alatilẹyin rẹ ni oun nikan ni oludije to ṣe ipolongo ibo kaakiri gbogbo ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria ṣaaju eto idibo naa.

Yatọ si ilera Tinubu, ọrọ mii ti awọn tun n jẹ lẹnu ni pe o ni iwe irinina orilẹ-ede Guinea, yatọ si ti Naiiiria, eyii to lodi sofin fun ẹni to ba fẹ di ipo Aarẹ mu.

Amọ awọn amugablẹgbẹ rẹ ti ni ahesọ ọrọ lasan ni ohun ti awọn alatako n gbe kiri, ko si ni dina rẹ lati tun Naijiria ṣe.