Odò kan rèé tí ọmọ ìlú máa ń bù lọ sí ìlú míràn láti dáàbo bo ara wọn lọ́wọ́ ìkọlù èèyàn tàbí àìsàn

Àkọlé fídíò, Ikiso River: Odò yìí kìí gbẹ lásìkò ẹ̀ẹ̀rùn, kìí gbé èèyàn lọ, ó ń fa òjò, bí ọ̀dá bá wà
Odò kan rèé tí ọmọ ìlú máa ń bù lọ sí ìlú míràn láti dáàbo bo ara wọn lọ́wọ́ ìkọlù èèyàn tàbí àìsàn

Idalu ni iselu, ohun to kọ oju si ẹnikan ninu ilu kan, ẹyin lo kọ si ilu miran.

Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ Kayeefi lo wa nilẹ Yoruba amọ awọn kayeefi to wa nilu ilu kan ti wọn n pe ni Sàwọ́njọ ṣe ara ọtọ.

Yatọ si pe ole kii ja ninu ilu naa, (Gẹgẹ bi a ti mu wa fun yin saaju,) odo kan tun wa nibẹ ti a le se apejuwe rẹ bii odo agbọmọla.

Orukọ odo naa ni odo Ìkíṣọ́, eyi to n se ọpọ anfaani fun awọn ara ilu naa.

Lasiko abẹwo BBC Yoruba si ilu Sawọnjọ, a de idi odo Ikisọ naa lati mọ nipa odo pataki yii.

Gẹgẹ bi a se gbọ, odo Ikísọ yii ni ọn fi orukọ iyawo ẹni to da ilu Sawọnjọ silẹ sọri rẹ, ẹni to n jẹ Ikisọ.

Ki wa ni pataki odo naa sawọn ara ilu Sawọnjọ, awọn anfaani manigbagbe wo lo ti n se fun wọn lati ẹyin wa titi di oni, eyi ti wọn fi maa n bọ bọ?

BBC Yoruba se ẹkunrẹrẹ iwadi nipa odo Ikisọ naa, ẹ maa ba wa kalọ.

Odo Ikiso

"Omi odo Ikisọ maa n daabo bo awa ọmọ ilu lọwọ aisan, omi yii si ni wọn yoo bu lọ si ojubọ oriṣa koriṣa ti wọn ba fẹ bọ"

Lasiko ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, ọpọ ọmọ ilu Sawọnjọ salaye pe odo gidi, ti ko se fi sere nitori ọpọ anfaani to n fun awọn, ni odo Ikisọ.

"Pataki odo Ìkísọ́ ni pe bi ojo ko ba rọ ni aarin ilu laarin ilu, awọn obinrin yoo pọn omi ninu odo yii, wọn yoo lọ da si oju adogan.

Bi omi yẹn ba ti lee san de oju odo Ikisọ pada, ojo yoo maa pa awọn obinrin yẹn ki wọn to dele ni.

Odo gidi ni odo yii, odo to wulo gan ni, bi ara ba n ro wa, ti a ba ti ja lu inu rẹ, ti a si wẹ, gbogbo nnkan to n se wa yoo lọ.

Ko si gbogbo orisa to wa nilu Sawọnjọ yii, ti wọn ba fẹ bọọ, wọn yoo ni ki wọn lọ bu omi odo yii wa ni.

Omi Ikisọ ni wọn yoo kọkọ ta silẹ ni ojubọ orisa yẹn, ki wọn maa bọọ.

Bakan naa, omi odo Ikisọ yii maa n daabo bo awa ọmọ ilu lọwọ aisan kaisan kankan.

Ọpọ eeyan lo maa n lọ si oju odo Ikisọ lati fọ asọ wọn tori kii ba asọ jẹ."

Omi Ikiso

"Bi a ba n lọ sibi kan, a maa n fi omi Ikisọ dẹru ba awọn eeyan to ba fẹ se ijamba fun wa, ti a ba sọ fun pe bayi lo maa ri fun, bẹẹ naa si lo maa ri fun"

Bakan naa ni BBC Yoruba gbọ pe awọn eeyan kan tiẹ wa nilu Sawọnjọ, to jẹ pe omi odo Ikisọ nikan ni wọn maa n mu, ti wọn ko si fẹran lati maa mu omi kanga.

"Awọn iya kan ti ẹ, ti wọn kii mu omi kanga, bi o tilẹ jẹ pe kanga pọ pupọ ninu ilu wa, amọ omi odo Ikisọ ni wọn maa n mu.

Koda, awọn ọmọ ilu Sawọnjọ gan to n gbe lẹyin odi, maa n rọ omi odo Ikisọ yii lọ si ilu ti wọn n gbe lọ sibi ti wọn n gbe.

Bi ohunkohun ba n se wọn tabi ọmọ wọn ti wọn ba fi lee fi omi yẹn wẹ fun ọmọ naa, ara rẹ yoo ya.

Koda, bi awa ba n lọ sibi kan, a maa n fi dẹru ba awọn eeyan pe a pe omi Ikisọ dani, to ba fẹ se ijamba fun wa, ti a ba sọ fun pe bayi lo maa ri fun, bẹẹ naa si lo maa ri fun.

Ni ọdun ti wọn ti bi mi, ti mo si gbọnju, odo yii ko gbẹ ri. Asiko ẹẹrun gan lo maa n kun si daadaa, ti omi ko si da wa laamu ri ki kanga to de.

Omi yii kii gbe eeyan lọ, tori rẹ la se maa n bọ ọ, odo yii dara ju."