Ṣé lóòótọ́ ni àwọn agbéṣùmọ̀mí bẹ́ orí alága CAN ti ìpínlẹ̀ Adamawa?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Adamawa ti jiyàn ìròyìn kan tó gba orí ayélujára pé àwọn agbéṣùmọ̀mí gé orí alága ẹgbẹ́ àwọn Kristẹni ìyẹn Christian Association of Nigeria, CAN, tẹ̀ka ìpínlẹ̀ náà.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, Suleiman Yahaya Nguroje nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kọkànlá, ọdún 2025 júwe ìròyìn náà èyí tí ẹnìkan, Lionman Lioni gbé sórí ìkànnì Facebook rẹ̀ bí ọ̀nà láti dá ìjà ẹ̀sìn sílẹ̀.

Nguroje ní ìgbésẹ̀ náà jẹ́ ìgbìyànjú láti dá ìbẹ̀rù sọ́kàn àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ náà ni.

Ó sọ pé Kọmíṣánnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Adamawa, Dankombo Morris ti jiyàn ìròyìn náà, tó sì ní irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò wáyé ní ìpínlẹ̀ náà rárá.

Ó wá rọ àwọn aráàlú náà láti kọtí ọ̀gbọ̀in sí ìròyìn òfégè náà àti pé kí wọ́n máa ṣe àgbéyẹ̀wò ìròyìn dáadáa kí wọ́n tó máa tàn án ká.

Ó fi kun pé ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ láti ṣàwárí àwọn tó ń gbé ìròyìn òfégè bẹ́ẹ̀, tí wọ́n yóò sì ri pé àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ yóò fojú winá òfin.

Láyọ̀ àti àlááfíà ni alága wa wà - CAN Adamawa

Bákan náà ni ẹgbẹ́ CAN tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Adamawa náà ti rọ àwọn èèyàn láti kọtí ọ̀gbọ̀in sí ìròyìn tó ń jà lórí ayélujára pé àwọn agbéṣùmọ̀mí gé orí alága ẹgbẹ́ náà.

Àtẹ̀jáde kan tí alága CAN ti Adamawa fi léde fúnra rẹ̀ sọ pé àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kan ló mọ̀ọ́mọ̀ fi ìròyìn náà léde láti fi tàbùkù ìjọba àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò.

CAN ní àwọn tó gbé ìròyìn náà síta mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ láti fi dá hílàhílo sílẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tó ń kojú awuyewuye lórí ẹ̀sìn lọ́wọ́.

Àtẹ̀jáde náà sọ pé alága náà, Ẹni ọ̀wọ̀ Joel Manzo wà ní àlááfíà pípé, wà láyé láàyè àti pé ó ń bá iṣẹ́ oójọ̀ rẹ̀ lọ láì sí ìbẹ̀rù tàbí ìfòyà kankan.

Bákan náà ni wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fún àtẹ̀jáde tí wọ́n gbé jáde láti fi jiyàn ìroyìn náà, tí wọ́n sì rọ̀ wọ́n láti ṣe ìwádìí àwọn tó wà nídìí ìròyìn òfégè ọ̀hún.

Láti bíi ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn báyìí ni àwọn èèyàn Nàìjíríà ti wà nínú inú fu àyà fu lẹ́yìn Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump kéde láti ṣe ìkọlù sí Nàìjíríà lórí ẹ̀sùn pé àwọn alákatakítí ẹ̀sìn Islam ń pa àwọn Kristẹni lọ́nà àìtọ́.