Lẹ́yìn tí Biden ti kéde àtìlẹyìn fún Harris, kí ló kàn ṣáájú ètò ìdìbò?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Aarẹ Joe Biden ti juwọlẹ ninu idije fun saa keji gẹgẹ bii Aarẹ Amẹrika, to si kede atilẹyin rẹ fun igbakeji rẹ, Kamala Harris lati jẹ ẹni ti yoo soju ẹgbẹ oṣelu Democrats ninu eto idibo to n bọ.

Igbesẹ yii lo waye ni o ku oṣu kan ti ipade apero ẹgbẹ oṣelu naa yoo waye nibi ti wọn yoo ti ma kede ẹni ti yoo gba asia ẹgbẹ oṣelu naa lati kopa ninu eto idibo.

N jẹ Biden si ni Aarẹ Amẹrika?

Bẹẹni, o kan fopin si iponlongo ipadasipo rẹ gẹgẹ bii Aarẹ ninu eto idibo to n bọ ninu oṣu kọkanla.

O ti se ileri pe oun yoo wa ni ipo Aarẹ titi di oṣu kinni ọdun 2025 nigba ti wọn yoo ma burawọle fun oludije to ba bori.

Ẹwẹ, ọpọ ipe lo ti wa lati ẹgbẹ oṣelu alatako, paapa lati ọdọ olori ile igbimọ aṣofin, Mike Johnson pe ki Biden kuro lori ipo bayii.

N jẹ Kamala Harris ni oludije fun ipo Aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu Democrats?

Ko si aridaju kankan pe Igbakeji aarẹ Kamala Harris ni yoo bọ si ipo Biden gẹgẹ bii oludije fun ipo aarẹ ẹgbẹ oṣulu Democrats.

Bo ti lẹ jẹ pe Biden i fi ontẹ lu Harris pe ko gba ipo oun gẹgẹ bi oludije, o si wa lọwọ awọn ẹgbẹ lati pinnu lori eeyan ti wọn fẹ se atilẹyin fun.

Bẹẹ ba gbagbe, Harris wa pẹlu Biden gẹgẹ eeyan ti wọn jọ dije pọ, ti ibuwọlu Biden si ti n jẹ ko da bi pe Harris ni wọn yoo gbe asia fun lati dije.

Lọdun 1968 ni irufẹ iṣẹlẹ yii waye lasiko iṣejọba Baines Johnson, ẹni ti oun naa juwọle ninu idije dupọ aarẹ.

Se awọn oludije mii jade sita ati pe bawo ni wọn yoo se mu eeyan ti yoo dije?

Bi ọpọ ipe se n jade pe ki Aarẹ Biden juwọlẹ kuro ninu idije Aarẹ, ọpọ awọn eeyan lo ti fi ifẹ han lati rọpo Aarẹ Biden.

Gomina Michigan, Gretchen Whitmer ni ẹnu kọkọ kun botilẹ jẹ pe o sọ pe oun ko ni jade dupo ti Aarẹ ba ni oun ko ṣe mọ.

Lọjọ Aiku, lẹyin isẹju diẹ ti Aarẹ Biden gbe ikede sita , o sọ pe oun yoo lo gbogbo agbara to ni lati ri pe oludije Democrats lo wọle, ti Trump yoo si fidi janlẹ.

Awọn ọmọ ẹgbẹ mii ti ẹnu n kun ni Gomina California, Garvin Newsom, Akọwe fun eto irinna, Pete Buttigieg ati Gomina Pennsylvania, Gomina Josh Shapiro.

Ipade gbogbo ẹgbẹ oṣelu Democrats yoo wate ni ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹjọ, nibi awọn ọmọ yoo ti ma dibo lati mọ ẹni ti yoo soju wọn.

Awọn oludije yoo milo ibuwọlu toto ọọdọrun lati fi ọrukọ wọn sinu iwe idibo.

Joe Biden fa Kamala Harris kalẹ̀ láti díje du ipò Ààrẹ Amẹrika

Aarẹ Amẹrika, Joe Biden ti kede igbakeji rẹ, Kamala Harris, gẹgẹ bii ẹni ti oun ṣatilẹyin fun lati dije du ipo Aarẹ labẹ aisa ẹgbẹ oṣelu Democrat.

Ana ode yii ni Biden kede pe oun ko ni dije fun saa keji mọ gẹgẹ bii Aarẹ Amẹrika.

Igbesẹ Biden ọhun ti da omi tutu sọkan awọn kan ninu ẹgbẹ oṣelu naa bayii to oṣu kan ṣoṣo ki wọn ṣe ipade gbogbogbo ẹgbẹ naa to maa n waye ṣaaju eto idibo.

Ọjọ karun un, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii eto idibo Aarẹ naa yoo waye.

Awọn to ṣeeṣe ko tako Kamala Harris

Lati igba ti awọn ọmọ ẹgbẹ kan ti n ke si Aarẹ Biden ko juwọ didu ipo fun saa keji silẹ lawọn eeyan kan ti n yọju pe awọn naa nifẹ lati du ipo ọhun.

Lara wọn ni gomina ipinlẹ Michigan, Gretchen Whitmer, ti oun naa jẹ obinrin.

Ni kete ti Aarẹ Biden sọ pe oun ko du ipo mọ lọjọ Aiku ni Whitmer kede pe oun yoo ṣe ohun gbogbo to yẹ ni ipa oun lati ri pe Donlad Trump lulẹ ninu ibo naa, ki ẹgbẹ Democrat le yege.

Awọn mii to tun yọju pe awọn nifẹ si ipo Aarẹ ọhun ni gomina ipinlẹ California, Gavin Newsom, gomina ipinlẹ Pennsylvania, Josh Shapiro ati minisita eto irinna, Pete Buttigieg.

Ààrẹ Joe Biden ti jáwọ́ nínú ìdíje fún sáà ìkejì gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà

Aarẹ orilẹede Amẹrika, Joe Biden ti kede pe oun o ni kopa ninu eto idibo fun saa ikeji gẹgẹ bii aarẹ ilẹ Amẹrika.

Biden ni oun gbe igbesẹ yii nitori o gbagbọ pe o dara fun ẹgbẹ oṣelu rẹ ati orilẹede Amẹrika lapapọ.

Igbeṣẹ Aarẹ Biden waye ni o ku oṣu mẹrin ti eto idibo yoo waye fun ipo Aarẹ ni Amẹrika.

Ninu lẹta kan to gbe sori opo ayelujara rẹ, o ni aponle nla ni o jẹ fun oun lati jẹ Aarẹ Amẹrika.

“Pẹlu bi o ṣe jẹ erongba mi lati lọ fun saa keji, mo gbagbọ pe ohun dara bayii ni ki juwọlẹ, ki n si gbajumọ iṣẹ mi fun igba diẹ to ku ki pari saa mi”.

O sọ ninu lẹta naa pe oun yoo ba awọn ọmọ orilẹede Amẹrika sọrọ ni ọsẹ to n bọ.

Aarẹ Biden wa dupẹ lọwọ igbakeji rẹ, Kamala Harris fun aduroti rẹ gẹgẹ bii igbakeji rẹ.

Ọpọ awuyewuye lo ti n lọ pe ilera Aarẹ Joe Biden ko da to lati lọ fun saa keji gẹgẹ bii Aarẹ Amẹrika.

Saaju ni Aarẹ Joe Biden sọ pe Ọlọrun Ọba nikan lo le yi oun lọkan pada lati ma dupo iwọle pada gẹgẹ Aarẹ Amẹrika.

Bakan ni Biden tun fi da awọn ololufẹ rẹ loju pe alaafia ni oun wa, ti oun setan lati tun se saa mii gẹgẹ bii Aarẹ sugbọn ọrọ ti yi pada bayii.

“Mo n se ayẹwo lorekore. Ni ojojumọ ni mo ma se ayẹwo,” O sọ fun Geroge Stephanopoulos.

Ni ọsẹ to kọja ni iroyin jade sita Aarẹ Joe Biden ti lugbadi aarun Korona.

Ààrẹ Joe Biden pè fún àtìlẹyìn fún Harris Kamala

Bakan naa ninu ọrọ to gbe sori opo ayelujara rẹ, Aarẹ Joe Biden rọ awọn akẹgbẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Democrat lati se atilẹyin fun igba keji rẹ lati gbe asia ẹgbẹ oṣelu fun eto idibo aarẹ.

Biden ni igbesẹ akọkọ ti oun kọkọ lọdun 2020 ti oun wọle gẹgẹ bii Aarẹ ni yan Kamala Harri gẹgẹ bii igbekeji, ti oun ko si kabamọ pe oun gbe igbesẹ naaa.

“Lonii, mo setan lati se atilẹyin, ti mo si buwọlu Kamala lati jẹ pe oun ni oludije fun ẹgbẹ oṣelu wa.

“Democrats, asiko ti to lati fọwọsowọpọ lati fidi Trump janlẹ. Ẹ jẹ ka se yii.”