You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọkọ̀ ojú omi gbiná, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò
O to ogoji eeyan to ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti ọkọ oju omi ti wọn gbe rin irinajo lori oni sadede gbina.
Ajọ agbaye lo fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ pe o waye ni apa ariwa lorilẹede Haiti.
Ajọ Agbaye fun awọn Arin irinajo (IOM) ni ikọ alabo Haiti doola ẹmi awọn eeyan mọkanlelogoji lasiko iṣẹlẹ naa.
Ohun pato to fa iṣẹlẹ ina naa ni awọn alasẹ ko ti le fi idi rẹ mulẹ sugbọn awọn oṣojumikoro sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe awọn eeyan to wa ninu ọkọ oju omi naa gbe abẹla dani, ti wọn si gbadura pe ki kọja lori omi lia si aburu sugbọn ina ran mọ ile epo ọkọ naa, to si gbina lojiji.
Awọn eeyan to farapa n gba itọju lọwọ ni ile iwosan to wa ni itosi ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Ọpọ eeyan lo n gbiyanju lati saa kuro ni orilẹede Haiti, ti wọn gbiyanju lati saa kuro nibi ti iṣẹ, aisi ofin ati awọn ija janduku ti n ba awọn finra.
Bẹẹ ba gbagbe, awọn agbebọn sekupa aarẹ orilẹ-ede Haiti Jovenel Moise ni ile rẹ lọdun 2021.
Bakan naa ni iyawo oloogbe naa farapa ninu ikọlu naa
Bi eto ọrọ aje se n ri ijikule lorilẹede naa, ti awọn ile ẹkọ si wa ni titi pa lo n fa ti ọpọ eeyan fi n gbero lati saa kuro.
O le ni eeyan 86,000 ti wọn ju pada si orilẹede Haiti lati awọn orilẹede to yi wọn ka lọdun yii.
Ọpọ ọlọpaa lati orilẹede Kenya balẹ si Haiti loṣu yii lati pese iranlọwọ fun awọn ọlọpaa Haiti lati koju awọn janduku.