Ìjìyà ìkọlù sí ọlọ́pàá Nàìjíríà, Njẹ́ ó mọ, àwọn nkan tó lè mú aráàlú tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ lábẹ́ òfin?

Lawujọ lonii, yala lọdọ wa ni Naijiria tabi ni ibomiran, awọn ọlọpaa ni ofin gbe agbara fun lati daabo ki wọn si fgbofinro laarin ilu.

Ni ọpọ igba igbiyanju ọlọpaa lati ṣe iṣẹ wọn a maa mu ki awọn araalu kọọkan doju ija tabi ki wọn si ṣe ikọlu si wọn.

Ni kopẹ yi ni ọkan lara awọn gbajumọ ori ayelujara fi ọrọ sojuopo Twitter pe oun tu itọ soju ọlọpaa kan nigba ti ọrọ pa wọn pọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa koro oju si iwa yi ti wọn si ni awọn n wa arakunrin to hu iwa naa.

Bi wọn ṣe n tẹsiwaju lori ọrọ yi, a ni ka beere lọwọ awọn amofin pe ki ni ohun ti araalu le ṣe si ọlọpaa ti wọn yoo fi le sọ pe o ṣe ikọlu siwọn ati pe kini iha ti ofin kọ si ṣiṣe ikọlu sawọn agbofinro.

Ki lofin Naijiria ka si ikọlu?

Njẹ ki eeyan mọ ẹnikeji rẹ loju, ki eeyan ta igba ọja ẹlomiran nipa tabi ki eeyan si ṣe akoba fun dukia ẹlomiran.

Ṣe awọn nkan wọnyi la le pe ni ikọlu?

Agbẹjọro Lateefat Oyebimpe Hassan-Ahmad to jẹ agbẹjọro ijọba ni ipinlẹ Kwara ṣalaye pe ikọlu jẹ eyikeyi iwa ti eeyan ba hu to lagbara debi pe o dẹru ba ọmọlakeji rẹ tabi to ko ipalara kan tabi omiran ba.

''Ọrọ ẹnu ko le jẹ ikọlu. O ni nkan mii ti ofin pe eleyi,slander lo n jẹ''

''Ti ẹ ba ṣe ikọja aaye si ẹlomiran bi ko halẹ lati gba leti ti ẹru si ba onitọun.Tabi ki o si gba eeyan leti. O ti ṣe ikọlu si onitọun niyẹn''

O fi kun pe ''ka tutọ si eeyan loju, ka ba nkan eeyan jẹ, ki a gba ọmọ rẹ tabi dukia rẹ jẹ.Ikọlu lawọn nkan wọnyi''

Ikọlu si ọlọpaa nkọ?

O ni ikọlu yi ti oloyinbo n pe ni assault kii ṣe laarin araalu si ara wọn nikan.

''Lopin igba ti awọn ọlọpaa naa kọkọ jẹ ẹlẹran ara, iru iwa ti eeyan ba hu si araalu taa ka si ikọlu, ba baa ṣe iru rẹ naa si ọlọpaa ikọlu lo jẹ''

Ero ọkan agbẹjọro yi ṣe deede pẹlu ti akẹgbẹ rẹ Dele Farotimi to ni ofin to de ikọlu si araalu naa lo de ikọlu si awọn agbofinro.

''Bi mo ba tutọ si araalu lara tabi ọlọpaa, wọn a mu mi fun assault abi?Iwa ti ofin ba ti s pe koyẹ, eyikeyi ẹni taa ba hu iwa naa si ikọlu ni ikọlu njẹ''

O ni o ṣeni laanu pe awọn araalu n hu iruiwa yi ni paapa si awọn ọlọpaa amọ o ni lọpọ igba awọn ọlọpaa naa kii duro sipo ọwọ lo jẹ ki awọn araalu ma tasẹ agẹrẹ siwọn.

''Eyi to pọ ti ọlọpaa fi n kan araalu ninu iwa alufansa lo pọju. Bi wọn ba bọwọ fun ara wọn ni a ko ni maa ri ki araalu naa ma ri wọn fin. Amọ ṣa, eleyi ko to ni waijare lati ṣe ikọlu si ọlọpaa''

Ijiya wo lo wa labẹ ofin fun ikọlu''assault''

Agbẹjọro Hassan-Ahmad ni labẹ ofin Naijiria, lẹyin ti eeyan ba ṣe ikọlu yala si araalu ni tabi ọlọpaa nkan to kan ni pe ki awọn agbofinro mu iru ẹni bẹẹ lọ si agọ ọlọpaa.

O fikun pe bi ọlọpaa ba koju ikọlu lọwọ araalu, oun gaan ko le fi iwa ikọlu yanju rẹ bi kii ṣe pe ko mu ẹni naa lọ si agọ wọn ko si pe lẹjọ labẹ ofin.

''Ọlọpaa naa lẹtọ gẹgẹ bi eeyan labẹ ofin. Bi o ba ṣeeṣe pe araalu ṣe idiwọ fun lẹnu iṣẹ rẹ tabi to si ṣe ikọlu siohun to kan ni ko pe iru ẹni bẹ lẹjọ labẹ ofin. Adajọ ile ẹjọ lo si lagbara ijiya fun ẹni to ba lẹbi. Ọlọpaa ko gbọdọ mu idajọ wa lati ọwọ araarẹ. Bo ba ṣe bẹẹ, o ti tasẹ agẹrẹ sofin ni yẹn''

Tori naa,agbẹjọro yi sọ pe ijiya ti ile ẹjọ le gbe kalẹ, o kere ju ẹni naa yoo ṣe ẹwọn ọdun kan tabi ki wọn fi ijiya mii jẹ labẹ ofin.