You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nkán tí ọlọ́pàá sọ rèé nípa arákùnrin ''afurasí agbésùmọ̀mí '' tó múra bí obìnrin tí ọwọ́ bá lEko
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti tan imọlẹ si ọrọ arakunrin kan tawọn eeyan fẹ dawọ jọ ṣe idajọ ara wọn fun lori ẹsun pe afurasi agbesunmọmi ni.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko Benjamin Hundeyin sọ pe iwadii ibẹrẹpẹpẹ awọn ti fi han pe orukọ arakunrin naa n jẹ Sanni Gafar ti o si jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn.
O tẹsiwaju pe ọpẹlọpẹ pe awọn tete yọju si ibi iṣẹlẹ naa, awọn eeyan ko ba da sẹria ọwọ ara wọn fun ẹyin yi to si ṣeeṣe ki wọn dajọ iku lọwọ ara wọn fun un.
Ninu atẹjade kan to fi soju opo Twitter ni Hundeyin fi alaye nkan to ṣẹlẹ yi si to si ni awọn tẹsiwaju pẹlu iwadii.
Arakunrin naa mura bi obinrin lootọ
Aworan ti Hundeyin fi kin alaye rẹ lẹyin lojuopo Twitter ṣafihan arakunrin kan to wọ hijab obinrin le aṣọ to wọ to si de aawọ oju naa.
Hundeyin sọ pe awọn ri baagi kan lọwọ rẹ to si ko awọn nkan bi hama mẹta,skru draifa mẹfa sipana ati awọn nkan mii sinu rẹ.
Bakan naa ni ṣokoto dudu kan naa wa ninu baagi to gbe lọwọ gẹgẹ bi Hundeyin ṣe sọ.
O ni aafurasi naa sọ pe oniṣẹ mọnamọna loun n ṣe.