You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Dapo Abiodun faraya lẹ́yìn tí wọ́n ri Ireoluwa ti wọn jigbe l’Ogun
Ìpìnlẹ̀ Ogun kò ni gba èmí àti àwọn oníṣẹ́ ibi mọ́- Dapo Abiodun
Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti sọ pe ikoko ko ni gba omi, ko tun gba ẹyin lori ọrọ awọn ọdaran, paapaa awọn ajinigbe ti wọn fẹẹ sọ ipinlẹ naa di ibugbe.
Ọmọọba Dapọ Abiọdun lo sọ eyi lọsan oni, ọjọ Aje, latari ti ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹtadinlogun to jẹ akẹkọọ fasiti Redeemers University, ìyẹn Akinlaja Ireoluwa Oluwatọmiwa ti wọn jigbe lopin ọsẹ to kọja yii, eyi ti wọn ti ri gba pada jade.
Gomina Abiọdun nigba to n sọrọ lori bi wọn ṣe ri ọmọ naa gba jade ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Kunle Ṣomọrin fi sita, o ni inu oun dun pe wọn gba ọmọ naa jade lai farapa.
O ni gbogbo igbesẹ lo ti n lọ lọwọ lati rii pe ọwọ tẹ awọn amookunṣeka to wa nidii bi wọn ṣe ji ọmọ naa gbe, ti wọn yoo si jiya ẹṣẹ wọn labẹ ofin.
Ki lo kọkọ ṣẹlẹ?
Ṣe ni ariwo ibanujẹ tun ṣẹyọ l’opin ọsẹ ti a ṣẹṣẹ lo kọja yii, iyẹn ọjọ Abamẹta, Saitide, ọjọ kẹtala, oṣu kẹjọ ti a wa yii.
Nigba ti iroyin tun jade sita pe awọn amookunṣeka ji ọmọdekunrin akẹkọọ fasiti Ridiimu gbe.
Ireoluwa Akinlaja lorukọ akẹkọọ naa, ti a si gbọ pe ipele akọkọ lo wa ni fasiti ridiimu, iyẹn Redeemers Univerty of Nigeria.
Nnkan bi agogo meji ọsan ọjọ naa ni BBC YORUBA gbọ pe wọn ji Ireoluwa gbe, pẹlu erongba lati fi ṣoogun owo, ṣugbọn ti ori pada ko o yọ lọwọ iku ojiji.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?
Lara awọn to fi iṣẹlẹ ọhun to wa leti sọ pe awọn alaṣẹ fasiti naa lo gbe bọọsi silẹ lati fi ko awọn akẹkọọ wọn lọ sile l’opin ọsẹ naa.
Bi wọn ṣe de agbegbe Interchange to wa loju ọna Eko si Ibadan, ipinlẹ Ogun ni Ireoluwa bọ silẹ lati duro de awọn obi rẹ to fẹẹ lọ gbe lati maa lọ sile.
Wọn ni bi Ireoluwa ṣe bọ silẹ ninu bọọsi ọhun, lo ti pe awọn obi rẹ lori foonu wi pe oun ti bọ silẹ ninu bọọsi ọhun, ti wọn si ni ko duro de wọn lẹgbẹ opopona nibẹ, nitori ti wọn ti wa nitosi.
Si iyalẹnu, a gbọ pe ko ju iṣẹju mẹwaa lọ lẹyin ti Ireoluwa ba awọn obi rẹ sọrọ tan, ni wọn ṣakiyesi atẹjiṣẹ kan to wọle sori foonu wọn, ti wọn si yẹ ẹ wo.
Bi ala lo ri nigba ti wọn ka atẹjiṣẹ naa, to si jẹ lati ọdọ ọmọ wọn ti wọn ṣẹṣẹ ba sọrọ tan, eyi to sọ pe wọn ti ji oun gbe.
Bawo ni Ireoluwa se wa mori bọ ?
Wọn ni loju ẹsẹ l’awọn obi rẹ ti sare debẹ, to si jẹ kayeefi pe wọn ko ri Ireoluwa nibi to duro si de wọn.
Gbogbo bi wọn ṣe n pe foonu rẹ la gbọ pe ko lọ, eyi lo fa a ti wọn fi sare gba teṣan ọlọpaa, ẹkun ti Owode/Ẹgba lọ lati fi to wọn leti.
Awọn ọlọpaa ko fi ọrọ naa falẹ ti a gbọ pe wọn fi dide lati wa ọmọ naa, to si jẹ pe pabo lo ja si.
Lẹyin ọpọlọpọ wakati ti wọn ti n wa ọna abayọ lati ri Ireoluwa, ni wọn tun gba atẹjiṣẹ lati ọdọ rẹ, iyẹn nirọlẹ patapata.
Ohun to kọ sinu atẹjiṣẹ to fi ranṣẹ naa ni pe ‘Wọn fẹẹ lọ fi mi ṣe oogun owo ni ọla’.
Eyi lo jẹ iyalẹnu, ti wọn tun fi dide sii pe ọrọ naa ko ṣee fi ọwọ yọbọkẹ mu rara.
A gbọ pe nibẹ l’awọn obi rẹ ti ranṣẹ pe awọn eeyan wi pe ki wọn maa ba wọn gbadura lori ọmọ wọn ti wọn jigbe.
Iwadii awọn ọlọpaa pada f’idi rẹ mulẹ pe agbegbe Ikorodu ni wọn gburo Ireoluwa si nirọlẹ ọjọ naa, iyẹn gẹgẹ bi wọn ṣe n fi foonu wa a nipa imọ ayelujara ti a mọ si tẹkinọlọji.
Bawo ni ori ṣe ko Ireoluwa yọ?
BBC YORUBA gbọ pe nnkan bi ọsan ọjọ Aiku, ni wọn ṣẹṣẹ ri Ireoluwa Akinlaja.
Wọn ni b'awọn ọlọpaa ṣe wọ buba awọn amookunṣeka ọhun niluu Ikorodu, ni wọn ti na papa bora, ti wọn si yọnda Ireoluwa.
Nibẹ la gbọ pe Ireoluwa ti ja ajabọ kuro lọwọ wọn, ti awọn ọlọpaa si gbe e lọ teṣan wọn, ko to di pe wọn fa a le awọn obi rẹ lowo.
Ni bayii, ọga ọlọpaa kan to ni ka fi orukọ bo oun laṣiri ti fi ọrọ idaniloju sita wi pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo tubọ maa ṣiṣẹ lati rii daju pe wọn daabo bo ẹmi ati dukia araalu.
Gbogbo akitiyan lati ba Ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun lo ja si pabo titi d’igba ti a pari akojọpọ iroyin yii.