Ìjọba sọ kọ́kọ́rọ́ sí àwọn ilé ẹ̀kọ́ nítorí idúnkookò àwọn àjíǹigbe ní Jigawa

Bí awọn akẹkọọ ṣe n gbaradi fun idanwo lati bọ si ipele miiran, Gomina ipinle Jigawa, Mohammed Badaru Abubakar, tí pa a lasẹ pe ki wọn sọ kọkọrọ sì awọn ile ẹ̀kọ́ ìjọba nitori idunkooko awọn ajinigbe.

Gomina kede asẹ naa lọjọ isẹgun, to si ni kí awọn Ọga agba ile ẹ̀kọ́ ìjọba sọ fun awọn akẹkọọ pe ki wọn duro si ile wọn.

Asẹ naa lo waye nítorí idunkoko awọn ajinigbe ni Ipinlẹ naa.

Kọmisona fun Ileeṣẹ ọlọpaa ni Ipinlẹ naa, Mr Sale Tafida, ẹni tí agbẹnusọ rẹ, DSP Lawal Shisu gba ẹnu rẹ sọrọ, ní ileeṣẹ ọlọpaa ko mọ nípa asẹ ijọba ipinlẹ Jigawa.

"Ẹnikẹni ko bawa sọrọ kí wọn to tí ile iwe pa."

Kọmisonna fun eto ẹkọ ni Ipinlẹ Jigawa, Mr Lawan Yunusa Danzomo, ẹni to fìdí asẹ ijọba ipinlẹ Jigawa mule, to si ni asẹ naa lo waye nítorí idunkooko awọn ajinigbe, tí wọn fẹ ṣe ikọlu si awọn ile iwe ni Ipinlẹ naa.

"Gẹgẹ bii gbogbo wa ṣe mọ, ọrọ eto abo mẹyẹ lorilẹede wa sugbọn o sunmọ ara wa ju ara wa lọ nítorí a sunmọ ọpọlọpọ awọn ibi tí ikọlu tí n waye.