You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọmọ mẹ́rin bómilọ níbùdó ìgbafẹ́ etí òkun kan l'Eko
Awọn ọmọde mẹrin kan ti di awati lẹyin ti wọn lọ luwẹ ni etikun Ẹlẹgushi nilu Eko.
Iroyin to jade sita ni pe awọn akẹkọọ mẹwaa lo lọ luwẹ ni etikun naa ki omi okun to gbe mẹrin ninu wọn lọ ti awọn omuwẹ si doola awọn kan lara wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Bẹnjamin Hundeyin fidi iroyin yii mulẹ pẹlu afikun pe iwadii ti n lọ lori iṣẹlẹ naa.
Atẹjade ti awọn alaṣẹ ileeṣẹ igbafẹ etikun Elegushi Beach fi sita sọ pe awọn akẹkọọ naa wa si etikun naa ṣugbọn wọn ko sanwo wọle sibudo igbafẹ etikun naa, leyi to mu ki wọn le wọn pada.
Atẹjade naa ti oloye Ayuba Ẹlẹgushi fọwọsi sọ pe awọn akẹkọọ naa gba ibo miran lọ ni etikun naa ti ko yẹ ko wa fun lilo gbogbo eeyan, nibẹ si ni omi naa ti gbe awọn kan lara wọn lọ.
“Mẹwaa ni awọn akẹkọọ naa ni iye, ọ̀kunrin ni gbogbo wọn wọn wa si etikun naa lati ṣe ajọyọ aṣeyọri esi idanwo WAEC wọn”
O tun ṣalaye siwaju pe “Mẹwaa ninu wọn ti n bomi lọ nigba ti iroyin naa tẹ awọn ikọ adoola ẹmi ninu omi (Beach life guard) wa lọwọ, ikọnaa sare de ibẹ ṣugbọn mẹfa ninu wọn ni wọn ri doola, meji ninu awọn ti wọn doola naa si fara ṣeṣe.
“Ṣugbọn a ṣi n wa mẹrin ninu wọn lasiko ti a fi n gbe iroyin yii sita.”
Awọn alaṣẹ ibudo igbafẹ etikun naa ni awọn ti fi ọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti