You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Òṣèlú da oju ọ̀rọ̀ rú níbi ayẹyẹ ṣíṣí ilé ìkó-nǹkan ìṣẹ̀mbáyé sí oni $25m l'Edo, ariwo sọ
- Author, Todah Opeyemi
- Role, BBC Africa
- Reporting from, Benin City
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9
Ile ti wọn maa n ko awọn manigbagbe nnkan iṣẹmbaye si, ti oloyinbo n pe ni Museum, ni iru rẹ kan ti n foju wina iṣoro oṣelu bayii niluu Benin, ipinlẹ Edo.
Alaranbara ni ile aṣa to n koju iṣoro naa, wọn pe orukọ rẹ ni Museum of West African Art (MOWAA).
Ọsẹ to yẹ ki eto ṣiṣi rẹ bẹrẹ ni rogbodiyan bẹ silẹ, ti awọn olufẹhonuhan kan da oju eto to n lọ lọwọ ru nitori ọrọ oṣelu, ti eto gbogbo si ṣe bẹẹ wa sopin.
Ni bayii, ibudo olowo iyebiye to yẹ ko ti wa fun lilo gbogbo eeyan naa ti wa ni titipa.
Ori saare ilẹ mẹfa ( six-hectare) ti i ṣe eeka ilẹ mẹẹẹdogun ni wọn kọ ile iṣembaye yii si ni olu ilu ipinlẹ Edo, lorilẹede Naijiria- awọn nnkan itan atirandiran lo wa nibẹ ati awọn ile ti akọṣẹmọṣẹ abanikọle ọmọ ilẹ Gẹẹsi ati Ghana nni, David Adjaye, kọ.
Ọdun karun-un ti wọn ti n kọ ibudo naa ree, afojusun awọn to gbe e kalẹ si ni lati mọ riri awọn nnkan atijọ to ti kọja ati awọn iṣẹ atinuda asiko yii to wọpọ ni Benin, iru eyi ti i ṣe awọn iṣẹ ọna ti wọn fi idẹ (bronze) ṣe, ati awọn iṣẹ ọna miran ti awọn ṣọja ilẹ Gẹẹsi ji ko lọ ni aafin ilu naa ni sẹnturi kọkandinlogun sẹyin (19th Century).
Ile iṣembaye yii wuyi, o wu eeyan lori bi wọn ṣe gbe e kalẹ, bi wọn si ti n ṣeto ati ṣi MOWAA to dun un wo loju ree ki ohun gbogbo too yipada.
Awọn oṣiṣẹ ti yoo ṣiṣẹ nibẹ ti gbaradi lati fi ibẹ han bii ọkan lara awọn ibudo to le ba awọn yoku iru rẹ forigbari ni Iwọ-Oorun..
Wọn ti ṣe gbogbo ohun ti yoo mu awọn iṣẹ ọna to wa nibẹ duro pẹ titi lai bajẹ sibẹ, gbogbo igba ni wọn si n ṣe akọsilẹ bi ohun gbogbo ṣe n lọ ninu ilẹ aṣa yii.
Koda, awọn oniṣẹ ọwọ ti ṣeto awọn ohun ti yoo jẹ ki oju ọjọ yoowu to ba yipada ma nipa aburu lara ibudo aṣa yii.
Oniṣowo nla, Phillip Ihenacho, to jẹ adari eto ile iṣẹmbaye yii lo gbe MOWAA kalẹ.
"Mo fẹ ka nipa to jọju lori ọrọ aje nibi" Bẹẹ lo sọ fun BBC.
O fi kun un pe o wu oun lati sọ ilu Benin di aaye aṣa tawọn eeyan yoo maa de si.
MOWAA ti wọn gbe kalẹ ki i ṣe lati fi pa owo tabi jere, iṣẹ to le ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn (30,000) ni wọn lo le pese fun awọn ọmọ Naijiria, yoo si maa pa to $80m (£60m) lọdun si ọrọ aje nipaṣe awọn eto alajọṣe ti wọn yoo maa lo o fun.
Ṣugbọn ki lo sọ ile iṣẹmbaye di nnkan oṣẹlu ti gbogbo ẹ fi fọju pọ ?
Owo ti wọn ti na si i ti to $25m (£19m) lati ba a de ibi to de duro - wọn ko awón owo naa jọ lati ọdọ awọn to dawo jọ, titi kan ijọba France ati German, British Museum ati ijọba ipinlẹ Edo.
Ṣugbọn ni bayii, ijọba Edo ti da nnkan mi-in silẹ, wọn n beere fun ilẹ ti wọn kọ musiọmu yii le lori.
Agbẹnusọ ipinlẹ Edo kan sọ fun BBC pe eyi n waye nitori nigba ti wọn kọkọ bẹrẹ iṣẹ yii, orukọ ipinlẹ Edo ni wọn kọ si i, eyi ti i ṣe Edo Museum of West African Art - o ni nigba ti wọn si ti waa yọ ọ kuro bayii to ti di MOWAA, ko si nnkan mi-in ju ki ọlọmu da ọmu iya rẹ gbe lọ.
Lẹyin ikede yii, ifẹhonuhan lo tẹle e lọjọ Aiku, awọn eeyan yabo ile iṣẹmbaye naa, wọn si n beere pe ki wọn yi orukọ rẹ pada si Benin Royal Museum.
Awọn olufẹhonuhan naa ko ba ere wa rara, wọn bẹrẹ si i sọrọ abuku si awọn alejo to ti ilẹ okeere waa woran ile aṣa naa, ṣaaju ifilọlẹ ati ṣiṣi rẹ. Eyi to jẹ ki awọn alejo naa tete wa ọna gba pada sibi ti wọn ti wa, pẹlu awọn ọlọpaa to ṣọ wọn ti wọn fi rọna lọ.
Koda, Aarẹ Bola Tinubu ti da si ọrọ yii, o si ti gbiyanju lati pana wahala naa. Aarẹ gbe igbimọ alagbara kan dide lati pana ọtẹ ọhun.
Ṣugbọn ki lo sọ ile iṣẹmbaye di nnkan oṣẹlu ti gbogbo ẹ fi fọju pọ bi eyi?
Pupọ ninu wahala yii wa nitori ija agba to n ṣẹlẹ ninu ijọba ipinlẹ , gomina Edo tẹlẹ, Godwin Obaseki - ẹni to pari saa rẹ lọdun to kọja lo jẹ eekan to wa lẹyin ile aṣa naa ni kikọ.
O si jọ pe iṣakoso gomina tuntun to tun jẹ ọrẹ fun ọba ilu naa ti wọn n pe ni Oba, nifẹ si iṣẹ ile aṣa yii.
Fun apẹẹrẹ, awọn to fẹhonuhan lọjọ Aiku naa, n beere fun pe ki wọn gbe aṣẹ ile naa fun Ọba Ewuare II lati maa paṣẹ ibẹ.
Eyi naa si jẹ kinni kan to tun n mu awọn eeyan ranti ọrọ awọn nnkan iṣẹmbaye onidẹ Benin (Benin Bronzes), to jẹ ọkan lara awọn ogun ini ilẹ Africa to ni ọ̀wọ̀ lara .
Nitori bi wọn tiẹ pada ṣi ile aṣa yii, kedere lo han pe awọn iṣura idẹ naa ko le si nibẹ.
Idẹ ni wọn, awọn mi si jẹ eyin erin (ivory) ninu wọn, bẹẹ si ni awọn ti wọn fi igi gbẹ naa wa lara wọn, ti wọn ti figba kan ṣiṣẹ ẹwà laaafin ọba Benin, kawọn ṣọja ilẹ Gẹẹsi too de, ti wọn ji wọn lọ ni 1897.
Lonii, ẹgbẹẹgbẹrun rẹ ni wọn fọnka kaakiri awọn ile aṣa ni Europe ati North America titi kan British Museum, Berlin's Humboldt Forum ati Metropolitan Museum of Art.
Bi awọn ogun ini ilẹ yii naa yoo ṣe pada sorilẹede wa ti figba pipẹ jẹ nnkan tawọn eeyan n sọ kari aye lawujọ awọ alaṣa. Nnkan bii aadọjọ ninu wọn (150) la gbọ pe wọn ti pada sile, awọn mi-in yoo si tun tẹle e bi a ṣe gbọ.
Ni 2019 ti ikede kọkọ waye pe wọn yoo kọ musiọmu si ilu Benin, ipinlẹ Edo, awọn alagbara Naijiria ti ro pe ibi ti awọn yoo ti maa lọ naju wo aṣa niyẹn - aaye kan ti yoo jẹ ape-waa-wo, ti yoo fi iyi nla han gbogbo aye.
Ṣugbọn omi eto naa daru lọdun meji sẹyin, lẹyin ti ijọba apapọ kede pe Oba ni yoo ni awọn idẹ ti wọn ba da pada naa, ti yoo si tun jẹ apaṣẹ itan rẹ. Aafin dide nigba naa, wọn beere fun ile aṣa ti yoo jẹ ti iran ọba, ti wọn yoo maa paṣẹ rẹ, eyi to tako ohun ti Obaseki, gomina igba naa n fẹ.
Ìdààmú MOWAA
MOWAA di ohun ti ko mọ bi yoo ti ṣe ara rẹ nipa iru iṣẹ to wa fun gan-an ati ta lo ni aṣẹ lori rẹ -eyi naa lo fa a ti wọn fi yọ "Edo" kuro ninu orukọ rẹ.
"Lara awọn nnkan to n bi eeyan ninu ti mo ti koju lori rẹ ni pe lati ibẹrẹ lati sọ pe o maa wa fun nnkan asiko yii ati awọn ti wọn jọ wa.Ṣugbọn nitori itan awọn ilẹ okeere ati idapada awọn idẹ Benin, gbogbo eeyan bẹrẹ si i sọ pe ọdọ wa ni musiọmu tawọn yoo maa lọ. Iṣoro to wa nibẹ ni pe awa kọ la ni, a ko si ni aṣẹ ofin kankan to ni tiwa ni awọn idẹ naa."
Ihenacho, adari ile naa lo sọ bẹẹ.
O ni afojusun oun ni lati kọ aaye aabo fun awọn eeyan to n ṣiṣẹ atinuda ni Africa, titi kan awọn onifiimu, ayaworan, olorin, onijo ati awọn to n ṣe ọ̀ṣọ́, ki i ṣe iṣẹ ọna nikan.
"Loooto la fẹẹ gbajumọ itan, ṣugbọn afojusun wa ni lati da oju kọ awọn nnkan ti wọn ri bakan naa." Iheanacho lo sọ bẹẹ.
Awọn eeyan ti iṣẹ wọn jẹ mọ ile aṣa yii naa ko sai maa fi ero ọkan wọn han lori ohun to n ṣẹlẹ yii, Eweka Success, ẹni ọdun mẹtalelogun to jẹ agbẹgilere, sọ pe oun faramọ idasilẹ MOWAA gan-an.
O ni bi awọn eeyan ko tilẹ ka ti ẹni to ni i tabi gbigba idẹ pada si, ohun ti ko ṣee fowo ra ni ile aṣa naa jẹ.
Oluwatoyin Sogbesan toun naa jẹ alaṣa, sọ pe bi awọn eeyan yoo ṣe ri ounjẹ oojọ wọn lo kan han, ọpọ eeyan ni ko tiẹ mọ nipa ti idẹ ọhun rara.
Iṣẹ́ ọnà Yinka Shonibare
Awọn iṣẹ ọna lati ọwọ awọn eeyan bii Yinka Shonibare, Toyin Ojih Odutola, Precious Okoyomon ati Tunji Adeniyi-Jones - ti wọn n gbe ni oke okun ti wọn ko si ki n saba fi iṣẹ wọn han ni Naijiria wa nibẹ.
Shonibare lo ṣe awọn iṣẹ ọna aadọjọ (150) to jọ awọn idẹ Benin sinu ile aṣa MOWAA.
"Bi a ba ṣe awọn iṣẹ ọna bi eyi, a n fi han bo ṣe dun wa to pe wọn ko awọn nnkan agbara wa lọ ni" Shonibare lo sọ bẹẹ fun BBC.
O mọ-ọn-mọ lo yẹpẹ amọ, lati le fi ajọṣepọ han pẹlu ilẹ Benin.
"Loni ti oju ti la, niṣe lo jọ pe a ti jinna si awọn nnkan iṣẹda, bẹẹ awọn alalẹ wa bọwọ fun un gidi, wọn si ni ajọṣe pẹlu rẹ."
Iranti ni awọn ohun to ti sọnu naa yoo maa mu wa .
"Atinuda ni iṣẹ naa - itumọ ohun ti a ko ri mọ ati awọn agbara inu idẹ naa." Shonibare lo sọ bẹẹ.
O ni: "lọna kan, iranti ni, bii ọ̀fọ̀ lo jẹ"
Bakan naa ni iṣẹ ti Ndidi Dike ṣe ni 2016, lori opo ina ọba to maa n wo lemọlemọ, ti araalu ko ni i ri ina lo ni Naijiria naa sọrọ lori agbara ijọba.
Dike fi iṣẹ rẹ ran ijọba leti nipa bi wọn ṣe n kuna lẹka ipese ina mọnamọna.
Eyi naa le jẹ ohun kan ti awọn eeyan yoo tun ranti, paapaa awọn oṣiṣẹ MOWAA ti wọn n ni ireti pe wọn yoo pada ba awọn yanju aawọ yii.
Bo ṣe ṣẹlẹ nipa ina ọba.
Minisita ọrọ Aṣa, Hammatu Musawa, ko yee rọ awọn tọrọ kan lati yanju rẹ.
"Idanimọ wa ni awọn ile ẹkọ aṣa, o si ka da aabo bo wọn nipa ajọṣepọ to bọwọ fun iṣẹmbaye ati ẹni to ni nnkan." Hannatu Musawa lo sọ bẹẹ.
Ibẹru bojo ti gba ọkan awọn kan saa, pe ohun to n ṣẹlẹ yii le ṣakoba fun riri awọn ini Africa ti wọn ji lọ naa gba pada, pẹlu bi awọn ile aṣa agbaye ti wọn ti lorukọ nla ṣe n sọ pe awọn nikan lawọn le tọju awọn iṣẹ naa ko ma bajẹ ati awọn eyi ti wón ti da pada.
Ṣugbọn ọpọ eeyan to n ṣiṣẹ ni MOWAA n fi igbagbọ gbe e, pe ile aṣa ilẹ Africa ṣi le duro digbi, pẹlu ọgbọn atinuda awọn, koda ki awọn nnkan itan atijọ ma si nibẹ.