Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Ẹ ye gberoyin ofege kiri!
Awọn wo lo n baa wi?
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo lo n kilọ fawọn to n pin fidio kan
Eyi to n ṣafihan bi Boko Haram ṣe gbiyanju lati ya wọ ipinlẹ naa
Ileeṣẹ ọlọpaa ni irọ to jinna si ootọ ni fidio yii, ati pe...
Ati pe kinni?
Lọ ka iyoku lori ikanni BBC Yoruba
''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''
Níbo ni King Sunny Ade wà gan an?
Bi ti bawo, ṣe agbaọjẹ olorin Juju sọnu ni?
Bẹẹ la a bi ni o, ọkan lara awọn ọmọbìnrin gbajugbaja akórin naa lo ké gbàjarè bẹẹ lórí ayélujára
Koda, o tun fẹsun kan ọkan lara ọmọkunrin baba rẹ pe oun lo gbe baba awọn pamọ
Amọ, ẹbi KSA ti fidi rẹ mulẹ pe ṣaka lara baba da
Kan soju opo BBC Yoruba fun ẹkunrẹrẹ
''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''
Ajọ EFCC to n gbogun tiwa ibajẹ ti fọwọ ṣinkun ofin mu gbamujọ E-Money niluu Eko
Lori ẹsun pe o takubu owo naira eyi to lodi sofin orilẹede Naijiria
Lalẹ ọjọ Aje ni wọn mu E-Money nile rẹ l'Eko
EFCC ni yoo foju ba ile ẹjọ ti iṣẹ iwadii ba ti pari lori ọrọ rẹ
















