Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Kano tún gbé òfin tuntun kalẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Emir, àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ nìyí

Aworan Emir Sanusi Lamido Sanusi ati Gomina Abba Yusuf

Oríṣun àwòrán, fb/multiple

Lẹyin wakati mẹrinlelogun ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Kano paṣẹ fun Emir karundinlogun ilu Kano, Alhaji Aminu Ado Bayero atawọn Emir mẹrin miran ti ofin agbekalẹ agbegbe akoko Emir tuntun ti ọdun 2020 gbe kalẹ lati dẹkun pipe ara wọn ni Emir tabi ọba ni ọnakọna, ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kano ti gbe ofin tuntun kalẹ bayii.

Ofin tuntun ti wọn gbe kalẹ bayii ti da ẹkun Emir onipokini kan ati awọn ẹkun iṣakoso mẹta silẹ fun awọn Emir onipokeji.

  • Ẹkun ilu Kano: Ijọba ilu Kano yii ni olori ati olubori gbogbo agbegbe to yi ilu Kano ka; Emir Kano ti yoo jẹ Emir onipo kini ni yoo maa ṣe akoso rẹ. Emir ilu Kano to jẹ onipokini yii ni yoo maa wa ni iṣakoso awọn alakoso ijọba ibilẹ mẹrindinlogoji ninu mẹrinlelogoji to wa ni ipinlẹ Kano.
  • Ẹkun ilu Rano: Eyi yoo maa ṣe akoso ijọba ibilẹ mẹta to jẹ Rano, Bunkure ati Kibiya.
  • Ẹkun Karaye: Ilu onipokeji ni eyi pẹlu. Ileto meji lo wa labẹ rẹ; Karaye ati Rogo
  • Ẹkun Gaya: Ilu onipokeji ni eyi pẹlu. Ileto mẹta ni yoo wa labẹ akoso rẹ; gaya, Ajingi ati Albasu.

Ki lo wa ninu ofin tuntun yii?

Iwe ofin yii to wa niwaju gomina ipinlẹ Kano, Abba Kabir Yusuf bayii fun ibuwọlu rẹ yoo la awọn nnkan wọnyi kalẹ:

  • Awọn Emir mẹta to jẹ onipokeji yii ko ni maa gba aṣẹ lọwọ Emir onipokini mọ.
  • Ọkọọkan awọn ijọba ilu wọnyii ni yoo maa ṣe eto yiyan eeyan sipo tabi ojuṣe wọn ni ibamu pẹlu aṣẹ ati ifọwọsi gomina ipinlẹ naa nipasẹ kọmiṣọna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ.
  • Ofin yii tun fun gomina laṣẹ lati yan ẹnikẹni to ba wu u, laarin akoko perete, si ipo Emir onipokeji lawọn ẹkun mẹtẹẹta naa, ki o to wa gbe eto kalẹ fun ilana oye jijẹ ati yiyan awọn adari ẹkun naa labẹ ilana iṣakoso rẹ lọjọ iwaju.

Ni kete ti gomina ipinlẹ Kano ba ti buwọlu aba ofin yii, yoo di ofin. Lẹyin eyi ni Gomina Abba Yusuf yoo gbe ọpa aṣẹ fun awọn Emir onipokeji mẹta tuntun naa pẹlu amọran Emir ilu Kano.

Amọṣa o, awọn onimọ nipa ofin sọ pe omi ṣi n bẹ lamu fun ofin naa paapaajulọ pẹlu awọn ẹjọ to n bẹ kaakiri awọn ile ẹjọ lori aga Emir ilu Kano bayii.