You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mó padà síbí ìbẹ̀rù mi- Kemi Afolabi kọminú bó ṣe padà sí Nàìjíríà
- Author, Akinlabi Afolabi
- Role, Broadcast Journalist
Gbajugbaja oṣerebinrin Kemi Afolabi ti kọminu lori ipo to ba Orilẹede Naijiria lẹyin to pada lati oke okun, eyi to sapejuwe gẹgẹ bii ohun ibẹru fun oun.
Afolabi ni o lọ gba itọju lori ìlera ara rẹ lẹyin to kede pe Dokita ni ọdun marun un ni oun ni mọ lati lo laye tori aisan Lupus to n ba finra.
Nigba ti o sọrọ lori opo ayelujara Instagram rẹ, o ni ko si ohun tuntun kankan to jẹyọ lorilẹede Naijiria lẹyin to oun kuro.
"Mo pada si ilu ibẹru, ko si nkankan to yatọ, lati paapa ofurufu ni orun ti bẹrẹ si ni mumi.
"Irinajo mi lati papakọ ofurufu lọ si Oshodi, lọ Mowe lo nira, ti sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ si papọju lọna opopona marosẹ Eko sì Ibadan.
"Ẹ duro, ki ni awọn oloselu yii n fi ṣe ipolongo ibo to n bọ, nitori ko ye mi rara.
"Ọrọ ijinigbe ni Naijiria kii se awada mọ"
Bakan naa ni o bu ẹnu atẹlu bi ìjínigbé ṣe wọpọ lorilẹede Naijiria ati bii o ṣe nira fun ijọba lati fi opin si iwa ijinigbe lawujọ.
O ni ọrọ ijinigbe lorilẹede Naijiria ni kí n ṣe ọrọ awada mọ nitori ko si ẹnikẹni to kọja ijinigbe lasiko yii ti Orilẹede yii wa.
"Ṣe ka ni o nira fun ijọba lati mu awọn ajinigbe yii nítorí ki n ṣe ọrọ awada mọ bíi ijinigbe ṣe n gbero si lojojumọ lorilẹede Naijiria.
"Kini o fẹ na ìjọba lati pese awọn ti yoo bọ sinu igbo pẹlu ìranlowo awọn agbofinro.
Kí ní ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun wó tí ọ̀nà fí bájẹ́ báyìí?
Kemi Afolabi tun bu ẹnu atẹ lu bi aibikita bii ijọba ipinlẹ Ogun si awọn opopona ṣe n ṣe ijamba fun ọkọ ayọkẹlẹ.
O ni opopona to de ile oun naa kọja afarada, to si n ṣe akoba fun awọn ọkọ ayọkẹlẹ.
"Opopona Ofada Owode to lọ sí ile mi lo kọja afarada, koda ọkọ SUV jẹ ọpọlọpọ iya lopopona naa.
"ìjọba ìpinlẹ Ogun, nigba wo ni ẹ ma tun opopona wa yìí ṣe.
"Gomina Dapo Abiodun, a nilo iranlowo yin bayii, eleyi kan wa gan-an ó"