Bí oríadé bá ni ọ̀pọ̀ ayaba láàfin, wo àwọn ohun tó jẹ́ èèwọ̀ fún wọn nílẹ̀ Yorùbá

    • Author, Olubayode Alebiosu
    • Role, Broadcast Journalist
    • Reporting from, Lagos

Ni ilẹ Yoruba, bi ipo ọba ṣe jẹ pataki naa ni ipo olori jẹ pataki pẹlu.

Idi niyi ti Yoruba fi n pa owe pe ko si apọnle fun ọba ti ko lolori.

Amọṣa o, ni ilẹ Yoruba ọba kii ṣe oniyawo kan.

Ọba ni oreọfẹ lati fẹ ọpọ iyawo ati lati yẹra fun obinrin yowu to ba n fọlajiyọ to si n kọja aye rẹ si oriade.

Lẹnu lọwọlọwọ yii lawọn eeyan lori ayelujara ti n sọ oriṣiriṣi ọrọ nipa awọn ọba to n fẹ ọpọlọpọ obinrin pẹlu ọpọ ariwisi lori rẹ.

Bi ọpọ ṣe n lo anfani ori ayelujara lati wẹnu si awọn oriade lara , lawọn miran n fi ọrọ kotọ ṣọwọ si awọn olori laafin lọna gbogbo.

Kii ṣe ipa kekere ni awọn olori maa n ko ninu igbesi aye ọba.

Boya ni daadaa ni o tabi ni ti aida rẹ, ọwọ Olori lo wa.

Nigba mii wa gẹgẹ bi awọn agba ṣe maa n sọ, ti awọn olori maa n sọ pe ti ọrọ ba ta koko, ki wọn gbe e tọ olori lọ.

Idi ni pe wọn gba pe ohun ti awọn ko lee ba sọ ko gbọ ni ọsan gangan, olori yoo lee ba a sọ ni oru ọganjọ ko gbọ.

Ki ni pataki awọn olori laafin lati igba iwaṣẹ nilẹ Yoruba?

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ lori pataki awọn olori laafin, aarẹ ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe nipinlẹ Ọṣun, TRADSU, Dokita Atanda sọrọ, ilẹ kun.

Atanda ni laye atijọ, bi ọba ba waja, olori kii kuro laafin.

To tumọ si pe awọn olori ijẹta, ana ati eyi to wa nipo lọwọ ni yoo wa laafin. Ọba to ba si wa nipo lọwọ ni ọkọ gbogbo wọn.

Dokita Atanda ni awọn olori ni asopọ ana mọ ọba laafin, awọn lo si maa n tọ ọba lọna ko ma baa ṣi ẹsẹ gbe.

O ni “ko si ohun to buru ninu ki ọba fẹ aya to pọ, amọ o yẹ ka rii daju pe awọn olori bẹẹ n gba idanilẹkọ lori ihuwasi laarin ara wọn.

O ni eyi naa tun wa pẹlu huwasi wọn si ọba, si awọn afọbajẹ ati oloye to ku, ihuwasi si araalu pẹlu.”

Akọda Awo Olukunle ni bi a ba n darukọ olori, ọba la n darukọ. O ni ibi ti wọn ṣe pataki de, ko si ẹnikẹni to gbọdọ gun ori iyawo rẹ mọ.

“Nitori rẹ ni wọn fi n ṣe aiku ki ẹmi ọba lee gun ko le ba ab atọmọ atolori jina.”

Akọda awo ni laye atijọ olori ko gbọdọ da rin. O ni awọn ẹṣọ to ba yẹ ko ba rinrinajo.

Ṣe awọn Olori n gba idanilẹkọ gẹgẹ bi Ọba ti wọn fẹ ṣe wọ ipebi?

Ibeere to yẹ ka beere lọwọ awọn olori lode oni ni boya wọn ni idanilẹkọ lori ipa to yẹ ki wọn maa ko laafin.

Dokita Atanda ṣaye pe nigba iwaṣẹ, bi ọba ba ti wa ni ipebi lati gba idanilẹkọ ati lati ṣe awọn etutu gbogbo to ba yẹ naa, ni olori pẹlu gbọdọ maa gba idanilẹkọ lọna tirẹ, ki ọla ma ba ru boo loju.

Ko ma baa ṣi ipo lo.

Akọda awo ni o ni ẹkọ ti olori gbọdọ kọ. Lara apẹrẹ to fi silẹ ni pe labẹ ẹkọ yii ni yoo ti mọ oriki ọba ati ti ilu to jọba le lori. Oriki yii ni yoo si fi maa kii nigbkugba to ba ti ji n kii lojojumọ.

O ti ni eto ti olori gbọdọ ṣe laafin. Eto ti wọn n ṣe laafin yii kii ṣe eyi ti ẹnikẹni n ṣe nile rẹ rara.

"Gbogbo olori lo yẹ ko ṣe oro iya laafin"

Ni iṣẹ̀ṣe Yoruba, awọn olori ni oro ti wọn gbọdọ ṣe ki wọn to wọ afin ati nigba ti wọn ba wa laafin, Olori melo lo n ṣe oro yii loni?

Dokita Atanda, aarẹ awọn oniṣẹṣe nipinlẹ Ọṣun ṣalaye pe oro yii lo n fun awọn olori ni iriri ati oye lori ẹtọ wọn, ihuwasi wọn ati agbara ti wọn ni gẹgẹbi alakoso aafin.

Akọda Awo, oloye Olukunle Idowu ti oun pẹlu ba BBC News Yoruba sọrọ lori ọrọ yii ṣalaye pe oriṣa ni ọba, olori rẹ pẹlu ko gbọdọ jẹ ẹni lasan.

O ni bi ọba ba ti ṣe n moju to awọn oriṣa kan lapa ọtun lawọn olori naa a maa mojuto awọn miran lapa osi. Ki ilu lee tuba ko tuṣẹ.

“O ni ohun ti a n pe ni oro iyaafin. ṣugbọn ọpọlọpọ wọn, a o ṣoro fun wọn.

Kii sii ṣe ẹbi wọn. Nitori pe ọba to gbe wọn sile gan an, melo ninu wọn lo ṣe oro ko to de ori itẹ?

‘Ọkunrin to ba gun ori olori ọba to ṣoro, aye rẹ yoo bajẹ ni’

Ọpọ eewọ lo wa fun awọn olori laafin nilẹ Yoruba. Niwọn igba to jẹ pe ipo ti wọn di mu kii ṣe ipo lasan.

Gbogbo ohun to ba jẹ eewọ ọba ni eewọ olori rẹ pẹlu. Bi olori ba ti fẹ kabiyesi, o di dandan ko ba kabiyesi wọ eewọ rẹ pọ ni.

“Oriṣa ni ọba. Ọba to ba ti n bẹ lori itẹ to si ṣe oro rẹ pe, gbogbo obinrin to ba ti n ba iru ọba bẹẹ fi aya kin aya ko gbọdọ ba ọkunrin miran fi aya kin aya mọ.

“Iru ọkunrin to ba ṣe bẹẹ, aye rẹ yoo bajẹ, yoo ri beba, yoo pe ni owo.”

Aarẹ ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe nipinlẹ Ọṣun naa tẹsiwaju lati sọ pe lootọ awọn kan n sọ ọ lori ayelujara pe awọn ọkunrin kan n ba iywao ọba lajọṣepọ. O le ri bẹẹ bi ọba tabi olori lee ma ṣoro to yẹ, “amọṣa to ba ya, ade ti wọn de, nitori ade kii ṣe lasan yoo bi wọn.

Olori ko gbọdọ ṣi ọba lọna. Bi olori ko ba ṣọra pẹlu lilo agbara ọwọ rẹ, o lee ṣi ọba lọna.

Ti kii ba ṣe aye to di aye ọlaju ti ohun gbogbo dorikodo, “aga ti iru wọn ba fi joko lode, wọn yoo gbe e tẹle wọn lọle ni o. idi niyi ti wọn fi maa n ru apere tẹle ọba. Ohunkohun ti wọn ba lo lode, wọn yoo ko o tẹle wọn rele ni o.”

Gbogbo ibi ti wọn kii ba ti le ba ọba, wọn ko gbọdọ ba Olori nibẹ bi o ti wulẹ ko mọ.

Obinrin pupọ, wahala pupọ laafin?

Eke daye aasa di apomu. Aiṣe bo ṣe yẹ ni ko fi ri bo ṣe yẹ ko ri. Lootọ ko ni ṣalai si gbungbungbun, ṣugbọn laarin iyẹwu ọba ni eyi yoo wa, kii ṣe eyi to gbọdọ han si araye.

Gẹgẹ bi Akọda awo Olukunle Idowu ṣe sọ, ko si bi a ṣe le ṣe ti gbungbungbun ko ni si, ṣugbọn awọn ara ita to lanfani ati mọ ko gbọdọ ju ijoye, awo ọba, tabi awọn mọlẹbi ọba.

Bi o ba jẹ olori bii mẹrin, marun ni wọn, wọn mọ bi wọn ṣe tẹle ara wọn si. Ọrọ mii si le maa de ọdọ olori agba gan ti awọn olori kekere a ti yanju lọdọ awọn olori to ju wọn lọ.

‘Ko si nnkan ti Olori n wa lori social media’

Ni oṣu kejila ọdun 2021 ni olori ana ni aafin Oodua, Silẹkunọla Naomi kọwe sori ayelujara pe oun ti fa iwe ajṣepọ laarin oun ati Ọọni Ogunwusi ti Ile Ifẹ ya. Igba akọkọ niyi ninu itan ti olori yoo kede ikọsilẹ fun ọba lori ayelujara nilẹ Yoruba.

Ọpọ onwoye lo wo eyi gẹgẹ bi ara ipa kotọ ti ayelujara mu ba iṣẹṣe ati ọrọ oye jijẹ.

Yatọ si eyi, pupọ awọn olori laafin Alaafin Ọyọ to gbesẹ, Ọba Lamidi Adeyẹmi pẹlu ni wọn fọn ka si ori ayelujara to si jẹ pe oniruuru aworan ati ọrọ ni nigba naa.

Akọda Awo Idowu Olukunle rọ awọn olori nilẹ Yoruba lati maa pa ara wọn mọ, ki wọn si mọ pe ayelujara kii ṣe ibi ti olori ti lee maa ṣe bo ṣe wu u.

“Kikọja aye wọn ni n fa abuku, ni n fa arifin. Ki lolori n wa lori ayelujara. Ọwọ aye ati ọla ti n bẹ ninu afin ko si lọdọ ẹlomiran.”

O ni kii ṣe pe ko lee wo o ṣugbọn wọn ko gbọdọ maa gbe ara wọn sori rẹ.

Awọn eekan aṣiwaju iṣẹṣe mejeeji wọnyi wa rọ awọn ọba, awọn afọbajẹ, awọn oloye ati gbogbo majẹobajẹ lati maṣe dẹ oju silu ki aṣa ati iṣe Yoruba bajẹ.