Wọ́n jí èmi àti ‘manager’mi gbé, wọ́n gba €2,000 lọ́wọ́ wa – Portable

"Wọ́n yìnbọn níbi tí mo ti fẹ́ kọrin, mo sì kọ̀ láti ṣeré níbẹ̀"

Gbajugbaja olorin takasufe, Habeeb Okikiola, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Portable ti ṣalaye ohun ti oju rẹ lasiko to lọ ṣere lorilẹ-ede Italy.

Ṣaaju ni Portable ti kọkọ n ṣere kaakiri ilẹ Yuroopu, ko to ko si wahala ọhun ni Italy.

Gẹgẹ bii ohun to sọ loju opo Instagram rẹ, awọn to ṣagbatẹru ere naa ko tete gbe oun lọ sile itura.

O ni bẹẹ naa lo gba wọn ni ọpọ akoko, ki wọn to gbe oun kuro ni papakọ ofurufu.

"Awọn to gbe mi wa si Yuroopu, ko sanwo ọkọ ta wọ."

Portable fi kun pe awọn eeyan ọhun ko tun le san owo ọkọ ti oun wọ lọ si gbagede ere naa gan.

O ni “Ọjọ Abamẹta, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹwaa ni mo balẹ si papakọ ofurufu Venice, ni Marco Polo, ni Italy lati ni Germany pẹlu awọn eeyan mi.”

“O le ni wakati meji abọ ki awọn ‘promoter’ to wa gbe mi kuro nibẹ, koda, wọn ko san owo ọkọ ti a wọ.”

"Mo sọ fun wọn pe n ko sere nibi ti wọn ti n yinbọn, ibi ti wọn ti n nawo ni mo ti fẹ sere"

Portable sọ siwaju si pe nigba ti wọn yoo fi de gbagede ere laarọ ọjọ keji, oun ṣakiyesi pe ija ti bẹ silẹ nibẹ.

O ni awọn kan ti n yinbọn nibẹ, bẹẹ si ni wọn ti gun awọn kan lọbẹ.

O ni “Wọn fẹ ja mi lole ni Italy lana, Ọlọrun lo ko mi yọ.”

“Wọn ko fun wa nile itura to jọju, ile itura ti wọn tun fun wa gan jinna rere si gbagede to yẹ ki a ti ṣere, nigba ti wọn tun gbe wa lọ, wọn tun ṣina.”

“Wọn ni ki a wa ṣere nibi ti wọn ti n yinbọn, mo si sọ fun wọn pe mi o ṣere nibi ti wọn ti n yinbọn, ibi ti wọn ti n na owo, ni mo ti fẹ ṣere.”

Portable ṣalaye pe ibi ti wọn ti n gbiyanju lati wa ọna lọ sibi gbagede ere naa, lawọn janduku kan ti da awọn lọna.

Koda o ni wọn tun gba ẹgbẹrun meji pọun lọwọ awọn, ki wọn to tu wọn silẹ.

Lẹyin naa lo bu ẹnu atẹ lu awọn to n ṣagbatẹru orin ni Italy pe wọn ko tii mọ iṣẹ naa daadaa.

O pari ọrọ rẹ pe oun ko ni da owo ti wọn san fun oun lati ṣere naa pada laelae.