You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn ènìyàn Ukraine ń tò láti pọn omi, tí àdó olóró sì ti ba iná ọba jẹ́
Akoko ipenija nla ni awọn eeyan orilẹede Ukraine n la kọja bayii nitori ikọlu ti orilẹede Russia n se si wọn.
Lọwọ lọwọ bayii, awọn araalu ni Ukraine ti n koju aisi omi ati ina ọba kaakiri , ti wọn si n to lati ri omi pọn.
Eyi ko ṣẹyin ado oloro to le ni ogun ti Russia ju si Ukraine ni ibi ti awọn ohun ini ilẹ naa pọ si yanturu.
Adari ilu Kyiv, Vitaliy Klitschko ni ida ogoji ilu naa ni ko si omi , ti ọgọgọrun ile si wa lai ni ina ọba.
Ukraine ju ado oloro si ọkọ oju omi wa la se da ado iku bii ogun li awọn ohun isura wọn
Kaakiri ilu naa ni wọn ti ri awọn eniyan to to si ori ila lọna ati pọn omi ti wọn yoo lọ
Bakan naa ni Russia ṣe ikọlu si ilu Kharkiv, ti awọn alaṣẹ nibẹ si ni o kere tan ileeṣẹ ijọba ati ohun ini ijọba to le ni mejidinlogun ni wọn ṣe ikọlu si.
Amọ aarẹ orilẹede Russia, Vladmir Putin ni idi ti awọn fi ṣe ikọlu si orilẹede Ukraine ni pe Ukraine ju ado oloro si ọkọ oju omi wọn ( Black Sea Fleet) ni agbegbe annexed Crimea.
Amọ ijọba Ukraine ko i ti sọ pe awọn lo ṣekọlu si ọkọ oju omi naa.
A ti fofin de gbigbe agbado lati Ukraine gba Russia - Putin
Aarẹ orilẹede Russia, Vladimir Putin ti ni awọn n fofin de adehun to ni ki awọn gba gbigbe agbado koja lati ilẹ awon lo si Ukraine abi lati Ukraine lo si ile miran.
Aare Putin ni idi ni pe Ukraine sekolu si ọkọ oju omi wọn nitori wọn gba ọkọ oju omi wọn laaye lati kọja ni agbegbe naa.
Amọ Ajọ Iṣọkan agbaye to gbe adehun naa kalẹ ni ko si ọkọ oju omi kankan ni oju omi lalẹ ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye.
Bakan naa ni Ukraine ko tii fẹsi si ẹsun ikọlu ọkọ oju omi Russia naa.