You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mo ṣì ń wá ìgbákejì mí, mi ò tíì ri - Bola Tinubu
2023 Presidential Election: Bola Tinubu ní òun ṣì ń wá ìgbákejì
Oludije sipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ti ni oun si n wa ẹni ti wọn yoo jọ dije dupo aarẹ ni ọdun 2023 nitori oun ko i tii ri igbakeji oun.
Ikede Tinubu yii lo fi idi rẹ mulẹ pe Kabir Ibrahim Masari, ti wọn fi orukọ rẹ silẹ lọdọ INEC gẹgẹ bi igbakeji oludije aarẹ fun APC, kan jẹ fidiẹ lasan ni.
Tinubu fi idi ọrọ naa mulẹ lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi abẹnugan Ile Igbimọ Asọjuṣofin, Femi Gbajabiamila ni Abuja, to si n se ifilọlẹ iwe ti wọn pe akọle rẹ ni ‘Mr Speaker’.
Tinubu ni oun fẹran ibaṣepọ to wa laarin Gbajabiamilan ati igbakeji rẹ, ti oun yoo si wo awokọṣe rẹ.
O sapejuwe Femi Gbajabiamila gẹgẹ bi akinkanju to mọ iṣẹ rẹ ni iṣẹ, ti ko si ṣe imẹlẹ nipa oṣelu.
Bakan naa lo fikun un pe labẹ iṣejọba rẹ, ko si alakatakiti alatako si ijọba Buhari ni Ile igbimọ Aṣofin, ti wọn si gba ijiroro laaye.
Ninu esi tirẹ, Gbajabiamila rọ Tinubu lati gbimọ pọ pẹlu oun to ba ti ṣetan lati yan igbakeji rẹ.
To si dapara pe Tinubu yoo sanwo nibayii to ba fẹ gba imọran oun lori igbakeji aarẹ.
Ẹgbẹ oṣelu APC lo fi Kabiru Masari sibẹ lati ba gbedeke ọjọ kẹtadinlogun ti ajọ INEC fi lede gẹgẹ bi igba ti awọn oludije le yan igbakeji wọn.