Àwọn afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn pa èèyàn kan, jó ilé ìgbé méjì gbúrúgbúrú ní Kwara

Oríṣun àwòrán, Kwara Police
Awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ti ṣọṣẹ niluu Ẹyẹńkọrin si Bala, nijọba ibilẹ Àṣà, nipinlẹ Kwara.
Iroyin ni lalẹ ọjọ Aje, ọjọ Kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ni rogbodiyan bẹ silẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti wọn si faa titi di ọjọ Iṣẹgun.
BBC News Yoruba gbọ pe awọn ọdọ kan ti wọn jẹ afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ni wọn fija pẹẹta niluu Ẹyẹnkọrin, Bala, nijọba ibilẹ Aṣà, ti wọn si n pa ara wọn.
Ni owurọ kutukutu, ọjọ Iṣẹgun, ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2024, ni wọn tun bẹrẹ wahala wọn ti wọn si gun gende ọkunrin kan ti wọn n pe ni Adamu, lọbẹ pa.
Iwadii fihan pe, lẹyin eyi ni awọn ọmọ ẹgbẹ ti o padanu ọkàn lara wọn yabo ile meji ọtọọtọ ti o jẹ ti baba adari ẹgbẹ akọkọ, wọn si dana sun-un deeru.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, ASP Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Kọmisanna ọlọpaa ni Kwara, CP Victor Ọlaiya, ni ki awọn araalu fọkan balẹ, pe awọn ẹṣọ aabo ti gunlẹ si iluu Ẹyẹnkọrin, ti alaafia yoo si jọba laipẹ.
Ileeṣẹ panapana ni Kwara ni ile meji ni awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun naa dana sun, to si jo deeru niluu Ẹyenkọrin ki awọn to de ibẹ lati ṣe iṣẹ awọn.
Atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ panapana Kwara, Hassan Adekunle fi lede ni ile kan ti o ni yara mẹfa ati ekeji to jẹ oni yara mẹrin ni o jo patapata.
O ni iwadii jẹ ko di mimọ pe ni ṣe ni awọn ọmọ ẹgbẹ kan mọọmọ sun awọn ile naa nina lati fi gbẹsan iku ọkan lara wọn ti wọn sekupa.
O fi kun pe bi ile naa ṣe n jona ni wọn duro tii, ti wọn ko si jẹ ki awọn olugbe bomi pa, wọn si rii daju pe o jona patapata.
Ẹwẹ, oga agba ileeṣẹ naa, Prince Falade John kẹdun pẹlu awọn idile ti ọrọ naa kan, o si rọ awọn obi lati bojuto awọn ọmọ wọn ki a baa le ni awujọ alaafia.















