UEFA fi àmì ẹ̀yẹ tí agbábọ́ọ̀lù kan ò gbà rí dá Cristiano Ronaldo lọ́lá

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Agbaọjẹ ẹlẹsẹ ayo, Cristiano Ronaldo, tun ti dabira bi iṣe rẹ o.

Ni irọlẹ Ọjọbọ ni ajọ UEFA to n ṣakoso ere bọọlu nilẹ Yuroopu fi ami ẹyẹ ti agbabọọlu kankan ko tii gba ri da a lọla.

Ami ẹyẹ ọhun duro fun agbabọọlu ẹlẹsẹ ayo to gba goolu sawọn julọ ninu itan idije UEFA Champions League.

UEFA ṣe imọyi naa fun Ronaldo lẹyin to ti gba ogoje goolu sawọn ninu idije Champions League eyi ti agbabọọlu mii ko ti ṣe iru rẹ ri.

Ninu ọrọ rẹ, aarẹ UEFA, Aleksander Ceferin, ni ‘’ti a ba n sọ nipa idije Champions League, idije EURO, tabi ere bọọlu lapapọ, Ronaldo ni a n sọ nipa rẹ.

Ronaldo nikan ni eeyan ti mo mọ ti ọjọ ori rẹ n lọ, amọ, ti ko dagba loju.

Mo si ni ireti wi pe Ronaldo si maa pada wa si Yuroopu lati gba Champions League lẹẹkan si.’’

Ninu ọrọ imọyi rẹ, Ronaldo sọ pe idije Champions League lo gbọrẹgẹjigẹ julọ ninu idije bọọlu laye.

‘’Orin to maa n ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ Champions League lasan maa n dun un gbọ leti.

Mo maa n ṣafẹri idije Champions League ni gbogbo igba ti mo ba ti wa silu Monaco fun isọri ere bọọlu fun saa tuntun Champions League.

Ko si ẹni to mọla, o ṣee ṣe ki n si pada lọ gba Champions League ni Yuroopu,’’ Ronaldo lo sọ bẹẹ.

Ronaldo gba ife ẹyẹ Champions League marun un ọtọtọ, ninu eyi to si gba goolu sawọn ninu mẹrin.

Amọ, Ronaldo ni akọkọ ti oun kọkọ gba pẹlu Manchester United ati eyi toun gba ni papa iṣere ilu Lisbon ni Portugal to jẹ orilẹede oun ṣe pataki soun gan an.