Àdó olóró ṣekúpa èèyàn 28 ni Pakistan

Aworan

O le ni ogun eeyan to ti padanu ẹmi wọn nitori ibugbamu ado oloro meji to waye ni ilu Balochistan lorilẹede Pakistan ni o ku ọjọ kan ki eto idibo waye.

Bakan naa ni ọpọ eeyan lo ti dero ile iwosan lẹyin ti wọn farapa yanayana nibi isẹlẹ naa.

Eto idibo lo yẹ ko waye ni Ọjọ kẹjọ oṣu keji ọsun 2024.

Awọn alasẹ lorilẹede naa fi idi isẹlẹ naa mulẹ, ti wọn si salaye pe ado oloro akọkọ ṣekupa eeyan mejila niwaju ọfisi ipolongo ti ẹgbẹ oṣelu Indefenda ni agbegbe Pishin.

Aworan

Ado oloro keji sekupa eeyan mẹjọ ni agbegbe Qillah, kilọmita 150m si ibi ti ibugbamu akọkọ ti waye.

Bakan naa ni awọn alasẹ ti fidi rẹ mu lẹ pe ọpọ eeyan farapa yanayana nibi ibugbamu naa.

Titi di aṣiko yii, awọn ẹgbẹ agbesunami kankan ko ti sọ pe awọn ju ado oloro naa.

Ọpọ awọn lo ti bu ẹnu atẹlu bi eto idibo naa se fẹ waye. Ọpọ aworan lo ti waye lori ayelujara to safihan bi ado oloro se bugbamu ni Pishin.

Rogbodiyan bẹ silẹ ni agbegbe Balochistan ati Khyber Pakhtunkhwa ni ọsẹ to kọja.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lati tan imọlẹ si ohun to sokunfa ibugbamu naa, ti wọn si ti gbe awọn eeyan to farapa lọ si ile iwosan fun itọju.