Igun PDP méjì pàdé nílé ẹgbẹ́ l'Abuja, rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀, tajútajú ba àwọn gómìnà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Rogbodiyan bẹ silẹ lonii ọjọ Iṣẹgun, nile ẹgbẹ oṣelu PDP to wa niluu Abuja, nibi ti igun ẹgbẹ oṣelu PDP meji ti pade ara wọn to si di bo o lọ ko o yago lọna.

Nile ẹgbẹ naa to wa ni Wadata Plaza ni awọn ọlopaa ti ṣe ọkọ wọn lọjọ si lati dena wahala to ba fẹ waye.

Ṣugbọn rogbodiyan ọhun pada waye, tajutaju lo si yanju ọrọ ti wọn ko le fi ẹnu sọ.

Koda, tajutaju ọhun ko mọ awọn gomina to wa nibẹ,wọn fi oju ko o.

Kí ló ṣẹlẹ̀ gan-an?

Ni kutu hai ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlogun oṣu Kọkanla ọdun 2025 ti i ṣe oni, awọn aṣiwaju ẹgbẹ PDP bẹrẹ si i de si ile ẹgbẹ naa fun ipade.

Ipade ọhun ki i ṣe fun igun kan ṣoṣo, bi ko ṣe igun mejeeji ti PDP ti pin si.

Ohun to jẹ iyalẹnu ni pe ile ẹgbẹ kan ṣoṣo yii ni igun mejeeji fi ipade wọn si.

Nyesom Wike, ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn yọ lopin ọsẹ, naa wa, ṣugbọn ko sọkalẹ ninu mọto rẹ.

Awọn agbofinro lo si yi mọto naa po.

Igun ti Gomina Seyi Makinde n lewaju fun wọle lati ba awọn akọroyin sọrọ.

Ṣugbọn Makinde ni oun ko ni i ba awọn eeyan sọrọ nikọọkan, nitori erongba oun ni lati da aabo bo ijọba awaarawa ni Naijiria, oun ko ni i jẹ ki orilẹede yii di ilu ẹlẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo .

Ohun ti BBC ri ni pe awọn ọlọpaa bẹrẹ si i yin tajutaju.

Koda, tajutaju naa kan Seyi Makinde ati Bala Mohammed, gomina ipinlẹ Bauchi ti wọn jọ wa nikalẹ.

Nigba ti wọn kuro nibudo ipade yii, a ri wọn ti wọn n fi aṣọ ilewọ nu oju, latari ẹrọ naa to ti ba wọn.

Ko sohun meji to fa rogbodiyan yii, bi ko ṣe ede aiyede to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ PDP.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú?

Ohun ti a le pe ni rogbodiyan abẹle ti n koju ẹgbẹ oṣelu alatako, Peoples Democratic Party (PDP) ni Naijiria bayii, o ti tojọ mẹta.

Ogun abẹle ọhun ko si jọ pe yoo pari laipẹ, ojumọ kan, aroye kan lo n ṣẹlẹ lẹgbẹ Alaburada.

Ọpọ nnkan to n ṣẹlẹ ohun lo si ṣee ṣe ko tu ẹgbẹ naa ka bi awọn awoye oṣelu ṣe wi, paapaa igun kan ṣe ṣepade apapọ ti wọn si yọ awọn eeyan kan danu.

Lopin oṣẹ to kọja, igun ẹgbẹ PDP kan ṣeto ipade apapọ wọn niluu Ibadan, nibi ti wọn ti fẹnuko lati Nyesom Wike ti i ṣe Minisita ilu Abuja.

Wọn yọ Sam Anyanwu ti I ṣe Akọwe, wọn yọ Ayo Fayose atawọn mi-in naa danu fun aṣemaṣe ti wọn ni wọn ṣe ninu ẹgbẹ PDP.

Ṣugbọn Anyanwu ti wọn yọ nipo Akọwe tun pe ipade igbimọ olufọkantan ẹgbẹ, nibi to ti kede fun wọn pe ipade yoo waye lọjọ Isegun.

Ṣè ìpàdé wọn tó wáyé lẹ́sẹ̀ nílẹ̀?

Awọn eekan kan ninu ẹgbẹ PDP ti ṣapejuwe ipade apapọ to waye ni Papa iṣere Lekan Salami, niluu Ibadan bii eyi to lodi sofin.

Wọn ni eyi ri bẹẹ nitori ile ẹjọ giga ilu Abuja ti paṣẹ pe ipade naa ko le waye, wọn si ti ni ki ajọ INEC ma ṣe da si i.

Gomina ipinlẹ Jigawa, Sule Lamido, lo mu ẹjọ PDP lọ si kootu, o ni oun fẹ ra fọọmu lati dije fun ipo alaga apapọ wọn ko si foun laye lasiko ipade naa.

Eyi ni Adajọ Peter Lifu, da pe o lodi sofin ẹgbẹ PDP lati dena ọmọ ẹgbẹ to ba fẹ ra fọọmu.

Adajọ naa paṣẹ pe ipade ọhun ko ni I le waye, afi bi wọn yoo ba gba Lamido laye lati dije fun ipo to wu u lo ku.

Lamido paapaa ni oun ko ni i yee ja fun ẹtọ oun, bi ipade apapọ ba si fi le waye, o lodi sofin.

Ṣugbọn ipade pada waye.

Àṣẹ kootu kọlu ara wọn

Ẹwẹ, awọn eleto ipade apapọ naa sọ pe awọn ko deede gbe ipade kalẹ, wọn ni awọn ri aṣẹ gba lati ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo ni.

Awọn eeyan naa sọ pe kootu yii lo fun awọn laṣẹ lati tẹsiwaju ninu ipade ati yiyan awọn ti yoo di ipo mu lẹgbẹ PDP.

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, aṣẹ to wa lati ọdọ Adajọ Ladiran Akintola, waye lọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla.

Wọn fi kun un pe aṣẹ naa lo mu PDP ṣe ipade apapọ rẹ, gẹgẹ bawọn ṣe ṣeto rẹ, pe ki INEC naa si waa moju to o.

Ẹwẹ, ọga kan ni National Judicial Institute (NJI), Babatunde Adejumo, ṣalaye ohun ti yoo ṣẹlẹ bi aṣẹ ile ẹjọ meji ba kọlu ara wọn bayii.

Paapaa awọn ile ẹjọ ti wọn jọ ni agbara kan naa, ti wọn wa gbe idajọ ọtọọtọ kalẹ.

O ni: "Bi ile ẹjọ meji tabi mẹta ba gbe idajọ ọtọọtọ kalẹ lori ẹsun kan naa, ile ẹjọ Ko-tẹmi-lọrun ni yoo yanju rẹ.

"Ohunkohun ti ile ẹjọ to ga julọ ba si pada da ni abẹ yoo ge."

Nibi to de duro yii, o ti foju han pe ọrọ kootu ko ti i tan ninu lọrọ PDP

Wike, Anyanwu, Fayose

Nibi ipade to waye n'Ibadan naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ti dabaa pe ki wọn yọ awọn ọmọ ẹgbẹ kan danu, nitori wọn n huwa to lodi si ohun ti ẹgbẹ n fẹ

Lara awọn ti wọn darukọ ni:

Nyesom Wike

Sam Anyanwu

Ayodele Fayose

Austin Nwachukwu,

Kamaldeen Ajibade (SAN)

Umar Bature

Mohammed Abdulrahman

George Turner

Dan Orbih

Mao Ohuabunwa

" Ọpọ ọmọ ẹgbẹ lo fọwọ si igbesẹ yii, o si fi han pe ẹgbẹ ṣetan lati fopin si gbogbo ipinya abẹnu ati awọn iwa to lodi si ofin ẹgbẹ."

Bẹẹ ni di PDP kọ ọ si oju opo X wọn.

Àwọn gomina kan ni awọn ko lọwọ nibẹ

Lara awọn gomina ti wọn ni awọn ko mọ nipa yiyọ ti wọn yọ Wike ati awọn eeyan rẹ ni:

Gomina Umaru Fintiri ti ipinlẹ Adamawa.O ni bi PDP yoo ṣe ni alaafia lo ṣe pataki

Gomina Plateau: Caleb Mutfwang, sọ pe asiko to le ni PDP wa.

Awọn to fọwọ si i

Gomina Bala Mohammed ti ipinlẹ Bauchi, ati Dauda Lawal ti Zamfara, ṣatileyin fun Seyi Makinde ipinlẹ Oyo, ẹni ti ọpọ eeyan n ri bii olori igun PDP yii.

Bakan naa ni Oloye Bode George, ọkan lara awọn agba to da PDP silẹ naa wa lẹyin Makinde.

Iroyin si sọ pe baba naa lo da aba pe ki wọn yọ Wike, ti Bala Mohammed si ṣikeji rẹ lati kin aba naa lẹyin.

Ki lo kan fun PDP

Ẹnikan to le sọ ohun to kan fun ẹgbẹ PDP bayii ko si, oju rẹe, iran la o fi wo ni ọpọ eeyan n wi.

Eyi ri bẹẹ pẹlu bi wahala abẹnu ẹgbẹ Alaburada ṣe n fi ojoojumọ gba ọna ọtọ yọ.

Igbagbọ awọn eeyan mi-in si tilẹ ni pe PDP ti ku, ojiji rẹ lo ku to n tẹle e kiri.

Ṣugbọn awọn eeyan bii Gomina Seyi Makinde, Bala Muhammed ati Oloye Bode George ti wọn jẹ igun kan naa duro lori ipinnu wọn lati gbe PDP dide.