Àwọn nǹkan mánigbàgbé mẹ́fà tó wáyé níbi ìpàdé gbogboogbò ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní Ibadan

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ilu Ibadan gbalejo ipade gbogbogbo ẹgbẹ oṣelu PDP lopin ọsẹ, bo tilẹ jẹ pe ipadenaa ti pari amọ ohun to ṣẹlẹ nibẹ ko tii tan nilẹ.

Oniruru nnkan lo ṣẹlẹ ṣaaju ipade gbogbo naa ati nibẹ ti ọrọ ọhun ko fi tii tan nilẹ.

Yatọ si ọgọrọ oloṣelu to wa nibẹ, awọn eeyan ilu Ibadan naa ni imọlara ipade gbogbogbo ẹgbẹ oṣelu ọhun. Iwọnyii lawọn nnkan manigbagbe to waye lasiko ipade gbogbogbo ẹgbẹ oṣelu naa.

Ajọ eleto idibo INEC ko si nibẹ

Lẹyin ipade naa ni ọpọ awuyewuye bẹrẹ si n waye lori ayelujara lori boya ajọ eleto idibo, INEC, wa nibi ipade naa tabi ko si nibẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti ofin sọ, o yẹ ki ẹgbẹ oṣelu naa kọwe si INEC ki INEC si wa nibẹ lati bojuto awọn idibo ti yoo waye nibẹ, amọ ṣe INEC yọju?

Akọroyin BBC Yoruba to wa nibi ipade naa to waye lọjọ Abamẹta jabọ pe ajọ INEC ko si nibẹ.

Nigba to ba agbẹnusọ tuntun fun ẹgbẹ oṣelu naa, Ini Ememobong sọrọ, o ni awọn kọwe si INEC lati yọju amọ awọn ko mọ eredi to ṣe kọ lati ṣe bẹẹ.

Gomina Ademola Adeleke ko si nibi ipade naa

Ọpọ awọn gomina ni Naiiria ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lo yẹ ki wọn yọju sibi ipade naa amọ pupọ ninu wọn ni ko yọju.

Lara awọn gomina PDP ti ọpọ n reti nibẹ amọ ti wọn ko yọju ni gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, Sim Fubara to jẹ gomina ipinlẹ Rivers to fi mọ Agbu Kefas to jẹ gomina ipinlẹ Taraba.

Sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ niluu Ibadan

Ọpọ olugbe ilu Ibadan ni ko ri aye lati lọ sawọn ibi to yẹ ki wọn lọ lọjọ Abamẹta ti ipade naa waye latari ọpọ alejo ti ilu naa gba, paapaa lagbegbe ibi ti ipade ọhun ti waye ni papa iṣere Lekan Salami to wa ni Adamasingba.

Awọn kan to n gbe lagbegbe naa sọ pe inira nla ni ipade ọhun mu ba awọn latari bi wọn ko ṣe tete ri ọkọ wọ nigba ti awọn mii ti wọn ri ọkọ ko tete de ibi ti wọn n lọ.

PDP yọ Wike, Fayose atawọn mii bii jiga

Nibi ipade naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun ti gbe igbesẹ kan to ya ọpọ araalu lẹnu.

Igbesẹ ọhun ni bi wọn ṣe fi ọwọ osi juwe ile fun minisita fun FCT, Nyesom Wike, gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayodele Fayose atawọn mii lori ṣiṣe lodi si ẹgbẹ oṣelu naa.

Yatọ si Fayose ati Wike awọn mii ti wọn tun fi ọwọ osi juwe ile fun ni agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Samuel Anyanwu, Bature, Adeyemi Ajibade, SAN, Mohammed Abdulrahman, Mao Ohuabunwa, Austin Nwachukwu, George Turner, Abraham Amali ati Dan Orbi.

Ọpọ awọn agbofinro to duro digbi

Ọpọ awọn agbofinro lati ipinlẹ Oyo lo wa nibi ipade gbogbogbo naa lati pese aabo to peye fun awọn to wa nibẹ.

Ṣaaju ipade ọhun ni agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun, Osifeso Adewale, ti kọkọ sọ ninu atẹjade kan pe ọpọ ọlọpaa ni yoo wa nibẹ latari irufẹ awọn eeyan jankan ati ọpọ ero ti yoo yọju sibẹ.

Ipolonogo ibo Aarẹ fun Seyi Makinde

Lara awọn nnkan mii to waye nibẹ ni awọn patako ipolongo ibo gomina Seyi Makinde fun ipo Aarẹ lọdun 2027 to wa nibẹ.

Bo tilẹ jẹ pe Makinde funra rẹ ko tii sọ pe oun fẹ dije du ipo Aarẹ amọ ọpọ awọn alatilẹyin rẹ lo ti n pologo rẹ.