You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn agbébọn ti ń gba owó orí l'Oke Ọya ní Naijiria, wọ́n tún ń ṣòfin - Dambazau
O jọ pe igbesunmọmi, ikọlu ati rogbodiyan to maa n waye lapa Ariwa Naijiria ti gba ọna mi-in yọ , pẹlu gbajare tuntun to jade lati ẹnu minisita ọrọ abẹle tẹle to tun jẹ ológun, Ajagunfẹyinti Abdulrahman Bello Dambazau.
Dambazau lo ke gbajare pe awọn agbesunmọmi ti n gba owo ori lọwọ awọn eeyan l'Oke-ọya bayii, wọn si ti n ṣe ofin lọwọ ara wọn.
Nibi ipade awọn ẹṣọ alaabo ati awọn akọroyin, akọkọ iru rẹ to waye ni Birnin Kebbi, ipinlẹ Kebbi, ni Ajagunfẹyinti Bello Dambazau ti sọrọ yii.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ai si aabo ti n ṣẹlẹ ni ẹkun Ariwa bayii, o ti le ni ogun ọdun.
"A ti de ọgangan ibi tawọn agbebọn ti n gba awọn ilu wa kan bayii, ti wọn n ṣe ofin fun wọn ti wọn si n gbowo lọwọ wọn."
"Apa Ariwa ti foju winna ikọlu awọn daran-daran ati agbẹ, ikọlu ati igbesunmọmi.
"Wọn pa awọn eeyan ninu mọṣalaṣi ni Katsina, Borno, Zamfara ati Kano."
''Ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lo ti ku, awọn to le ni miliọnu lo ti di alarinkiri lai si igbesẹ kan pato tijọba n gbe le e lori''
Dambazau ṣalaye pe awọn ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lo ti ku, awọn to le ni miliọnu lo ti di alarinkiri lai si igbesẹ kan pato tijọba n gbe le e lori.
O rọ awọn gomina ilẹ Hausa lati dẹkun gbigbe ara le owo ti ijọba apapọ n fun wọn, o ni ki wọn da awọn ẹka to n ri si nnkan alumọni silẹ lọdọ wọn funra wọn.
Ki wọn ba ijọba apapọ ṣiṣẹ pọ nipa bi wọn yoo ṣe fi nnkan alumọni ilẹ wọn pese iṣẹ funra wọn, ti wọn yoo fi le ìṣẹ́ ati òṣì wọgbẹ.
Dambazau sọ pe awọn nnkan wọnyi ti ko si lo n fa ki eto aabo mẹhẹ.
" O le ni ida aadọrin (70%) awọn eeyan ti ìṣẹ́ ń ṣe l'Oke-Ọya to jẹ pe aisi aabo lo fa a fun wọn.
"Akatakiti ẹsin lo ṣikeji, oun lo fa ẹgbẹ bii Boko Haram, Lakurawa ati awọn agbebọn to n da wahala silẹ kiri."
Bẹẹ ni Ajagunfẹyinti Dambazau wi.
Awọn eeyan nla-nla lati apa Ariwa lo peju-pese sibi eto naa, lara wọn ni Sultan ilu Sokoto, Alhaji Sa'ad Abubakar III, ẹni to ni ọrọ aabo ki i ṣe fun ijọba nikan, bi ko ṣe ki gbogbo Naijiria jọ boju wo o.
Pẹlu Gomina Abdullahi Sule ti ipinlẹ Nasarawa, toun naa sọ pe ai si aabo lapa Ariwa gba ki eeyan wo o lati isalẹ.
O ni aibalẹ ọkan pọ nibẹ ju ki eeyan ma mọ idi abajọ rẹ lọ.