You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kó ṣáà ti dáa ni mo wà fún - Gómìnà Fintiri, Muftwang yọ ara à wọn nínú ìyọnípó Wike kúrò lẹ́gbẹ́ PDP
Gomina ipinlẹ Adamawa, Ahmadu Fintiri, ti yọ ara rẹ kuro ninu igbesẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party to fọwọ osi juwe ile fun minisita fun olu ilu Naijira, Nyesome Wike.
Eyi wa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Humwashi Wonosikou buwọlu fun awọn akọroyin lọjọ Ṣatide, Ọjọ kẹdogun oṣu kọkanla ọdun 2025.
Fintiri, ẹni to tun jẹ alaga ipade apero to waye niluu Ibadan to jẹ olu ilu ipinlẹ Oyo, ni igbesẹ naa le fa rogbodiyan fun ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ọ fikun pe oun ko ni lọwọ ninu ohunkohun ti yoo da wahala silẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.
"Gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ to ni otitọ ọkan, nnkan ti mo di mu ree, mo duro fun alaafia ati isọkan , ti n ko si da si ohun ti yoo tu ẹgbẹ ka.
"Mo ni igbagbọ ninu alaafia ati irẹpọ laarin ara wa gẹgẹ bii ohun ti yoo gbe ẹgbẹ lọ siwaju," gomina naa ṣalaye.
Fintiri wa rọ gbogbo awọn agba ẹgbẹ pe ki wọn fọwọsowọpọ lati wa bii alaafia ati irẹpọ yoo ṣe jọba ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.
Gomina ipinlẹ Plateau, Caleb Muftwang, naa darapọ mọ Fintiri lati bu ẹnu atẹlu igbesẹ lati fọwọ osi juwe ile fun Nyesom Wike kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Gomina gbe sita, Muftwang ni awọn ti ọrọ kan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ati awọn gomina ko sọ ọrọ ṣaaju ki wọn to gbe sita lasiko ipade apero to waye ninu Ibadan.
O fikun igbesẹ yii ko yẹ ko waye lasiko ti wọn n gbiyanju lati da ikolọ ẹgbẹ naa pada.
Ki lo sẹlẹ ṣaaju?
Ninu oṣu kẹjọ, rogbodiayan ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party PDP tun gba ọna miiran yọ nigba ti Nyesom Wike, tii se minisita fun olu ilu ilẹ wa, Abuja, ni oun ti yọwọ kuro ninu adehun wiwa ojutu si iṣoro ẹgbẹ naa.
Bakan naa ni Wike tun fẹsun kan Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo pe oun lo n fa ọpọ wahala to n ja ẹgbẹ oṣelu PDP nitori bo ṣe kuna lati ko ipa tirẹ lori adehun ti wọn jọ fẹnuko le lori.
Wike wa ṣapejuwe Makinde, Mba ati awọn mii ninu ẹgbẹ oṣelu PDP gẹgẹ bii ọdalẹ.
Ninu atẹjade kan ti Wike gbe soju opo ayelujara X ni gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ naa ti fẹsun kan awọn agbagba ẹgbẹ oṣelu PDP bi Gomina ipinlẹ Enugu, Peter Mbah, to ṣapejuwe wọn gẹgẹ bii ọdalẹ, alailootọ ati awọn ẹsun mii to ni ṣe pẹlu yiyẹ adehun.
Ni opin ọsẹ yii niluu Ibadan ni ẹgbẹ oṣelu PDP dibo yan Kabiru Tanimu Turaki (SAN) lati ipinlẹ Kebbi gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ tuntun nibi ipade apero ẹgbẹ naa to waye niluu Ibadan ipinlẹ Oyo lọjọ Abamẹta ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹwaa yii.
Turaki to jẹ agbẹjọro agba bori pẹlu ibo 1,516, nigba ti alatako rẹ, Lado Danmarke, lati ipinlẹ Katsina ri ibo 275.
Sẹnẹtọ Ben Obi to ti figba kan ri ṣoju ipinlẹ Anambra nile aṣofin agba l'Abuja lo kede esi ibo naa.