You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìbò ààrẹ 2023 sàn ju gbogbo ìbò ìṣaájú ní Naijiria lọ – Ìjọba àpapọ̀
Ijọba apapọ ti kede pe eto idibo Aarẹ to waye ninu oṣu keji ọdun yii dara ju awọn eto idibo to ti n waye tẹlẹ ni Naijiria.
Agbẹnusọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin.
O ni “Eto idibo yii san ju awọn eto idibo to ti waye ni Naijiria ṣeyin, o si yẹ ki a gboriyin fun ijọba atawọn eeyan orilẹ-ede yii.”
“Ko si ẹnikẹni to tako esi ibo naa ayafi awọn oludije to lulẹ.”
“Eto idibo ọhun ni eyii to le koko julọ ninu itan Naijiria eyii ti Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti jawe olubori.”
“Lara awọn to ti ki Tinubu ku oriire ni olori ijọba ilẹ Gẹẹsi, Rishi Sunak, atawọn olori ijọba mi ninu ajọ ECOWAS ati African Union.”
Atiku Abubakar ati Peter Obi kọ esi ibo aarẹ naa
Ọjọ karundinlọgbọn ni Naijiria ṣe eto idibo Aarẹ atawọn aṣofin agba waye, nibi ti Bola Ahmed Tinubu ti gbegba oroke gẹgẹ bii Aarẹ.
Amọ, awọn oludije ẹgbẹ oṣelu to wa ni ipo keji ati ipo kẹta, Atiku Abubakar ati peter Obi sọ pe esi ibo naa ko tẹ awọn lọrun, wọn si ṣeleri lati lọ ile ẹjọ.
Wọn ni awọn kudiẹkudiẹ kan waye lasiko eto idibo naa, paapaa nibi ti wọn ti n ko idibo ọhun jọ titi ti wọ fi kede ẹni to bori.
Tinubu lo ni iye ibo to pọ ju, eyii to le ni ida 25% ni ipinlẹ mọkandilọgbọn, eyii to mu ko bori, gẹgẹ bii alakalẹ ofin.
Nigba ti Obi ati Atiku bori ni ipinlẹ mejila-mejila, eyii to jẹ akọkọ iru rẹ ni Naijiria.
Kí ló dé tí Desmond Elliot fi ń tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ̀ Nàìjíríà?
Gbajugbaja osere Nollywood ati ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko, Desmond Elliot ti tọrọ aforijin lọwọ awọn ọdọ Naijiria lori ọrọ kan to sọ jade lasiko iwọde EndSARS ninu oṣu kẹwaa ọdun 2023.
Elliot ló n soju ẹkun ijọba ibilẹ Surulere ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko, eyi ti oṣere miirann du mọ lọwọ bayii.
Lati igba to ti pe awọn ọdọ Naijiria ni ọmọde, ni wọn ti bẹrẹ si ni maa sọrọ odi si.
Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe, o gbinyanju lati tan imọlẹ si ọrọ naa.
O ni oun mọ awọn ti oun n ba wi, paapaa awọn to n fi epe ransẹ si abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko, Mudashiru Obasa.
"Nnkan ti mo le sọ nipe, mo tọrọ aforijin, ko si ẹni to mọ ohun gbogbo tan.
"Ohun to jẹ otitọ niwaju temi, le e maa jẹ otitọ niwaju tirẹ.
"Ko si anfani ti ọrọ to tí lo fẹ ṣe.
"Lẹyin ti mo sọrọ naa, mo tọrọ aforijin, mo si tun tọrọ aforijin lọwọ awọn eeyan ti ọrọ naa ta ba.
Kí gan ni Desmond Elliot ṣe?
Ọrọ Desmond Eliot ni awọn ọmọ Naijiria fi bọnu lori ẹrọ ayelujara nipa ọrọ to sọ lori bi awọn Ologun ṣe da ibọn bo awọn afẹhọnuhan tako ifiyajẹni awọn ọlọpaa ni Lekki Toll gate,ni ipinlẹ Eko.
Desmond Eliot ni ki awọn gbajumọ lawujọ ati awọn oloṣere ki wọn ye sọrọ kubakugbe lori ayelujara mọ, amọ ki wọn lọ gba kaadi idibo wọn, ki wọn dibo fun ẹni ti wọn fẹ ninu eto idibo to n bọ,a bi ki awọn furawọn dije dupo.
Bakan naa lo ni orilẹede Niajiria yoo di ohun igbagbe ti awọn ọmọ Naijiria ko ba jawọ ninu bi wọn ṣe n ji awọn nkan gbe tabi fi ina si awọn ile.
Ohun ti mo sọ ni pe ki wọn mase lo ẹrọ ayelujara lati da Naijiria ru - Elliot
Elliot gboriyin fun Abẹnugan Ile Igbimọ Aṣofin to bu ẹnu atẹ lu ifiyajẹni to waye ni Lekki Toll gate.
''Inu mi dun pẹlu ọrọ ti Abẹnugan Ile Igbimọ Aṣofin sọ nipa iṣẹlẹ to waye ni Lekki, amọ o ba oun ninu jẹ pẹlu bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n ṣepe, ti wọn tun lo ji ọpa ọba gbe laafin Ọba Ilu Eko.
'Ifiyajẹni, ọrọ kobakugbe ati ikorira ti pọju lorilẹede Naijiria.''
Bakan naa ninu fidio miran to fi lede, o fihan gbangba pe oun ko fọwọsi abadofin to de bi awọn ọmọ eniyan ṣe n sọrọ lori ẹrọ ayelujara.
Amọ ohun ti oun sọ ni pe, ki wọn mase lo ẹrọ ayelujara lati fi da orilẹede Naijiria ru.
Amọ, gbogbo ọrọ to sọ yi bi awọn ọmọ Naijiria ninu, ti wọn si fi ọrọ gun un lara lori ẹrọ ayelujara.
PDP ní kí alága àjọ INEC kọ̀ ìwé fi ipò sílẹ̀, INEC fún PDP lésí
Ẹgbẹ oṣelu PDP ti pe fun ki alaga ajọ eleto idibo INEC ni Naijiria, Mahmood Yakubu kọ iwe fi ipo silẹ ni kiakia.
Eyi ko ṣẹyin bi PDP ṣe fi idirẹmi ninu idibo sipo aarẹ to waye ni Naijiria ni Ọjọ Karundinlọgbọn, Oṣu Keji, ọdun 2023.
Akọwe ẹgbẹ oṣelu PDP, Debo Ologunagba lasiko ti wọn n ba awọn akọroyin sọrọ ni ilu Abuja ni esi idibo sipo aarẹ fihan pe ọpọlọpọ magomago lo waye lati rii pe oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu lo wọle ninu idibo naa.
Ologunagba ni dandan ni alaga ajọ naa gbọdọ fi ipo silẹ ki idibo sipo gomina naa to waye ni Ọjọ Kejidinlogun, oṣu kẹta, ọdun 2023.
O fikun un pe ti alaga ajọ INEC ba fi ipo silẹ ni awọn eniyan yoo to ni igbagbọ ninu eto idibo ni Naijiria.
Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu PDP kesi Ọga agba ọlọpaa ni Naijiria, Usman Alkali Baba ati ajọ ọtẹlẹmuyẹ, DSS ki wọn fi panpẹ ọba mu ọjọgbọn Mahmood Yakubu naa, ki wọn si bẹrẹ iwadii pẹrẹwu lori rẹ.
INEC fun ẹgbẹ oṣelu PDP ni esi...
Ajọ INEC ti kilọ fun ẹgbẹ oṣelu PDP ki wọn dẹkun sisọrọ kobakungbe si olori ajọ naa.
Ninu atẹjade ti INEC fi lede ni wọn ti ni ki PDP ki ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ lori ẹsun orisirisi ti wọn fi n kan adari ajọ naa.
Ajọ eleto idibo naa ni ko si ẹri to daju lati pe fun ki alaga Ajọ INEC naa kọ iwe fi ipo silẹ.
‘’Ẹgbẹ oṣelu PDP ko lee mu ẹri jade pe alaga Ajọ INEC naa ṣe aṣemaṣe lasiko eto idibo sipo aarẹ.
‘’PDP ko lee fi idi rẹ mulẹ pe Yakubu tapa si ofin orilẹede Naijiria lasiko eto idibo naa to fi mọ ofin to de eto idibo ọdun 2022’’.
‘’Bakan naa ni PDP ko ni ẹti to daju pe alaga ẹgbẹ oṣelu INEC lo padipọ pẹlu awọn oṣiṣẹ ajọ naa lati maṣe fi esi idibo naa si ori ikanni wọn lori ẹrọ ayelujara.’’
Ajọ INEC naa ni awọn ko ṣe magomago lasiko eto idibo naa, ti awọn si gba awọn to fi orukọ silẹ lasiko idibo lati dibo lasiko to yẹ.
Amọ PDP ni idajọ ileẹjọ pe ki INEC tun ẹrọ BVAS sẹ yoo ba ẹri ti awọn ni nipa magomago to waye lasiko idibo naa.