You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn kan ń yọ́lẹ̀ gba owó bàbá mi ní bánkì; Gbèsè ni ẹ̀bùn owó N3M bá nílẹ̀ - Ọmọ Fadeyi Oloro
Ọmọ bibi oloogbe Fadeyi Oloro to tun jẹ ọmọbibi rẹ kan ṣoṣo, Olufunke Fasunwon ṣalaye fun BBC Yoruba ninu ifọrọwanilẹnuwo pe lati bii ọdun mẹta sẹyin ni ara baba ko ti ya ti awọ́n si ti gbe e lọ si ile iwosan fun itọju.
“Ṣugbọn a dupẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria to da si wa nigba ti aisan yẹn tun pada. A lọ si ileewosan UCH ni Ibadan, wọn dẹ gba wa niyanju nipa awọn nnkan ti baba n jẹ”.
Arabinrin Olufunke tubọ ṣalaye pe ara baba oun tilẹ ti n ya pada amọ nigba to di igba diẹ sẹyin ni aisan naa tun ru jade pade ti awọn si bẹrẹ si ni ṣa gbogbo ipa awọn lati tọju gbajugbaja oṣere naa.
“Awọn ọmọ Naijira dide si wa nigba taa ke gbajare si wọn, sibẹ sibẹ naa, igba ti ẹlẹmi de, ko si ohun ti a fẹ ṣe sii”.
Ṣe lootọ ni pe ẹ ja ilẹkun wọ inu ile baba tẹẹ si ba oku wọn nibẹ?
Arabinrin Olufunke ṣalaye pe ni alẹ patapata ọjọ Keje ọjọ Iṣẹgun Oṣu Kẹta ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, arakunrin oniṣẹ iroyin abẹle kan to ran baba awọn lọwọ́ lati kan si awọn eekan ọmọ Naijiria oninuure lori ayelujara ti wọn fi bẹrẹ si ni ran an lọwọ, Sunday pe oun nipa igbesẹ ti awọn tun fẹ gbe fun itọju baba ati nipa wiwa ọ̀nà láti kọ bii yara meji sori ilẹ ti baba Fadeyi oloro ti ra tẹlẹ lara owo ti awọn ẹlẹyinju aanu fi ran awọn lọwọ.
Arabinrin Olufunkẹ ni o saba maa n to nnkan bii ago mẹwa ki baba to gbe ipe lori ẹrọ alagbeka rẹ.
“Nigba ti a maa fi de ibẹ, ti a ti pe baba lori ẹrọ̀ tititi ti wọn ko gbe ipe, awọn alabagbe wọn sọ fun wa pe baba ti ji jade laarọ kutukutu, baba dẹ wọle pada".
O ṣalaye pe nigba ti awọn tun kan ilẹkun, baba Fadeyi Oloro ko dahun, idi niyii ti wọn fi wa ọna fi ja ilẹkun ile Fadeyi Oloro lati wọ ile.
"Igba taa maa wọ ile, a ba baba lori aga ti wọn n sun lai mọ pe wọn ti ku ni.
Eleyii lo faa taa fi pe awọn nọọsi ladugbo ki wọn wa ba wa wọn wọn boya wọn ṣi wa laye abi ṣe aaye ṣi wa lati doola ẹmi wọn amọ igba taa maa wo o lọ wo o bọ, baba ti jẹ Ọlọrun nipe".
Ọmọ oloogbe ni lẹyin ti nọọsi meji ba awọn yẹ ara Fadeyi Oloro wo ni wọn sọ fun awọn pe o ti jẹ Ọlọrun nipe.
Wọn gbe oku rẹ lọ si Mọṣuari lati ile niwọn igba ti aridaju wa latẹnu awọn nọọsi pe ẹmi ti lọ lara baba, o ti ku.
Ṣe Fadeyi oloro ti n gbe ile tuntun abi onile ti le e jade nile?
“Nigba ti baba onile to ni ibi ti baba mi n gbe ti fun wọn ni iwe pe ki wọn ko jade, a roo pe ka wa nnkan kekere ṣe sori ilẹ ti baba mi ti ra.”
O ni “a woye pe a ti n ṣe itọ́ju baba bayii o, ohun ti a ba le ṣe sori ilẹ yẹn naa ti wọn ni ki ipa to pin, ka lọ gbe e yẹwo”.
O fi kun un wipe, gbogbo owo ti o wa ninu apo isuna baba Fadeyi Oloro ni awọn ṣawari pe awọn eeyan kan ti n gba lara rẹ.
O ṣalaye pe idi ni pe baba maa n fun eeyan ni kaadi rẹ lati baa gba owo eyi si lo jẹ ki wọn ni anfani ati ki ọwọ bọ inu akanti baba.
Ẹwẹ, o ni kete ti awọn rii pe nnkan yii n ṣẹlẹ lawọn lọ gbe igbesẹ ni banki ti baba n lo.
O wa ni awọn ti di oju opo kaadi naa bayii, awọn wa gbiyanju lati gbe igbesẹ lori lilo owo rẹ fun un bo ṣe yẹ.
Paali Paali ẹlẹrindodo la n ra fun baba tori Dokita ni ki wọn ma mu ọti mọ nigba ti aisan yii pọ
Ọmọ baba Fadeyi sọ fun BBC Yoruba pe ko to di ọjọ̀ naa ni ohun maa n gbe ounjẹ lọ fun Fadeyi Oloro nile.
“Nigba taa ti de lati ileewosan ni wọn ti ni ki wọn ma mu ọti mọ torinaa paali ẹlẹrindodo la maa n ra sile fun baba lati maa mu ko le fun wọn ni okun ati gbogbo ohunkohun ti wọn ba beere pe awọn fẹ jẹ
Arabinrin yii sọ pe oun ni ọmọ kan ṣoṣo ti baba ni amọ oun ti wa ni ile ọkọ torinaa kii ṣe gbogbo igba ni oun n wa lọdọ baba amọ oun rii pe adugbo kan naa ni awọ́n wa ki oun le maa moju to o.