You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ta ló wó ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀bù ní Dugbe àti Ogunpa tí ariwo fi sọ?
L'ọjọ Aje ni iroyin gbode kan pe ijọba ipinlẹ Ọyọ lo awọn janduku kan, lati wo ọpọlọpọ ṣọọbu ti awọn eeyan ti n ta ọja ni Dugbẹ Alawo ati Ogunpa.
Iroyin naa ni ijọba ko sọ ohunkohun fun awọn ontaja naa saaju wiwo isọ wọn ọhun.
Iroyin naa fikun pe awọn oṣiṣẹ to n mojuto igbokegbodo ọkọ n'ipinlẹ Ọyọ, 'Park Managers', labẹ akoso Alhaji Mukaila Lamidi ti ọpọ eeyan mọ si 'Auxiliary', lo lẹ idi apo pọ pẹlu awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ọyọ kan, lati wa wo awọn isọ naa.
Ọna lati fidi otitọ ọrọ mul nipa isẹlẹ yii lo mu ki BBC Yoruba ṣe abẹwọ si ọja Dugbẹ Alawo lẹyin ti iroyin naa lu sita.
‘Kii se Auxillary tabi ẹnikẹni lo ni ki wọn wo awọn sọọbu l‘Ogunpa’
Pupọ ninu awọn ti ọrọ naa kan ninu awọn to n ta ọja nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, lo ba akọroyin wa sọrọ.
Sugbọn wọn kọ lati da orukọ ara wọn, bẹẹ si ni wọn ko gba ki a ya awọran wọn.
Alaye ti wọn ṣe fun akọroyin wa labẹ aṣọ ni pe, saaju asiko yii ni ijọba ipinlẹ Ọyọ ti kede erongba rẹ lati kọ awọn ṣọọbu igbalode si gbagede ibi ti karakata ti n waye tẹlẹri ni ọja naa.
Wọn fi kun ọrọ wọn pe, awọn ontaja to kọ eti ọgboin si ikede ti ijọba ṣe saaju asiko yii, ni wọn fi katakata wo ṣọọbu wọn lọjọ Aje.
Wọn wa fidi otitọ ọrọ mulẹ pe kii se Auxilliary tabi ẹnikẹni lo pasẹ pe ki wọn wo awọn sọọbu naa.
Bakan naa ni wọn ṣalaye pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ti ṣe abẹwo si ọja naa, lẹyin ti wọn wo awọn ile itaja to n bẹ ni gbagede ibi ti kọngila ti fẹ ṣiṣẹ.
Bẹẹ si ni karakata ko dawọ duro titi di akoko yii ninu ọja naa, nitori pe awọn eeyan ti wọn le kuro nibi ti wọn fẹ kọ awọn ṣọọbu tuntun si ti n to ọja wọn si ibomii bayii.